World Menopause Day: Ǹkan osù tó ń se ségesège jẹ́ àmì

Dokita onimọ nipa obinrin ti sọ wi pe ọmọbinrin ti ko ba tete lo si ile ọkọ, le se alaibimọ lasiko to yẹ.
Dokita Emmanuel Moses Rotimi to ni ile iwosan aladani, Delight Fertility Hospital ti sọrọ lori isoro to n koju awọn obinrin lasiko ti wọn ba dawọ lati ma a se nkan osu (menopausal stage).
Dokita Emmanuel ni irinwo ẹyin lo wa lara obinrin, ati wi pe osoosu ti obinrin ba n se nkan osu ni awọn ẹyin wọn yii n dinku lara, ti awọn homoonu ara a si bẹrẹ si ni dinku, ti ẹwa ara a si bẹrẹ si ni dinku.
Nitorina, Dokita naa wa parọwa si awọn obinrin ki wọn se kiakia, ki wọn le bimọ ni ọdun mẹtalelogun si mẹrinlelogun, ki o si pari ọmọ bibi ki o to pe ọmọ ọdun marunlelọgbọn.
Awọn ami wo lo ma n jẹyọ ti obinrin ba ti dawọ nkan osu?
Dokita onimọ ti sọ wi pe ki obinrin tete loyun , ki o si bimọ ni ọna abayọ si airọmọbi to le jẹyọ nitori nkan osu to kọ lati wa.
O ni o seese ki obinrin to ba tete bere nkan osu, ki o tete dawọ nkan osu. Ati wi pe ti obinrin ba ti dawọ nkan osu, awọn eroja ara homoonu ara a bẹrẹ si ni ku, eleyi ti o ma n fa ọpọlọpọ ipenija fun awọn obinrin.
- Ara gbigbona
- Ki ooru o ma a mu wọn lati inu
- Ki egungun o ma a dun eniyan
- Ki wọn ni isoro pẹlu aya ati ọkan wọn.
- Aisan ọpọlọ le wọle ti ọkọ wọn ko ba fi wọn lọkan balẹ.
- Isoro lasiko ibalopọ
- Irora lasiko ibalopọ nitori awọn eroja ara ti ko si mọ.
Ọna abayọ si awọn ipenija bi ọmọbinrin se n darugbo ni ki ọmọbìnrin bimọ tan ni ọmọ ọdun marundinlogoji

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita onimọ nipa obinrin ti sọ wi pe ọmọbinrin gbọdọ bimọ lasiko nitori ko si ẹni to mọ boya nkan osu ohun ma a pin. Atiwipe gbogbo eroja ara obinrin lo ma n dinku ti agba ba ti n de fun obinrin.
- Wọn a ma a lo si ile iwosan ni orekoore fun ayẹwo to peye.
- Lilo awọn oogun oyinbo ti yoo mu ki homoonu ara o ji pepe.
- Ki wọn ma a se ere idaraya lasiko to yẹ.
- Ki wọn lo ororo ti yoo mu oju ara obinrin yọ, lasiko ibalopọ.
Dokita onimọ obinrin wa parọwa si awọn obi lati ko ọmọ nipa ewu to wa ninu ibalopọ pẹlu ọpọlọpo eniyan, eyi to le fa aisan ibalopọ, to le le di oju ile ọmọ ati awọn arun ti ko gbogun miran to le fa iku aitọjọ tabi airọmọbi ni ọjọ iwaju.













