Ọkọ àtìyàwó tó sọ ọmọ wọn ni Adolf Hitler wọ wàhálà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Tọkọtaya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Tọkọ-taya kan to sọ ọmọ wn ni Adolf Hitler ti wọ wahala lẹyin ti iwadi fi idi rẹ mulẹ pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ́ agbesunmọmi kan.

Ile ẹjọ Crown Court to wa ni Birmingham sọ pe tọkọ-taya naa sọ ọmọ wọn ni Adolf lati fi bu ọlá fun olori ikọ̀ NAzi to ti papoda.

Wọn fi ẹsun kan Adam Thomas, ẹni ọdun mejilelogun, ati Claudia Patatas, ẹni ọdun mejidinlogoji, to fi mọ Daniel Bogunovic, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ́ ọlọtẹ National Action.

Claudia Patatas, Adam Thomas ati ọmọ wọn

Oríṣun àwòrán, West Mids Police

Àkọlé àwòrán, Tọkọ-taya Patatas ati Adam Thomas sọ ọmọ wọn ni Adolf nitori ifẹ ti wọn ni si Hitler

Ṣaaju asiko yii ni wọn ti fi ofin de ẹgbẹ National Action nilẹ Gẹẹsi, lẹyin ọdun mẹta ti wọn bẹrẹ rẹ l'ọdun 2013, ti wọn si ṣe ajọyọ lẹyin ṣiṣekupa aṣofin Jo Cox..

Ile ẹjọ sọ pe ẹjọ́ naa da lori i idunkooko mọni to n jẹyọ lati ara igbagbọ pe awọn alawọ funfun ni laari ju awọn ẹya to ku lọ.

Àkọlé fídíò, Ìwẹ̀ wíwẹ́ má n dín agbára ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn kù

Ileeṣẹ ọlọpa sọ pe awọn ba àdá meji, ọfà, to fi mọ ọpọlọpọ àsìá ati awọn nkan mi i to jẹ ami idanimọ asiko ti ikọ Nazi n dari, ati ti National Action ti wọn fi ofin de, ni yaara ibusun Thomas ati Patatas.

Sugbọn ninu ọrọ rẹ, Thomas sọ pe aṣọ ẹgbẹ́ okunkun ti oun fi ya aworan jẹ eré lasan, ṣugbọn o gba pe lootọ ni oun n dẹ́yẹ si awọn ẹ̀yà to ku.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila ni wn yoo ṣe idajọ wọn.