Yomi Fabiyi kési àwọn olólùfẹ́ òtítọ́ láti jáde fún ìwọ́de fún Baba Ijẹsha ni Panti

Oríṣun àwòrán, others
Yomi Fabiyi ko ti i dakẹ lori ipinnu rẹ ja fitafita fun itusilẹ akẹgbẹ rẹ, Baba Ijẹsha kuro ni ahamọ ọlọpaa.
Ninu ọrọ to tun kọ si oju opo Instagram rẹ ni ọjọ Aje, Fabiyi sọ pe oun ko ni i duro de ẹnikẹni ki oun to o bẹrẹ iwọde ti oun kede.
Fabiyi to fi ibinu han ninu ọrọ naa sọ pe inu n bi oun nitori pe ọrọ Baba Ijẹsha kan oun.
O ni ọkunrin kan bi i igba ni oun.
- Mo ti padà sí ẹ̀sìn òwúrọ̀ mi o! Ẹ̀ gbé Ọlọ́run tóbi - Yomi Fabiyi
- Kí ló lè fàá kí Yomi Fabiyi àti PA rẹ̀ máa fẹnu ko ara wọn l'ẹ́nu?
- Ẹ tú Baba Ijesha sílẹ̀ pẹ̀lú Béèlì, ẹ má ṣi agbára òfin lò bí bẹ́ẹ̀ kọ́
- Ipa tí Fathia Balogun kó nínú bí mo ṣe dèèyàn lágbo òṣèré fíìmù Yorùba rèé - Baba Ijesha
- Wo orúkọ mẹ́rìnlá tó làmìlaaka tí Lizzy Anjorin sọ ọmọ rẹ̀
- À ń ṣe ìwádìí lọ́wọ́ bí ''candle'' ṣe pa Kayode Badru ní ìpínlẹ̀ Eko - Ọlọ́pàá
"Ẹnikẹni to ba mọ pe ọrọ yii kan oun, to si nifẹ lati ṣe atilẹyin fun nkan to tọ, le darapọ mọ mi.
"Ti o ba si lero pe nkan to tọ ni fifi eeyan si atimọle lọna ti ko ba ofin mu, tabi o ro pe ko le kan ọ, ọmọ, baba tabi iya rẹ, ma gbiyanju lati darapọ."
Bakan naa ni Ọgbẹni Fabiyi kilọ fun awọn oṣiṣẹ ilu ati awọn olori ti ìbò gbe wọle, lati ma jẹ ki ifẹ inu wọn tabi eero ọkan wọn nipa nkan to ṣẹlẹ, ṣe idiwọ fun iṣẹ wọn tabi ofin ilu.
Fabiyi ni asiko ti nkan to dara ba ṣẹlẹ ni Naijiria ma n fi ara rẹ we America, ṣugbọn to ba ti nii ṣe pẹlu ẹtọ ọmọniyan, 'a ko gbọdọ fi Naijiria we America rara.
"Ẹ jẹ ki ofin ko ṣe iṣẹ rẹ, ko si daabo bo ẹtọ gbogbo eniyan."
Fabiyi tun fi kun ọrọ rẹ pe lootọ ni awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ wa ni iyanṣẹlodi, amọ ṣe atimọle ni Baba Ijẹsha yoo wa , koda ti iyanṣẹlodi naa ba pe ọdun kan?
- Èèyàn 28 kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó dànù ní ìpínlẹ̀ Niger
- 30 nínú 40 àwọn tí wọ́n jígbé nínú Mọ́ṣáláṣí lásìkò Tahajjud ní Katsina ti gba ìtúsílẹ̀
- Amotekun Ondo ju afurasí ajínigbé mẹ́rin s'átìmọ́lé, dóòlà àwọn tí wọ́n jígbé
- Ọkọ mi kò kú rárá- Arabinrin Temiloluwa aya olóògbé Dare Adeboye
- Ẹ̀mí ọlọ́pàá mẹ́tàlá ló sọnù lópin ọ̀sẹ̀ lọ́wọ́ àwọn "unknown gunmen"
- Orílẹ̀-ède UK ti fi kún iye òfin tó de àwọn arìnrìàjò wọn tó fẹ́ wá sí Nàìjíríà nítorí…
Àyànmọ́ ló mú mi pàdé Princess, èrò wa jọra wọn- Iyabo Ojo
Gbajugbaja oṣere ori itage Yoruba, Iyabo Ojo ti sọ oriṣiiriṣii ọrọ iwuri nipa adẹrinpoṣonu, Damilola Adekoya ti ọpọ mọ si Princess.
