''Ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣì n sọnù ni orilẹ̀-ede Burundi'

Àkọlé fídíò, ''Ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣì n sọnù ni orilẹ̀-ede Burundi'

'Awọn aworan kan to kọnilominu wa ninu fidio yii'.

Otẹlẹmuyẹ naa to pe ara rẹ ni Ọgbẹni Martin sọ nipa ọna ti wọn fi n pa àwọn eniyan ni Burundi fún BBC.

O sọ nipa oriṣi ọna ti àwọn ologun ṣi fi n fiya jẹ awọn eeyan ni orilẹ-ede Burundi.

Iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni ẹni to pe ara rẹ ni Ọgbẹni Martin naa n ṣe tẹlẹ.

O mẹnuba ọgba ẹwọn ìkọ̀kọ̀ ti wọn n lo fi ṣe ọṣẹ́ fawọn eniyan ni Burundi pẹlu ẹ̀sùn oriṣiiriṣii to fi kan ijọba ilẹ naa ṣugbọn ijọba ko fesi kankan.

Ọpọlọpọ awọn aworan nipa ile ti wọn ti n fiya jẹni naa lo ti wa lori ayelujara ṣugbọn awọn ọlọpaa ilẹ Burundi ni pe irọ́ ni, ko si ile bẹẹ ni Kinanira.

Igbe ayé alaafia ni awọn eeyan n pariwo kaakiri agbaye lasiko yii ni eyi ti o hande pe asiko ti to ki onile talejo, ọmọde ati agba, olori ati awọn ti wọn n ṣe ijọba le lori, ọkunrin ati obinrin, pẹlu èsin iyoowu ti onikaluku ba n sin ni agbaye gba alaafia laaye lati jọba bẹrẹ lati agbegbe koowa.