Ìròyìn òfégè: ìwádìí lórí ayédèrú ìròyìn l'Afirika fún ọdún kan

Àwòrán àgbáyé tí ó ń fi ilẹ́ Afirika hàn pẹ̀lú ẹ̀rọ kọmputa àti fóònù
Àkọlé àwòrán, Àwòrán ayé
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Titan kalẹ iroyin ayederu nilẹ Afirika ni awọn kan ti sọ pe o n fa ija ẹlẹyamẹya ati rukerudo laarin awọn oludibo, bẹẹni o n ṣe akoba fun bi owo ṣe lọ soke ti o nlọ silẹ

Ile iṣẹ iroyin BBC ṣe iwadi lori iroyin ayederu marun un to ni ipa nla nilẹ Afirika ni ọdun kan ṣeyin.

BBC
Presentational grey line

1. Ẹgbẹ ololufẹ ọkunrin s'ọkunrin fọwọ si oludije ipo aarẹ

Kinni iroyin naa?

Lẹyin ti wọn kede Atiku Abubakar gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ ninu idibo ọdun 2019, ayederu opo Twitter kan lorukọ olori ẹgbẹ alatako fi ọrọ kan lede ti o fi ki ẹgbẹ awọn ololufẹ ọkunrin s'ọkunrin fun atilẹyin wọn.

BBC
Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

BBC

Ninu iroyin naa, ''Ọgbẹni Abubakar'' sọ pe ohun akọkọ ti oun yoo ṣe nigba t'oun ba di aarẹ ni pe oun yoo wọgi le ofin ti ko gba ki ọkunrin ati ọkunrin ẹgbẹ rẹ fẹ ara wọn eyi ti aarẹ ana, Goodluck Jonathan bọwọ lu lọdun 2014.

Fifi ifẹ han laarin ọkunrin kan si omiran lodi sofin orilẹede Naijiria, koda ẹwọn ọdun mẹrinla ni ẹni ti ọwọ ba tẹ yoo fi gbara, bẹẹni igbeyawo ọkunrin s'ọkunrin naa lodi si ofin.

Iru ipa wo ni iroyin yii ni?

BBC
Iroyin ayederu lori iwe iroyin The Nation

Oríṣun àwòrán, The Nation

Àkọlé àwòrán, Aworan iroyin ayederu lori opo ayelujara kan
BBC

Lẹyin ti awọn eeyan ti pin iroyin yii loju opo Twitter lọjọ kẹrinla osun Kẹwaa, awọn iwe iroyin ayelujara meji ba gbe iroyin ọhun. Lẹyin bi ọjọ mejila, gbajugbaja iwe iroyin meji The Nation ati Vanguard naa fi iroyin ti akori rẹ jọ iroyin yii sita.

Wọn sọ ninu iroyin naa pe ẹgbẹ awọn ololufẹ ọkunrin s'ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ ''Diverse'' n ṣatilẹyin fun Atiku Abubakar fun ipo aarẹ. Wọn ni ti gbogbo eeyan lo n ṣe.

Iroyin ofege nipa oludije fun ipo aarẹ to n ṣatilẹyin fun ololufẹ ọkunrin s'ọkunrin le fa wọn ṣeyin. Bakan naa, awọn olori ẹsin kristẹni ati musulumi le sọ fun awọn ọmọ lẹyin wọn lati maa dibo fun iru oludije bẹẹ.

Bawo ni a ṣe le mọ iroyin ayederu?

Orisun iroyin yii kii ṣe lati oju opo oloṣelu Atiku Abubakar fun ra rẹ. Oju opo rẹ 'his real account' to ni ami idamọ alawọ buluu.

Àkọlé fídíò, Fake news is often published on legitimate-looking websites

Ko si ẹri lati fihan pe ọrọ awọn ẹgbẹ ololufẹ ọkunrin s'ọkunrin wa iroyin to tan kalẹ kaakiri ayelujara. Bẹẹ ni ko si akọsilẹ fun ẹgbẹ ololufẹ ọkunrin s'ọkunrin.

Ati pe at'awọn ati agbẹnusọ fun wọn (Spinky Victor Lee), ko si ẹni to ri wọn ri lori ayelujara ko to digba ti iroyin ọhun jade lori Twitter ninu oṣu kẹwaa gẹgẹ bi iwaadi ile isẹ iroyin AFP

BBC
Presentational grey line

2. Awọn ilumọka oniroyin lorilẹede Kenya meji pin iroyin ayederu

Kinni iroyin naa?

Oniroyin ọrọ aje fun ile iṣẹ iroyin CNN Richard Quest lọ si olu ilu Kenya, Nairobi ninu oṣu kẹwaa fun eto rẹ lori ẹrọ amohunmaworan.

