Year end: Gbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀
Ọpọlọpọ àwọn to lorukọ ati awọn mii ti ayé kò mọ̀ nipa wọn rara ni wọn ti doloogbe ni 2018.
Eekan lára àwọn to doloogbe lọdun to n kogba wọle yii ni Ọbabinrin Soul to jẹ Ọlọrun ni pe lọmọ ọdun mẹrindinlọgọrin loṣu kẹjọ ọdun.
Aretha Franklin ni arun jẹjẹrẹ lati ọdun 2010. O gba ami ẹyẹ Grammy mejidinlogun nigba aye rẹ.
Stephen Hawkins to jẹ Ogbontarigi onimọ sayẹnsi naa lọ loṣu kẹta ọdun lẹyin to koju arun iṣan ara fọdun mejilelogun.
Winnie Madikizela-Mandela, ajajangbara ni South Africa naa ṣalaisi ni oṣu kẹrin ọdun. Oun àti ọkọ rẹ tẹlẹ, Nelson Mandela ni awọn eniyan South Africa ko le tete gbagbe.
Sri Devi to jẹ gbajugbaja oṣere Bollywood to ṣe fiimu to le lọọdunrun naa lọ lọmọ ọdun mẹrinlelaadọta.
Aisha Abimbola, Omọge Campus to jẹ gbajugbaja oṣere taye n fẹ ni Naijiria naa doloogbe ni Canada lẹyin to ba arun jẹjẹrẹ faa, ko to lọ sinmi.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu karun un ni ọmọge campus re ibi agba n re lọmọ ọdun mejilelogoji.
Olorin régè Ras Kimono naa re iwalẹ aṣa lọjọ kẹwaa, oṣu kẹfa, ọdun 2018.
Ras Kimono Efe, aya olorin rege naa tẹlẹ ọkọ rẹ loṣu to tẹlee.
Baba Sala, ogbontarigi agba apanilẹrin elere ori itage naa re ibi agba n re loṣu kẹwaa ọdun.
Moses Olaiya dagbere faye lẹyin to ti ṣe awọn iṣẹ to lamilaaka ninu ere oniṣe ati fiimu agbelewo.
Oṣere agba, Ajimaṣan, ti gbogbo awọn eniyan mọ si agba ọjẹ apanilẹrin naa lọ loṣu kẹwaa.
Tosyn Bucknor, gbajugbaja sọrọsọrọ ori afẹfẹ dẹni ilẹ̀ loṣu kọkanla lẹyin to ba arun arunmọleegun pòó.
Dokita Fredrick Fasheun to jẹ oludasilẹ ẹgbẹ OPC nilẹ Oodua to tun ṣiṣẹ takuntakun ni NADECO naa dagbere faye nibẹrẹ oṣu yii.
DJ Avicil onijo ti gbogbo aye n fẹ dẹni ilẹ loṣu kẹrin ọdun.
Ẹnikẹni to ba wa laye yẹ ko dupẹ ni lai nii fi ṣe nkan ti o n la kọja, ki onikaluku to ṣi wa lori oke eepẹ sa ipa rẹ lati mu alaafia jọba ni agbaye, bẹrẹ lati agbegbe rẹ ti o wa.
#Year end