Iyabo wa lara awọn to n ja fita fita lati rii pe akẹgbẹ rẹ ninu ere tiata, Olarenwaju James ti awọn eeyan mọ si Baba Ijesha foju wina ofin lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn kan an.
Laipẹ yii iroyin kan jade ninu eyi ti wọn ti fẹsun kan Baba Ijesha o fi ipa ba ọmọbinrin Princess lopọ.
- Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Kayode Badru ṣe ṣẹlẹ̀ ní Celestial Church of Christ ni Eko? ẹ wo ohun tí a mọ̀!
- Wo orísun agbára tí Sunday Igboho gbójúlé tí ọwọ́ ẹnikẹ́ni kò fi le tẹ̀ ẹ́
- Mo gbé ìgbésẹ̀ láti ṣẹ́ oyún ọmọ mi tuntun, ọkọ mi nàá sì faramọ́ nítorí pé...
- Wo ẹ̀sùn mẹ́rin tí ìjọba fi kan Baba Ijesha àti ìjìyà tí ìkọ̀ọ̀kan ní lábẹ́ òfín
- Toyin Abraham jọ̀wọ́ dáríjì mí - Yomi Fabiyi
- Ẹ tú Baba Ijesha sílẹ̀ pẹ̀lú Béèlì, ẹ má ṣi agbára òfin lò bí bẹ́ẹ̀ kọ́
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Osun ṣe bẹbẹ lórí ètò Akomọlede àti Aṣa lórí BBC
Ṣugbọn lọjọ ibi Princess, Iyabo ki i ni mẹsan an mẹwaa loju opo Instagram rẹ.
O ni anfaani lo jẹ fun oun lati ba Princess pade ati lati mọ ọ sii daadaa.
Iyabo ni obinrin to ṣe e fi yangan ni adẹrinpoṣonu Princess, ati wi pe ayanmọ lo mu ki awọn mejeeji pade ara awọn.
''Ero wa jọ ara wọn, bakan ni a jọ nifẹ awọn ọmọde.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Mo mọ pe asiko to lagbara ni asiko jẹ fun ọ, ṣugbọn mo rọ ẹ pe ki o pakiti mọri.
Laipẹ lai jina, gbogbo rẹ ni yoo di afisẹyin ti egun n fi aṣọ,'' Iyabo lo sọ bẹẹ.
Iyabo ni ''mo nifẹ rẹ gan an ọrẹ mi atata. Isu ọmọ a jina fun wa je.''
- Ǹkan dé o! Àwọn jàndùkú tún yìnbọn pa ọlọ́pàá méje lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n dáná sun ọkọ̀ wọn
- Wo orúkọ mẹ́rìnlá tó làmìlaaka tí Lizzy Anjorin sọ ọmọ rẹ̀
- Sultan Sokoto ní káwọn mùsùlùmí wojú ọ̀run fún oṣù tuntun láti parí àwẹ̀
- Emmanuel Abina, ọmọ Olùdarí ìjọ GOFAMINT, Elijah Abina jáde láyé lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀
- Ìjọba Ààrẹ Buhari ti kùnà, kò le è sí ìfìmọ̀ṣọ́kan lábẹ́ ìṣèjọba rẹ̀ ní Naijiria- Wole Soyinka
- Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Akeredolu tó gbá ìyàwó mi létí ó bá má lọ lọ́fẹ̀ẹ́ - Ọkọ Aláboyún
- Egúngún bá òṣèrébìnrin lòpọ̀ nínú eré, àwọn Eléégún yarí



