Akaroyin tẹlẹ ri Julie Gichuru fi iroyin kan lede lori opo Twitter rẹ lọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹwa ki awọn eeyan jiroro lori bi Ọgbẹni Quest ṣe n gbadun ara rẹ ni Kenya.

Wọnyi ni awọn iroyin to fi lede, to si sọ pe lati ọdọ Ọgbẹni Quest lo ti wa:

''Kosi ohun to dabi ile iṣẹ itura ni Kenya..awọn agunfọn yi mi ka nibi ti mo ti jẹun aarọ mi bayii! Ni orilẹede ti banki agbaye sọ pe ibẹ ni o dara lati dokowo nilẹ Afirika. ki lotun ku ti mo n fẹ? Ajẹ bi idan ni orilẹede Kenya!''

BBC
A false quote shared by former news anchor

Oríṣun àwòrán, Twitter

BBC

Iru ipa wo ni iroyin yii ni?

Awọn eeyan bi miliọnu kan ni wọn n tẹle Julie lori Twitter , bẹẹ ni awọn bi ẹgbẹta lo n tẹle e lori Instagram, laarin iṣẹju akan ẹgbẹgbẹrun eeyan lo ti ri iroyin naa ti wọn si gbagbọ ọtitọ ni.

Ọpọ tiẹ fi ṣe yẹyẹ fun aṣiṣe rẹ papaa julọ pẹlu iriri rẹ ninu iṣẹ iriyin.

Djibouti and Somalia.

Oniroyin CNN fesi si iroyin ti Julie fi lede lori Twitter pe oun o sọ ohun to jọ bẹẹ.

BBC
Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

BBC

Gichuru ni lati lọ tọrọ aforiji lori Twitter lọwọ awọn alatẹle rẹ, bẹẹ lo yọ iroyin naa kuro.

BBC
Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

BBC
Presentational grey line

3. Wọn 'ti awọn ọmọ orilẹede Somalia inu iboji' ni Ethiopia

Kinni iroyin naa?

Ninu oṣu Keje, ile iṣẹ amohunmaworan kan to wa ni orilẹede Amẹrika(ESAT) gbe fidio kan jade to ṣafihan bi wọn ti n ti awọn Oromos ni Ethiopia sinu iboji ti ko jin.

Ile iṣẹ iroyin naa ni ẹkun Oromia ni orilẹede Ethiopia ni wọn ti ya fidio naa nibi ti ikolu lile ti n waye laarin ẹgbẹ meji ninu ọdun yii.

Iru ipa wo ni iroyin yii ni?

BBC
Fidio Cameroon

Oríṣun àwòrán, YouTube

Àkọlé àwòrán, Fidio yii fihan bi wọn ti n ti oku eeyan sinu koto
BBC

BBC Afaan Oromo gbe iroyin kan jade pe itankalẹ fidio naa ṣe okunfa ikọlu awọn ẹya Oromo ti wọn n gbe ni orilẹede Djibouti ati Somalia.

Awọn atipo ẹya Oromo ti wọn wa ni Djibouti sọ fun BBC pe wọn na awọn, bẹẹni wọn ja awọn lole nitori fidio ọhun.

Bawo ni a ṣe le mọ iroyin ayederu?

Ayederu fidio yii kan naa ni wọn pin ninu oṣu kẹfa lori ayelujara ti wọn ni pe o nii ṣe pẹlu aawọ to n lọ lwọ laarin apa orilẹede Cameroon to n sọ ede oyinbo ati ijọba nibi maili to din diẹ ni ẹgbẹrun meji lapa iwọ oorun Ethiopia.

Ẹda fidio naa ti ileeṣẹ mohunmaworan ESAT TV fi han lai ṣe ayẹwo boya otitọ ni tabi ayederu, jẹ eyi ti wọn ti tọwọ bọ ti wọn si gbe agbasilẹ ohun awọn eeyan kan ti wọn pe ni awọn ọdọ ẹya Oromo ti wọn n pariwo le ori ohun tootọ to ba fidio naa jade.

Ni kete ti ESAT rii pe ayederu ni fidio naa ni wọn ti yọọ kuro lori afẹfẹ wọn ti wọn si tọrọ aforiji ni ori ikanni Youtube wọn.

Ko si ẹni n sọ pe mohunmaworan ESAT TV dọgbọn si fidio yii tabi pe wọn mọọmọ gbe e sori afẹfẹ pẹlupẹlu pe wn mọ pe ayederu ni.

Atunṣe ọjọ kẹtalelogun oṣu kọkanla: A ti ṣe atunṣe lori akọsil iroyin yii lati lee jẹki o di mim pe ESAT TV ko mọ nipa didọgbọn si fidio naa, tabi wọn mọọmọ gbe ayederu rẹ si ori afẹfẹ.

