Ondo kidnap: Amotekun Ondo ju afurasí ajínigbé mẹ́rin s'átìmọ́lé, dóòlà àwọn tí wọ́n jígbé

Ẹṣọ Amotekun Ondo

Oríṣun àwòrán, Amotekun Ondo

Ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan bayii ni ti oloun.

Ẹṣọ Amotekun ipinlẹ Ondo lo ti fi ọwọ ofin mu awọn afurasi ajinigbe mẹrin niluu Akure.

Ọga agba Amotekun nipinlẹ Ondo to ba BBC Yoruba sọrọ, Oloye Adetunji Adeleye ṣalaye pe oju ọna Akure si Oda lawọn afurasi ọhun ti ji awọn eeyan gbe lọ.

Oloye Adeleye sọ pe ẹṣọ Amotekun doola awọn eeyan tawọn afurasi ọhun jigbe lọ.

Ọga agba Amotekun ni ileeṣẹ ọlọpaa naa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ Amotekun lati ri pe ọwọ tẹ awọn afurasi naa.

''Lẹsẹkẹsẹ ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ni a fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa ati ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ipinlẹ Ondo.

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan

Gbogbo ẹṣọ eleto abo nipinlẹ Ondo ni a jọ ṣiṣẹ papọ lori ati mu awọn afurasi naa,'' Oloye Adeleye ṣalaye.

O fikun ọrọ rẹ pe awọn afurasi mẹrin naa si wa ni atimọle ẹṣọ Amotekun nigba ti iwadii ṣi n lọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, Trade by Barter, Rivers: Mọ̀ síi nípa ọjà ní Esuk Mba, níbití o ti lè fi iṣu gba edé, epo

Oloye Adeleye ni o ṣeeṣe ko jẹ wi pe lati atimọle ẹṣọ Amotekun lawọn afurasi naa yoo gba lọ sile ẹjọ.

Amọ, o sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ, ati pe abajade iwadii lo maa sọ bo ya awọn maa fawọn afurasi naa lọ sọdọ awọn ọlọpaa.