CJ Gold: ẹ̀rù kọ́kọ́ ba ìyá mi nígbà ti mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìjà jíjà
O ni ẹ̀rù máa n kọ́kọ́ ba òun ni nigba ti oun ba ṣẹṣẹ de gbagede ìjà.
Cindy Gold sọrọ lori bi nkan ṣe ri fun oun ni oṣu mẹfa akọkọ to bẹrẹ ija jija ati awọn idojukọ ti oun ni pẹlu bi o ṣe bori wọn.
Gold gba awọn ọdọmọbinrin niyanju pé ki wọn tẹramọ ere idaraya eyikeyi to ba wu wọn lati maa ṣe nitori orí lo mọ iṣẹ aṣela ẹda laye.
Ewu ìjà to ba ni awọ omi goolu lara ni Cindy fẹran lati maa wọ lasiko to ba n lọ gbagede ija.
Ọmọ ọdun mọkandinlogun to wa lati Soweto ni agbegbe Johannesburg ni orilẹ-ede South Africa yii ta awọn ọdọ jí nilẹ Adulawọ pe, ko si nkan ti eeyan ko le ṣe ti o ba ti ni ifọkansin.
Bakan naa lo gba awọn obi ati alagbatọ nimọran lati maa ṣatilẹyin to ba yẹ fawọn ọmọ wọn nitori pe ko sẹni to mọ ọjọ ọla awọn ọdọ yii.
O ni kete ti oun ba ti gun pepele gbagede ija bayii ni agbara oun maa de ti ọkan oun maa le pe iṣẹ ti bẹrẹ naa niyẹn.
Bayii, Cindy ti di gbajugbaja ọdọbinrin to jà to si ti n di ilumọọka sii.
O ni afojusun oun ni lati di aṣaaju fawọn ọdọ binrin to ṣẹṣẹ n dide ninu ìja jija.