Bola Tinubu: Femi Kuti ní kí APC àti Tinubu yọ àmì ìdámọ̀ wọn kúrò lára èròjà ìbò

Femi Kuti ati Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Femi Kuti/ Bola Tinubu Twitter

Ẹbi gbajumọ akọrin nni, Fela Anikulapo Kuti ti yari fun asaaju ẹgbẹ oselu APC ati gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Koko ohun to fa sababi aawọ naa ko se lẹyin eto idibo aarẹ to n bọ lọdun 2023 ninu eyi ti awọn eeyan kan n sọ kiri pe oloselu naa fẹ kopa ninu rẹ.

Ẹgbẹ oselu APC lo gbe ọrọ atawọn aworan eroja ipolongo ibo fun Asiwaju Bola Tinubu soju opo Twitter rẹ, eyi ti wọn kọ 'Africana Jagaban' si lara.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ kálọ sí ìlú mi'... Ètò ńlá tó bẹ̀ sílẹ̀ kìjà lórí BBC Yorùbá

Olori ẹbi ati Dawodu Fela, Femi Kuti ti wa pariwo si oju opo Twitter rẹ pe oun ri awọn eroja ipolongo ibo naa ti ẹgbẹ APC gbe sita bii T-Shirt, ti wọn lo orukọ idamọ awọn.

Ọrọ ti Femi Kuti kọ soju opo Twitter rẹ

Oríṣun àwòrán, @Femiakuti

Femi ni lara awọn eroja ipolongo ibo naa ni wọn ti ri ọrọ 'Africana Jagaban', bẹẹ si ni orukọ Africana yii ọpọ eeyan mọ Fela Anikulapo mọ.

Femi Kuti wa n ke si awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC ati Asiwaju Tinubu funra rẹ pe ki wọn yọ orukọ Africana naa kuro lara eroja ipolongo ibo ti wọn n pin kiri.

O salaye pe orukọ idamọ ẹbi Fela ni Africana naa, ẹgbẹ oselu APC si n tẹ ẹtọ awọn mọlẹ nipa lilo orukọ nnaa lai gba asẹ lọdọ ẹbi awọn.

Ọrọ ti Femi Kuti kọ soju opo Twitter rẹ

Oríṣun àwòrán, @Femiakuti

Gbajumọ akọrin Afro Beats naa ni yoo dara ki ẹgbẹ oselu APC tete pa awọn ohun to kọ ati aworan to gbe soju opo Twitter rẹ rẹ ko to di nnkan mii.

"Ẹbi wa ko fara mọ ẹgbẹ oselu kankan lorilẹede Naijiria tabi loke okun. A n se ayẹwo bi nnkan yii se n lọ finnifinni.

Àkọlé fídíò, Irú ẹ̀dá wo ni Fẹla Jẹ́?

Tẹ ba si kuna lati tẹle ibeere wa, a jẹ pe a ko ni nnkan miran ta se ju pe ka tẹle ilana ofin to wa larọwọ to wa.

Amọ lọwọlọwọ bayii, ẹgbẹ oselu APC ti gbọ imọran ti Femi Kuti gba wọn, to si ti gbe awọn aworan eroja ipolongo ibo naa kuro loju opo Twitter rẹ.

Asọ T-Shirt fun eroja idibo

Oríṣun àwòrán, @Femiakuti