Robert Mueller ló ni kọ́kọ́rọ́ ìwádìí Donald Trump àti Russia lọ́wọ́

Àkọlé fídíò, Ọ̀rọ̀ Trump àti Russia kò yàtọ̀ pé àhesọ lásán ni èyí jẹ́

Ṣe tòọ́tọ́ ni Donald Trump dìtẹ̀ pẹ̀lú Russia?

Robert Mueller to ti jẹ adari ajọ oluṣewadii FBI ri ni àwọn ọmọ Amẹrika gba pé o le foju otitọ ọrọ ẹsun Trump yii hande.

Ọkàn àwọn mii rọ̀mọ́ Michael Cohen to jẹ agbẹjọro Trump tẹlẹ nitori pe ọpọlọpọ aṣiri lo maa n wà lọwọ agbẹjọrọ onikaluku.

O le ni ọdun kan ti iwadii yii ti n lọ lọwọ ni Amẹrika.

Ilẹkẹ má já silé, ma já síta ni ọrọ aarẹ Donald Trump tilẹ Amẹrika ati Russia, ibi kan lo maa ja si lọjọ kan.