America: Àìsàn jẹ̀jẹ̀rẹ̀ pa Sẹ́nétọ̀ John McCain l'ọmọ ọdún 81

Aarẹ tẹlẹri Barack Obama ati Sẹnetọ John McCain

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Obama ṣọfọ McCain ti wón jọ du ipo aare America
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

John Mc Cain ni o ba Obama jọdu ipò aarẹ America lọdun 2008.

Ọkan gboogi ninu awọn oloselu ni ilẹ Amẹrika, John McCain ti dagbere faye ni ọmọ ọdun mọkanlelọgọrin.

John McCain jẹ oloṣelu to ni igboya lati ja fun ohunkohun to ba gbagbọ ninu rẹ de opin.

Awọn mọlẹbi rẹ to fi iroyin naa lede sọ pe ati ẹbi ati ara lo wa lọ́dọ̀ akinkanju naa nigba to papoda. America pàdánù ọ̀kan gbòógì nínú olósèlú wọn.

John McCain

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọjọ Satide ní àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní sẹ́nétọ̀ náà pinnu láti máse gba ìtójú àìsàn jẹjẹrẹ mọ́ nítorí ọjọ́ orí rẹ̀.

Ọjọ Satide ní àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní McCain pinnu láti máṣe gba ìtójú àìsàn jẹjẹrẹ mọ́ nítorí ọjọ́ orí rẹ̀.

John McCain to fi aye silẹ ni Ọjọ Satide, Osu Kẹjọ, ọdun 2018 ni aisan jẹjẹrẹ ọpọlọ ba finra fun ọpọlọpọ ọdun.

Àkọlé fídíò, 'Mi o fẹẹkan ni mo fẹ dupo aarẹ'

Awọn adari gboriyin fun John McCain to papoda

Awọn oloselu ati ọtọkulu ni awujọ ilẹ Amerika ati kaakiri agbaye ti ba ẹbi ati ara Sẹnetọ John McCain kẹdun lori iku akinkanju naa.

Aarẹ àná, Barack Obama, ti wọn jọ dije dupo aarẹ ni ọdun 2008 sọ wi pe akinkanju eniyan ati ajafẹtọ ọmọniyan saaju ifẹaraẹni ni McCain to papoda naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Awọn ọrẹ rẹ ati ojulumọ rẹ, Joe Biden ati Aarẹ tẹlẹri George W Bush se apejuwe McCain gẹgẹbi olufẹ ara ilu ati asa ati ise to mu ilosiwaju dani.

Amọ iroyin kan sọ wi pe sẹnetọ John McCain sọ ninu iwe ikeyin rẹ wi pe Aarẹ ilẹ Amerika, Donald Trump kò gbọdọ wa si ibi ayẹyẹ ikẹyin oun.

John McCain fikun pe Aarẹ Barack Obama gbọdọ wa lara awọn ti yoo sọ ọrọ ikẹyin nipa oun ni ibi ayẹyẹ isinku oun.

Tani Sẹneto John McCain?

John McCain jẹ akinkanju ajagunfẹhinti ogun Vietnam to pada wa di ọkan gboogi lara awọn oloselu ni ilẹ Amerika.

John McCain

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọdun marun un ni McCain fi jẹ ẹlẹwọn ogun Vietnam, ti o si jẹ orisirisi iya ni ọwọ awọn ti o mu u pamọ.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, ọdun 1936 ni ibugbe awọn ologun oju omi ni Coco Solo Naval Air Station ni wọn ti bi John McCain.

Ọdun marun un ni McCain fi jẹ ẹlẹwọn ogun Vietnam, ti o si jẹ orisirisi iya ni ọwọ awọn ti o mu u pamọ.

Saa mẹfa ọtọọtọ ni Sẹnetọ John McCain fi jẹ sẹnetọ, ti o si dije dupo fun Aarẹ ilẹ Amerika labẹ ẹgbẹ oselu Republican ni ọdun 2008.

Àkọlé fídíò, Mori ara mi to funfun, mi o mọ pe ẹtẹ ni
Àkọlé fídíò, Megabite: Ilé-ìwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