Bórípẹ́ nílẹ̀, á dire; ẹlẹ́wọ̀n méjì yóò di dókítà ọ̀mọ̀wé

Oríṣun àwòrán, Rumourspro/Facebook
Ìbẹ̀rẹ̀ kìí ṣe oníṣẹ́, àforitì ni iìpilẹ̀ṣẹ̀ ilọsiwaju ẹ̀dá
Ọga agba to n dari ileeṣẹ ijọba to n mojuto awọn ẹwọn ni Ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Tunde Ladipo, ni bii mẹtadinlọgọjọ (157) ẹlẹwọn ni yoo kọ idanwo aṣekagba ile iwe girama (WASSCE) to n bọ ni ipinlẹ naa.
Bẹẹ naa ni o tun sọ pe awọn meji ni o n kawe lati gboye ọmọwe (PhD) ni fasiti NOUN bayii. Ẹka NOUN kan wa ni inu ọgba ẹwọn Kirikiri.
Ladipo sọ fun awọn oniroyin wi pe iwe kika ti wa di oun amuyangan laarin awọn ẹlẹwọn ipinlẹ naa.

Ninu awọn mẹtadinlọgọjọ naa, awọn mọkanlelaadorun wa lati ọgba ẹwọn Ikoyi, mejila wa lati ọgba ẹwọn ti obinrin ti mẹrinlelaadọta si wa lati ọgba ẹwọn Kirikiri.
Olori ọgba ẹwọn naa ni awọn n sa ipa lati ri i pe awọn ẹlẹwọn naa ṣe daadaa ninu idanwo wọn.

Awọn onimọ nipa ọrọ ẹlẹwọn ni, ida bii meje ninu mẹwaa awọn ẹlẹwọn ni o tun maa n ṣẹ ẹṣẹ ti yoo ran wọn pada s'ẹwọn. Wọn ni idi niyi ti iwe kika ninu ẹwọn ṣe pataki fun awọn ẹlewọn.
Ọpọlọpọ awọn ẹlewọn naa lo tun maa n sọ pe, bi ko ba ṣe awọn ohun ti awọn kọ bi iṣẹ ọwọ ati iwe ninu ọgba ẹwọn, ti awọn ba jade, awọn kò ba pada si ẹnu iwa janduku ni.















