Akeredolu: Àwọn akọ̀ròyìn tó fẹ́ sọ ilé ìjọba di ilé ọtí àti tẹ́tẹ́ ni mo lé dànù

Gomina Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu

Àkọlé àwòrán, Ni ọjọ Aje ni ijọba ipinlẹ Ondo kede pe wọn ti le awọn akọroyin ileeṣẹ meji kan kuro ni ọfiisi gomina ipinlẹ naa

Lẹyin ti iroyin tan kalẹ pe o le awọn akọroyin ileeṣẹ iroyin kan kuro ni ile ijọba ni ilu Akurẹ, gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti ṣalaye pe awọn akọroyin to fẹ sọ ile ijọba di ile ọti ati tẹtẹ ni oun gbọn yọ kuro ni ibudo awọn akọroyin ijọba to wa ni sẹkitariati ijọba ipinlẹ naa ni ilu Akurẹ.

Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣọna fun eto iroyin, Yẹmi Owolabi fi sita ni ọjọ Iṣẹgun, igbesẹ ti ijọba gbe wa "lati le awọn alatẹnujẹ ati awọn ti ko tọ ti wọn n pe ara wọn ni oniroyin kuro ni ile ijọba ni."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu atẹjade naa, o ni awọn oniroyin ti wọn le ni awọn ti o fẹ sọ "yara iroyin to wa ni ofiisi gomina di ile ọti ati ile tẹtẹ pẹlu ibuba awọn abanilorukọ jẹ gbogbo."

O ni lootọ iroyin ti n lọ kaakiri ori ayelujara pe ijọba ipinlẹ naa ti di ọna mọ awọn akọroyin kan lati maa le ṣe iṣẹ wọn, ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn oniroyin ti ko mọ iṣẹ wọn ni iṣẹ ni awọn le kuro ni ile.

Àkọlé fídíò, 'Olórí ìjọ wa kò fẹ́ràn Daddy Freeze'

Amọṣa iwadi ti BBC News Yoruba ṣe pẹlu awọn akọroyin kan to n ṣiṣẹ ni ipinlẹ ondo fidi rẹ mulẹ pe awọn akọroyin yii ko tilẹ ki n mu ọti de ibi ti wọn yoo tilẹ maa mu amupara.

Awọn ileeṣẹ akọroyin ti ọrọ kan, Channels Television ati AIT, ko tii sọ ohunkohun lori ẹsun naa.