Diabetes - Kí ló ń fa àìsàn ìtọ̀ súgà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aisan itọ ṣuga jẹ odu lawujọ ọmọniyan lagbaye; yala laaarin mẹkunu tabi ọtọkulu, olowo tabi talaka.
Aisan itọ ṣuga eyi ti oloyinbo mọ si Diabetes jẹ aisan ti o lagbara pupọ ti o si jẹ aisan ọlọjọ pipẹ eleyi ti o nii ṣe pẹlu iye eroja adun ṣuga ti o wa ninu ẹjẹ eniyan nipasẹ eroja gulukoosi ninu agọ ara.
Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:
Irufẹ aisan itọ ṣuga wo lo wa?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Irufẹ aisan itọ ṣuga mẹrin lo wa; ṣugbọn Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, oniṣegun oyinbo kan, Dokita Ọlamoyegun ṣalaye pe meji ninu wọn ni o jẹ ilu mọọka.
- Aisan itọ ṣuga onipile akọkọ ti a mọ si Type I: Aarin awọn ọmọde ni eleyi ti wọpọ. Gẹgẹ bi Dokita Ọlamoyegun ṣe sọ, "awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn wa ni aarin ọdun mẹta, mẹwa, ki a saa sọ pe awọn ti ọjọ ori wọn ko ju ọgbọn ọdun lọ."
- Aisan itọ ṣuga onipile keji ti a mọ si Type II: eyi ni o jẹ gbajugbaja julọ laarin awọn aisan itọ ṣuga to wa lagbaye. Laarin awọn eeyan ti ọjọ ori wọn ko ju ogoji ọdun si ọgọta ọdun ni eyi ti maa n waye.
- Aisan itọ ṣuga miran ni ti inu oyun ti oyinbo n pe ni gestational diabetes: asiko ti obinrin ba wa ninu oyun ni wọn maa n ri eleyi. Irufẹ obinrin bẹẹ lee maa ni tẹlẹ ri ṣugbọn ko jẹ asiko ti o ba wa ninu oyun ni yoo ṣa dede jẹyọ.
- Aisan itọ ṣuga to nii ṣe pẹlu awọn aiṣedede miran lagọ ara. Fun apẹrẹ, ' awọn oogun kan wa fun lilo ti o maa n fa aisan itọ ṣuga tabi awọn aiṣedede miran ni agọ ara.'
Kini o nfa aisan yii?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oniruru ni ohun to lee fa itọ ṣuga. Lara ohun ti awọn onimọ bii Dokita Ọlamoyegun ati ajọ eto ilera agbaye fi sita ni ajogunba eleyi ti o lee waye bi ẹnikẹni ninu ẹbi eniyan bẹẹ ba ni.
- Awọn ohun ti eniyan njẹ tabi mu pẹlu lee faa.
- Ẹjẹ riru lee fa aisan itọ ṣuga. Gẹgẹ bi awọn onwoye ṣe sọ, bi ibeji ni aisan ẹjẹ riru ati itọ ṣuga. O wọpọ lati ri ẹni ti o ni ẹjẹ riru lai ni itọ ṣuga tabi ni itọ ṣuga lai ni ẹjẹ riru.
- Bakan naa ni bi ọra ba pọ ju lara, iyẹn ara sisan ju pẹlu lee fa aisan itọ ṣuga.










