Ìjọba Nàìjíríà: Ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ni ọ̀rọ̀ Trump nípa Ààrẹ Buhari

Àkọlé fídíò, Ìjọba Nàìjíríà: Ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ni ọ̀rọ̀ Trump nípa Ààrẹ Buhari

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti sọ pe ko daju pe aarẹ Donald trump lee sọ ọrọ ti iwe iroyin Financial times kede pe o sọ lẹyin ipade oun ati aarẹ Muhammadu Buhari lorilẹede Amẹrika.

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ni pẹlu gulegule iroyin ayederu to n waye bayii lorilẹede Naijiria ati kaakiri agbaye, o yẹ ki eniyan ṣọra fun irufẹ iroyin bayi paapaa julọ lati ẹnu aarẹ orilẹede bii ti Amẹrika.

Minisita feto iroyin lorilẹede Naijiria, Alhaji Lai Muhammed to gbẹnusọ fun ijọba apapọ orilẹede Naijiria ṣalaye fun BBC Yoruba pe to ba jẹ pe lootọ ni Aarẹ Donald Trump sọ ọrọ yii jade, o ku diẹ kaato; paapaajulọ bi o ṣe jẹ pe niwaju gbogbo agbaye ni aarẹ Trump ti sọrọ to si gboṣuba fun aarẹ Buhari pe o kun oju iwọn lati kogoja gẹgẹ bii adari orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ọ̀rọ̀ Trump àti Russia kò yàtọ̀ pé àhesọ lásán ni èyí jẹ́

Ni owurọ ọjọ aje ni okiki kan nipa iroyin kan ti iwe iroyin Financial times gbe jade nipa ohun ti wọn ni aarẹ Trump sọ pe Buhari ko dun un ba rin pọ atipe oun ko gbadura ki oun pade irufẹ eeyan bii rẹ mọ laye oun.

Buhari kò ṣe é bá ṣe pọ̀

Buhari ati Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lẹyin ipade naa ni aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Trump ṣalaye pe oun ko fẹ pade 'ẹni ti ko dun-un ba ṣe pọ' bii Buhari mọ laye oun

Aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Donald Trump, ṣe apejuwe aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari, gẹgẹ bii 'ẹni ti ko dun-un ba ṣe pọ' ni kete ti wọn ṣe ipade tan ni ọgbọn ọjọ, oṣu kẹrin, ọdun 2018.

Ninu agbejade rẹ ninu iwe iroyin Financial Times ti ọjọ́ Aje ló ti sọ eyi di mimọ.

Buhari ni Aarẹ akọkọ lati ilẹ Afirika ti yoo ba Trump joko ṣepade pọ lẹyin ti wọn bura fun un gẹgẹ bii aarẹ karundinlaadọta fun orilẹ-ede Amẹrika.

Buhari ati Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lẹyin ipade ni aarẹ orilẹede Amẹrika,Trump ṣalaye pe oun ko fẹ pade 'ẹni ti ko dun-un ba ṣe pọ' bii Buhari mọ laye oun

O ba Trump sọrọ lasiko ipade naa lori ajọṣepọ okoowo laarin orilẹ-ede mejeeji.

Lẹyin ipade naa ni aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Trump ṣalaye pe oun ko fẹ pade 'ẹni ti ko dun-un ba ṣe pọ' bii Buhari mọ laye oun.

Lọwọ yii, ijọba Amẹrika ati Naijiria ko tii fesi lori iroyin yii paapaa bi o ṣe jẹ ọjọ́ kan naa ti aarẹ orilẹ-ede Kenya, Uhuru Kenyatta yoo ma ṣepade pẹlu aarẹ Donald Trump ni ile funfun balau White house.

Eyi yatọ gedegbe si ohun ti Aarẹ Trump sọ sita faraye gbọ lasiko ti ipade naa waye.

Buhari ati Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Buhari ati Trump ṣe ipade lori ajọṣepọ owo ni oṣu kẹrin ọdun 2018

Kini Trump sọ?

Trump ni oun ni igbagbọ to kuna ninu Buharai lati gbogun ti "obitibiti iwa ijẹkujẹ" to wa lorilẹ-ede Naijiria.

Gẹgẹ bii ọrọ kan ti eeyan kan ti iwe iroyin Financial Times fi orukọ bo laṣiri sugbọn to n ṣe alarinna laarin orilẹ-ede Amẹrika ati Kenya sọ, "Afirika ko figba kan ri wa ni ara ohun to ṣe koko fun aarẹ Trump ṣugbọn bi o ba fẹran rẹ yoo wa ọna lati rii pe nnkan rere waye laarin ẹyin mejeeji."

Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi