Dare Adeboye, #PDee àti #NotTodaySatan, I'm not leaving God: Ẹ wo bí Leke Adeboye, àwọn ọ̀dọ́ ìjọ RCCG ṣe gẹ irun wọn láti bú ọlá fún olóògbé Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, Instagram/PDEE
Gbogbo eto lo ti bẹrẹ fun eto isinku oloogbẹ, Pasitọ Dare Adeboye to jẹ ọmọkunrin ikeji Pasitọ Enoch Adeboye to jẹ adari ijọ Redeem Christian Church of God lagbaye.
Ọjọ Kọkanla, Oṣu Karun un ni yoo wọ kaa ilẹ sun, amọ lati Ọjọ Aiku ọṣẹ naa ni ayẹyẹ ikẹyin loriṣiriṣi ti bẹrẹ fun un pẹlu awọn ọdọ ijọ naa ti wọn gẹ irun ori wọn lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun oloogbe naa.
Pẹlu Hashtag #PDee ati #NotTodaySatan, I'm not leaving God, ni wọn n lo lati fi aworan wọn sita pẹlu bi wọn fa irun wọn lori ayelujara.
- Ẹni tó bá ní láàkàyè, a mọ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, àwà ti kọ lẹ́tà, èsì t'Ọ́lọ́pàá sì fún wa rèé - Yomi Fabiyi
- Mi ó ṣọ̀fọ̀, mo sọkún nítorípé... - Ìyàwó olóògbé Dare Adeboye sọ̀rọ̀ níbi ìsìn idágbére ọkọ rẹ̀
- A kò ní pe Ọlọ́run ní ẹjọ́ lórí ìkú ọmọ wa, Dare Adeboye - Ẹbí Adeboye
- Emmanuel Abina, ọmọ Olùdarí ìjọ GOFAMINT, Elijah Abina jáde láyé lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀
- Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Kayode Badru ṣe ṣẹlẹ̀ ní Celestial Church of Christ ni Eko? ẹ wo ohun tí a mọ̀!
- Ìyàwó Adeboye gbàdúrà fún Nàìjíríà ní ìgbà akọkọ tó fara hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn, Dare
''Awọn ọrọ akọle ti wọn ko si be ni pe'' A o bẹru iku mọ, iye ayeraye ni tiwa ni aye ati ni orun ti n bọ. Kikuro ninu ara mu mi wa pẹlu Oluwa ninu ẹmi''
''Ki emi wa laye ni lati wa ninu Kristi, ki emi si ku jẹ ere nitori iye ayeraye ni - Phillippians 1:21.''

Oríṣun àwòrán, Instagram/PDEE
Leke Adeboye lo kọkọ fa irun rẹ korodo!
Ẹni akọkọ to kọkọ gẹ irun rẹ ni aburo oloogbe naa, Leke Adeboye ki awọn ọmọlẹyin Kristi ninu ijọ naa kaakiri agbaye to bere lati ma a ṣe gẹgẹ bi Leke ṣe n ṣe.
Ninu fidio to fi lede lo ti sọ wi pe iṣe wọn ni lati bu ọla fun ẹni to ba jẹ akinkanju ọkunrin to jẹ ọdọ ninu Kristi, to si ja fitafita fun ọrọ Ọlọrun ki o to rekọja kuro ni aye.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Ọpọlọpọ eniyan lo si ti bẹrẹ si ni fesi si irun gigẹ naa lati bu ọla fun ẹni to doloogbe.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Ọpọ sọ wi pe kii ṣe ọna igbagbọ lati gẹ irun nitori oloogbe to kọja lọ nigba ti awọn miran ni o dara bẹẹ nitori ẹni ọdun mejilelogoji ni Dare ko to di oloogbe.

Oríṣun àwòrán, others
Ọjọ kẹfa, oṣu Karun un, ọdun 2021 ni iroyin iku pasitọ Dare Adeboye fa ori ayelujara ya.
Iroyin iku rẹ da omi tutu si ọkan gbogbo eeyan, paapaa awọn ọmọ ijọ Redeemed Christian Church, RCCG, ni Naijiria ati loke okun.
Dare Adeboye nigba aye rẹ jẹ ọkan lara awọn ọmọ alufa agba, to tun jẹ adari ijọ RCCG kaakiri agbaye, pasitọ Enoch Adejare Adeboye.
Wọn bi Dare Adeboye ni ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹfa, ọdun 1979.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Dare jẹ olukọ awọn ọdọ, o jẹ ẹnikan to ko awọn eeyan mọra, o si tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọdọ to lẹnu lọrọ ati ilumọka ninu ijọ RCCG.
Orukọ ti ọpọ awọn ọdọ ninu ijọ irapada maa n pe ni "Pastor Dee tabi PD".
- Emmanuel Abina, ọmọ Olùdarí ìjọ GOFAMINT, Elijah Abina jáde láyé lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀
- Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Akeredolu tó gbá ìyàwó mi létí ó bá má lọ lọ́fẹ̀ẹ́ - Ọkọ Aláboyún
- Egúngún bá òṣèrébìnrin lòpọ̀ nínú eré, àwọn Eléégún yarí
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Osun ṣe bẹbẹ lórí ètò Akomọlede àti Aṣa lórí BBC
- Wo orúkọ mẹ́rìnlá tó làmìlaaka tí Lizzy Anjorin sọ ọmọ rẹ̀
- Sultan Sokoto ní káwọn mùsùlùmí wojú ọ̀run fún oṣù tuntun láti parí àwẹ̀