Dare Adeboye: Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní olóògbé yóò wọ káà ilẹ̀ ṣùn ní Redemption Camp

Oríṣun àwòrán, Pst Dee
Idile Baba Enoch Adejare Adeboye to sẹsẹ padanu ọkan lara ọmọkunrin rẹ, Pasitọ Dare Adeboye, ti sọrọ sita fun igba akọkọ lẹyin isẹlẹ ibanujẹ naa.
Atẹjade kan ti mọlẹbi naa fisita lọjọ Ẹti, eyi ti Pasitọ Leke Adeboye fọwọsi lo dupẹ lọwọ gbogbo eeyan fun ibanikẹdun wọn.
Bakan naa lo tun salaye ilana bi iku oloogbe naa yoo se lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ohun tí ìyàwó Adeboye ṣe ní ìgbà akọkọ tó fojú hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn Dare
- Ikú Dare Adeboye kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú Covid-19, a bẹ̀bẹ̀ láti dá wà lákòókò yìí - Ẹbi Adeboye
- Àwọn ǹkan tí o kò gbọ́ rí nípa Dare Adeboye tó kú
- Mo dákú rangbọndan lẹ̀yìn tí amúgbálẹ́gbẹ gómìnà Akeredolu fún mi ní ìgbájú olóyì - Aláboyún
- Iléẹjọ́ pàṣẹ pé kí Makinde san N20m lórí bo ṣe dáwọn alága káńsù APC l'Oyo dúró lọ́nà àìtọ́
- Ọba Tejuosho tẹ ojú lọ́balọ́ba mọ́lẹ̀ fún ṣíṣe jìbìtì ìfẹ́ orí ayélujára - Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ
- Ẹbí Fela Anikulapo yarí fún APC àti Tinubu torí èròjà ìpolongo ìbò
Leke Adeboye ni "Pẹlu ẹmi imoore la fi n mọ riri yin bẹ se duro ti ẹbi wa lasiko idanwo yii, amọ a tu ara wa ninu pe ọmọ wa ọwọn pada lọ sile ni lati lọ sinmi lọdọ baba ati ẹlẹda rẹ.

Oríṣun àwòrán, Pst Dee
Igboya wa lo fidi mulẹ ninu igbe aye ifiraẹnijin ati aimọ tara ẹni nikan ti ọmọ wa gbe ninu Jesu Kristi, Olugbala wa.
Adura wa ni pe ki gbogbo wa dijọ pade nile ologo lorukọ Jesu."
Bakan naa ni ẹbi Adeboye tun salaye ilana ti eto isinku oloogbe naa yoo gba waye.
Bi eto isisnku Dare Adeboye yoo se lọ ree:
Ọjọ Aiku, ọjọ Kẹsan osu Karun ọdun 2021:
Akanse isin yoo waye ninu ijọ Redeem, City of David Youth Church to wa ni Eket nipinlẹ Akwa Ibom nibi ti oloogbe naa ti jẹ ojisẹ Ọlọrun, to si ku si.
Ọjọ Aje ọjọ kẹwa osu Karun ọdun 2021:
Akanse isin orin idupẹ ati ọrọ imọyi nipa oloogbe yoo waye ni ijọ Redeem, House of Favour to wa ni Redemption Camp nilu Eko.
Ọjọ Isẹgun ọjọ Kọkanla osu Karun ọdun 2021:
Isin idagbere yoo waye ni aago mẹwa owurọ ni ibudo awọn ọdọ, Youth Centre, to wa ni Redemption Camp ni Mowe, nipinlẹ Ogun.
Lẹyin naa ni wọn yoo sin oloogbe Dare Adeboye si ibẹ.



















