Falling Containers: Ilé ẹrù náà ló já bọ́ lé ọkọ̀ akérù lórí

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹru, taa mọ si container to to iwọn bata ogoji mita, tun ti ja bọ lori ọkọ tirela, to si ti mu ẹmi eeyan meji lọ.
Isẹlẹ naa, to waye ladugbo Ijẹsatẹdo nipinlẹ Eko ni oludari agba fajọ Lasema, Olufemi Osanyintolu fi idi rẹ mulẹ fawọn akọroyin.
Osanyintolu ni " A gba ipe pajawiri kan ni deede aago mẹwa ku isẹju mẹrindinlogun lalẹ ọjọ Ẹti, wipe ile ẹru kan tun ti ja le awọn eeyan lori.
Nigba ta de ibẹ, a ri ọkọ tirela kan ti wọn gbe Ile ẹru to to iwọn bata ogoji mita naa le lori, lo sọ ijanu rẹ nu."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọkọ̀ rélùwéè 16 yóò ná Eko sí Ibadan láti oṣù tó ń bọ̀ lọ - Iléeṣẹ́ Rélùwéè kéde
- Àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Mali ń fò fáyọ̀ pé ológun gba ìjọba mọ́ alágbádá lọ́wọ́
- Ìròyìn ayọ̀! Kùrù-kẹrẹ Coronavirus ṣeéṣe kó dópin láàrín ọdún méjì - WHO
- Géńdé agbébọn yabo àgọ́ ọlọ́pàá n‘Ibadan, ẹ̀mí ọlọ́pàá kan bọ́
- Ọba Ilorin ló pàṣẹ pé kí ń padà sọ́dọ̀ ọkọ mi - Risikat olójú búlúù
- NCDC kéde èèyàn 340 míràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà
- A fí ara mọ́ ìdájọ́ ikú Sharia tó tọ́ sí Olórin Yahaya- ẹgbẹ́ Amòfin Mùsùlùmí ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kano
Oludari agba fun ajọ Lasema tẹ siwaju ninu alaye rẹ pe idi eyi lo mu ki ọkọ akẹrun naa lọ rọ lu ọkọ ero kan to duro jẹjẹ rẹ, ti ile ẹru naa si jabọ.
"A doola ẹmi awakọ ero naa, ta si ti gbe lọ sile iwosan kan to wa nitori.

Oríṣun àwòrán, Others
Amọ ẹmi awọn obinrin meji lo ba isẹlẹ naa rin, ta si ti gbe oku wọn lọ si ile igbokusi.
Kii se igba akọkọ ree ti iru isẹlẹ yii yoo waye, eyi to ti mu ẹmi ọpọ ọmọ Naijiria lọ.
Àpótí ìkẹ́rùsí jálu ọkọ̀ méjì lórí l'Eko
Bakan naa la ti mu iroyin wa fun yin ni osu diẹ sẹyin pe apoti ikẹru si(container) lo ja lu ọkọ meji lagbegbe Maryland nilu Eko lọjọ Abamẹta.
Ọkọ Toyota Avalon ati Villager minivan ni awọn ọkọ mejeeji ọhun.

Oríṣun àwòrán, Twitter/FRSC
A o le sọ boya ẹmi ba isẹlẹ naa lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọga ajọ to n ri si ọrọ pajawiri nipinlẹ Eko Adesina Tiamiyu ṣalaye pe ọkan ninu awọn ọkọ ọhun tiẹ tun gbina.

Oríṣun àwòrán, Twitter/FRSC
Ẹnikan ti isẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe awọn tọkọ taya ti wọn wa ninu ọkan ninu awọn ọkọ ọhun mori bọ
Ẹlomiran tun sọ pe ẹni to wa ọkọ keji wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.












