Ìjà Anglophone àti Francophone ti ń gba ẹbọ lọ́wọ́ tonílé-tàlejò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ogun kìí bimọ re, ọmọ bíi iku, ọ̀fọ̀, ibanujẹ àti ìpayínkeke ló ń bí.
Ogunlọgọ eniyan lo padanu ẹmi wọn l'opin ọsẹ to kọja ni ẹkùn Iwọ̀-oorun Ariwa, orilẹ-ede Cameroon.
Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe awọn ọmọ ogun Ambazonia mọkanlelogun, ati awọn ọmọ ogun meji nileeṣẹ ẹka ileeṣẹ ologun to wa ni Menchum, lo dagbere f'aye lasiko idoju ibọn kọra ẹni to waye ni abule Wum ati Bafmen, to wa ni ẹkùn Iwọ̀-oorun Ariwa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun Cameroon, Didier Badjeck sọ fun BBC pe àwọn tó kú ọhun padanu ẹmi wọn lasiko ti awọn ọmọ ogun Ambazonia wọ̀yá ìjà pẹlu àwọn ọmọ ogun Cameroon ni Wum l'ọjọ Abamẹta to kọja.
Ṣaaju ni iroyin kan jade lori ẹrọ ayelujara pe àwọn isọmọgbe awọn ológun mẹsan ati oludari wọn, ni wọn ṣekupa nigba ti ọta ìbọn wọn tan, ti ko si si awọn ọmọ ogun to to lati ranwọn lọwọ.
Ṣugbọn Ọgagun Badjeck sọ fun BBC pe ''lootọ ni ọpọlọpọ awọn ọmọ ogun Ambazonia yabo ẹka ileeṣẹ ologun naa, ti wọn si pa akọni ọmọ ogun meji. Amọ, ileeṣẹ ologun naa pa mejila lara wọn, ti awọn to ku si salọ pẹlu ọta ibọn lara wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O fi kun un pe bi ileeṣẹ ologun ṣe n gbiyanju lati pese aabo fun agbegbe naa, ni wọn tun ṣekupa awọn 'agbesunmọmi' mẹsan ni Bafmen.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Awọn agbebọn tun kọlu awọn oṣiṣẹ ajọ Cameroon Development Cooperation ni ẹkùn Iwọ Oorun Guusu, ti wọn pa eniyan mẹrinlelogoji lara ninu wọn
O ti le ni ọdun kan ti awọn ẹya to n sọ èdè Gẹẹsi ti ni ifọkanbalẹ kẹhin, eyi si ti mu ki awọn Biṣọbu ijọ Aguda kesi ijọba ati awọn ọmọ ogun Ambazonia lati dawọ ipaniyan naa duro.














