Seun Kuti: Gbogbo mọ̀lẹ́bí mi ló wọ bàtà ti Fẹla bọ́ sìlẹ̀
Oni lọjọ ti oloogbe Fela Anikulapo Kuti pe ọdun mejilelogun ni kaa ilẹ, sibẹ sibẹ gbogbo agbaye ko lee gbagbe rẹ.
Seun Kuti to jẹ ọmọ bibi Fela ṣàlàyé fún BBC Yorùbá pé ògo ilé Kuti ni ti òun bá lè gbàmi ẹ̀yẹ Grammy fún afro beat rẹ̀.
O fidunnu rẹ han lori bi wọn ṣe yan an fun ami ẹyẹ naa nitori ohun ti oju oun ri pọ lẹnu iṣẹ orin kikọ.
O ni wọn ko ṣẹṣẹ maa yan idile Kuti ni Grammy, 'wọn ti yan ẹ̀gbọ́n mi Femi Kuti náà tẹ́lẹ̀ fún Grammy' ki idile wa gba ami ẹyẹ yii lo ku lasiko yii.
Seun sọrọ nipa bàtà ti Fela Anikulapo Kuti bọ silẹ nipa orin afro beat eyi ti gbogbo onkọrin naa lagbaye ti tẹsẹ bọ bayii.
Ogbontarigi olorin yii ni kò wu oun ki ọmọ oun yan iṣe orin kikọ laaye rara nitori pe inira oriṣiiriṣii lo rọ mọọ.
Ni ipari o ni oun a ṣatilẹyin to yẹ fún ọmọ oun to ba ti dagba to dẹ fi dandan lee pe orin kikọ lo wu oun.