Ọwọ́ ọ̀lọ́pàá tẹ́ àwọn afurasí ayédèrú apòógùn l'Eko

Oríṣun àwòrán, Abba Kyari
Ileeṣẹ ọlọpa ti ṣe awari ayederu ileeṣẹ kan nibi ti awọn kan ti n ṣe ayederu oogun oyinbo ni ilu Eko.
Ileeṣẹ ti wọn ti n ṣe oogun naa to wa ni adugbo Ikọtun-Egbe, nipinlẹ Eko, ni ileeṣẹ ọlọpa tu aṣiri rẹ lọjọru.
Ninu ikede to fi sita, Ọga Agba fun ẹka Ọtẹlẹmuyẹ kan nileeṣẹ ọlọpa, Abba Kyari fi sita l'oju opo Facebook rẹ, ọwọ tẹ afurasi mẹrin nibi ti wọn ti n ṣe ayederu oogun .

Oríṣun àwòrán, Abba Kyari
Awọn afurasi naa, Emeka Madu to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ naa, ati oṣiṣẹ mẹta; Eze Young, Chijoke Umunna ati Kingsley Obilo.
Lara ohun ti wọn ka mọ awọn afurasi naa lọwọ ni awọn Garawa to kun fun oriṣiriṣi ayederu oogun, awọn paali ayederu oogun ti wọn fẹ ẹ lọ ta, to fi mọ awọn kẹmika loriṣiriṣi ti wọn fi n ṣe awọn oogun naa.
Bakan naa ni wọn ba awọn ẹrọ agbelẹrọ ati ayederu iwe ẹri apoogun oyinbo ninu ile ti wọn n lo fun ṣiṣe awọn oogun naa.









