Dare Adeboye burial: Temiloluwa aya olóògbé Dare Adeboye ni ọkọ òun ń sùn ni

Iyawo Oloogbe Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, dareadeboye

Arabinrin Temiloluwa to jẹ aya oloogbe Dare Adeboye ni ọkọ oun ko bẹru iku rara.

O fidi ọrọ yii mulẹ pe ọkọ oun ko ku nibi eto isin idagbere to waye nile ijọsin House of Favour ni Redemption Camp ni Mowe ni irọlẹ ana ojọ Aje.

Temiloluwa ṣalaye pe oun ni aridaju pe ọrun rere ni Dare Adeboye ti lọ sinmi nitori pe eniyan ọtọ ni.

Bakan naa lo rọ awọn eniyan ti ko tii ni Jesu laye wọn tabi ti wọn ti pada se\yin lati pada sile lọdọ Olugbala wọn nitori iru ọjọ bayii ti wọn a sun ti wọn ko ni ji mọ.

Iyawo Oloogbe Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, dareadeboye

Mi ó ṣọ̀fọ̀, mo sọkún nítorípé... - Ìyàwó olóògbé Dare Adeboye sọ̀rọ̀ níbi ìsìn idágbére ọkọ rẹ̀

Wo àwọn ìdílé Dare Adeboye níbí ètò ìsìn ìdágbére rẹ tó bẹrẹ lana

Ero ko gba ẹsẹ nibi eto isin idagbere oloogbe Pasitọ Dare Adeboye to jẹ́ ọmọkunrin kejiadari ijọ Redeemed Christian Church of God, RCCG.

Gbogbo ẹbi, ara ọrẹ ati ojulumọ lo peju pesẹ sibi isin naa to bẹrẹ ni dede ago mẹrin irọlẹ ọjọ Aje, ọjọ kẹwa oṣu karun.

Iyawo oloogbe, Temiloluwa ni oun ko ṣọfo tori oun gbagbọ pe lootọ ni ọk oun jẹ onigbagbọ tootọ ti inu oun si dun.

Mi o sofo rara mo sọkun tori pe o fi mi silẹ ni - Iyawo Oloogbe

Nigba ti asiko rẹ to lati sọrọ, Temiloluwa aya oloogbe Pasitọ Dare Adeboye fi ọkan igbagbọ ke Halleluyah pẹlu gbogbo ero to wa ninu gbọngan.

"O sun ni ko ku, ko ku mo si mọ, o da mi loju pe ni owurọ ọjọ ajinde, yoo jinde a o si ri i ninu ogo".

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan

Iyawo oloogbe ni o da oun loju pe igbagbọ rẹ ninu Jesu daju.

"O sọ fun mi pe, bi mo(Dare) ba ku lonii, mo mọ pe mo ti ṣe ohun ti Ọlọrun ni ki n ṣe".

Iyawo rẹ ni o da oun loju pe o wa ni ọrun to si fi akoko na waasu fun awọn to wa nibẹ pe ti ko ba da wọn loju ibi ti wọn n lọ lẹyin aye, ki wọn yipada ki wọn gba Jesu gbọ.

Ẹni to bọwọ to tẹriba ni Pasitọ Dare - Osinbajo

Igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, dareadeboye

"Deeti ọjọ kan naa ni emi ati ẹgbọn mi ṣe igbeyawo, gbogbo ibi to lọ ni mo n gba tọ ọ lẹyin ni kekere"

Leke Adeboye, Aburo Olooogbe

Oríṣun àwòrán, dareadeboye

Aburo oloogbe to tun jẹ abigbẹyin baba Adeboye iyẹn Leke Adeboye ni gbogbo nkan lo fẹrẹ jẹ pe awọn jọ n ṣe papọ to bẹẹ to jẹ wipe bi igbin fa ikarahun a tẹle e ni ọrọ oun ati ẹgbọn oun Dare lati kekere.

"Ileewe alakọbẹrẹ titi de fasiti kan naa la jọ lọ, ori bẹẹdi onirin oke ati isalẹ kan naa lemi atirẹ n sun si".

Leke to gbiyanju lati ma jẹ ki omije bọ loju rẹ ṣa ara jọ to si sọ diẹ lara igbesi aye oloogbe Dare Adeboye.

Koda Leke ni deeti ọjọ ti ẹgbọn oun Dare ṣeyawo loun naa mu ni ọdun ti oun fẹ ṣeyawo ti awọn si tun fẹẹ bimọ tẹlera.

O ni bii kii ba ṣe iṣẹ iranṣẹ to pe awọn pada wa si Naijiria ni, iwe ti oun ati ẹgbọn oun lọ ka niilẹ Gẹẹsi ko ba ti mu awọn ti ọmọ adulawọ akọkọ to jẹ minisita tori ẹgbọn jẹ oye adari ọmọ ileewe girama lọhun to si jẹ pe oun ni ọmọ ilẹ Afirika akọkọ to ṣe iru rẹ.

Iyawo Leke Adeboye

Oríṣun àwòrán, www.dareadebooye

Bakan naa, iyawo aburo oloogbe, Leke Adeboye lo kọkọ ka iwe kika bibeli akọkọ ninu isin naa gẹgẹ bo ṣe ka lati inu iwe Kọrinti kini ori kẹẹdogun to sọrọ nipa igbasoke awọn ayanfẹ pe ...kii se gbogbo wa lao sun... iku oro rẹ da, isa oku iṣẹgun rẹ da..."

Awọn akọrin

Oríṣun àwòrán, Www.dareadeboye

Àkọlé àwòrán, Awọn akọrin nibi isin idagbere

Ireoluwa Adeboye - Ọmọ Oloogbe

Ọkan lara awọn ọmọ ọmọ Baba Adeboye

Oríṣun àwòrán, Adeboye

Àkọlé àwòrán, Ọmọ oloogbe

"Mo fẹ ka ẹsẹ Bibeli yii nitori baba mi to ti wa lọrun".

Ireoluwa ka lati inu iwe Tesalonika kini ori kẹrin lati ẹsẹ ikẹtala ninu eyi to ti sọ wipe "...nitoripe Oluwa fura r yoo sọkalẹ lati Ọrun wa pẹlu igbe ati ti awọn Angẹli, awọn oku ninu Krisiti ni yoo si kọkọ ji dide lọ pade rẹ... nitorinaa ẹ ma tu ara yin ninu".

Iyawo ati Ọmọ Pasitọ Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, dareadeboye

Àkọlé àwòrán, Iyawo ati Ọmọ oloogbe Pasitọ Dare Adeboye
Iyawo ati Ọmọ Pasitọ Leke Adeboye

Oríṣun àwòrán, dareadeboye

Àkọlé àwòrán, Iyawo ati Ọmọ Pasitọ Leke Adeboye nibi eto isin idagbere Dare Adeboye
Ọtunba Gbenga Daniel

Oríṣun àwòrán, dareaadeboye

Àkọlé àwòrán, Ọtunba Gbenga Daniel
Biṣọọbu Francis Wale Oke ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, dareadeboye

Àkọlé àwòrán, Biṣọọbu Francis Wale Oke ati iyawo rẹ
Ọrẹ timọ timọ Oloogbe

Oríṣun àwòrán, dareadeboye

Àkọlé àwòrán, Ọrẹ timọ timọ Oloogbe
Aworan Oloogbe

Oríṣun àwòrán, dareadeboye

Àkọlé àwòrán, Aworan Oloogbe ti wọn fihan nibi eto isin idagbere