First aid kits: Ilé ìwé tó bá kùnà yóò sẹ̀wọ̀n osù mẹ́fà- Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin

Ohun ìwòsàn
Àkọlé àwòrán, Ilé ìwé tó bá kùnà yóò sẹ̀wọ̀n osù mẹ́fà

Ile Igbimọ Asofin lorilẹede Naijiria ti pe fun ijiya to to fun awọn ile iwe, awakọ, awọn oni ile igbafẹ ati ile isẹ gbogbogbo ti ko ba ni ohun eto iwosan ti a ma n kọkọ fun awọn alaisan kiakia ti isẹlẹ ba waye.

Asofin

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ló ti kú nítorí kò sí ìwòsàn pàjáwìrì ní àwọn ilé ìwé àti ilé ìgbafẹ́.

Abadofin ti yoo mu ofin yii wa si imusẹ ti kọja ipele keji ni ile igbimọ asofin, lẹyin ti asofin lati ipinlẹ Ogun, Kehinde Agboola pe akiyesi awọn asofin si i bii abadofin naa se se pataki si.

Abadofin naa ni ẹnikẹni ti ko ba ni ohun elo iwosan pajawiri si inu rẹ yoo lọ si ẹwọn osu mẹrin si mẹfa tabi ki o san owo to to ẹgbẹrun mẹwa Naira.

Gẹgẹ bi ọrọ awọn asofin naa, iku aitọjọ yoo din ku lawujọ ti ijba apapọ ba buwọlu abadofin naa.

Lara awọn ohun elo iwosan ti wọn sọ wi pe o gbọdọ wa ni ayika ni oogun iwọsan oyinbo, bandeegi, iodine, ati ohun elo ti wọn nilo lati tete ji ẹnikẹni ti o ba dakun nibi isẹlẹ pajawiri.

Àkọlé fídíò, 'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'