BBC
Presentational grey line

4.'Ikọwe-fiposilẹ' Aarẹ South Africa acob Zuma

Kinni iroyin naa?

Lọjọ kejila oṣu keji, akọroyin fun ile iṣẹ iroyin SABC lorilẹede South Africa sọ pe Aarẹ igba na Jacob Zuma ti gba lati kọwe fipo silẹ.

Tshepo Ikaneng lo firoyin naa lede nigba ti o n jabọ iroyin yajoyajo nibi ti ko jina si bi ti awọn ọmọ African National Congress ti n ṣepade ọjọ iwaju Aarẹ Zuma.

Oniroyin ọmọ orilẹede South Africa miran firoyin ọhun lede lori opo Twitter

BBC
Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

BBC

Wọn ti onirururu ẹsun iwa ibajẹ kan Ọgbẹni Zuma ti awọn ti ẹ ti n ṣo fun pe ko kọwe fipo silẹ.

Orilelẹede South Africa ti n reti ikọwe fiposilẹ rẹ.

Iru ipa wo ni iroyin yii ni?

Owo orilẹede naa Rand to ti gberu si lẹyin tawọn eeyan gbọ pe Aarẹ Zuma yoo kọwe fipo silẹ lọjọ kejila oṣu keji ja walẹ nigba ti agbẹnusọ ijọba sọ pe irọ ni iroyin SABC.

BBC
Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

BBC

Ṣe a mọ pe ayederu iroyin ni?

Agbénusọ fun Aarẹ Zuma naa sọrọ pe ayederu iroyin ni.

Ṣugbọn lẹyin ọjọ mẹta, Zuma pada kọwe fipo sile ni tootọ.

BBC
Presentational grey line

5. Olori orilẹede Tanzania faramọ nini ju'yawo kan lọ lati fopin agbere

BBC
Tanzania President John Magufuli

Oríṣun àwòrán, Zambian Observer

BBC

Kinni iroyin naa?

Iroyin kan to sọ pe Aarẹ orilẹede Tanzania John Magufuli sọ fun awọn ọkunrin lati fẹ ju iyawo kan lọ lati dena iwa agbere lu ayelujara pa.

Iroyin naa sọ pe aarẹ sọrọ niwaju awọn ọkunrin bi ẹgbẹrun mẹrinla, nibi to ti sọ fun pe obinrin bi aadọrin miliọnu lo wa lorilẹede naa ti awọn ọkunrin kosi ju ọgbọn miliọnu lọ.

Ọwọn ọkunrin yii lo n fa agbere papa laarin awọn obinrin, iroyin naa ni Aarẹ lo sọ bẹẹ.

Iru ipa wo ni iroyin yii ni?

Iroyin ti wọn kọkọ gbe sita ni ede oyinbo loṣu keji ọdun kọ lo da wahala silẹ.

Ṣugbọn nigba ti wọn wa gbe sita ni ede Swahili to jẹ ede apapọ Tanzania lori opo ayelujara nipasheonline.com ni ọpọ eeyan bẹrẹ si ni maa kaa.

Lati bẹ ni o ti de ori gbajugbaja opo ayelujara JamiiForums nibi ti o ti wa gbona fẹlifẹli ti o si tan ka de Kenya, South Africa, ati Ghana.

Bawo ni a ṣe mọ pe ayederu iroyin ni?

Agbẹnusọ fun ijọba orilẹede Tanzania sọrọ lori opo Twitter pe Aarẹ ko sọ ohun to jọ bẹ rara.

Bakan naa, iṣẹ iwadii BBC Swahili tun fi han pe kosi otitọ ninu iroyin ọhun.

Ninu iroyin ayederu naa, ''Aarẹ Magufuli'' sọ nipa aadọrin eeyan to wa ni orilẹede Tanzania ti awọn obinrin si miliọnu mẹwa ju awọn ọkunrin lọ

Ṣugbọn ajọ iṣọkan sọ pe eeyan to wa lorilẹede Tanzania ko ju ọgọta miliọnu lọ, bẹẹ kosi iyatọ to pọ ninu iye ọkunrin ati obinrin

Oju ayelujara ti iroyin ayederu naa ti jade le dabi gbajugbaja iwe iroyin Nipashe ni Tanzania.

Ṣugbọn ko ni nkankan ṣe pẹlu opo ayelujara fun iwe iroyin naa ti oju opo gangan jẹ https://www.ippmedia.com/sw/nipashe.

line
Fake news branding

Iroyin yii jẹ ọkan lara awọn ofege ti BBC n la awọn eeyan lọyẹ lori rẹ- iṣoro lagbaye ti o doju kọ bi a ti n pin iroyin, ti a ṣe n gbọ layika wa.

Lati ka si nipa iṣẹ iwadi yii , lọ si opo ayelujara yii www.bbc.co.uk/fakenews

line