Yemi Osinbajo: Ìpínlẹ̀ Ondo lè bọ́ Naijiria pẹ̀lú ohun àlùmóọ́nì rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu
"Ipinlẹ Ondo ni ohun alumọni to le bọ awọn ara orilẹede Naijiria ti wọn ba lo awọn ohun alumọni yii fun imugboro ọrọ ajẹ lorilẹede Naijria".
Kọmisọnna fun eto isuna ni ipinlẹ Ondo, Emmanuel Igbasan fi idi ọrọ yii mulẹ, lẹyin ti igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yemi Osinbajo sọ pe ipinlẹ Ondo ni ọpọlọpọ ohun alumọni kaakiri ipinlẹ naa.
Kọnisọnna Igbasan fikun ọrọ rẹ wi pe ipinlẹ Ondo ni ibudokọ okun to jin julọ ni ilẹ Afirika(largest sea port) to le gba awọn ọkọ nla nla , eyi ti o le pese ibudokọ fun awọn oko oju omi ti wọn ba n kẹru bọ lati oke okun wa si Naijiria.
Ohun alumọni to wa ni ipinlẹ Ondo
- Okun to jin julo nilẹ Afirika
- Bitumen- ekeji to tobi julọ lagbaye
- Cocoa - 240 tonnes ni wọn n gbe lọ si oke okun
- Ilọ ọlọra ati oju ọjọ to sunwọn
- Ohun ere oko bii agbado,ọgẹdẹ lorisirisi, ẹgẹ, eso, ẹfọ, irẹsi, obi, epo pupa, rọba, isu, ẹran ọsin,
Ki lo sẹlẹ si awọn ohun alumọni ipinlẹ Ondo?
Kọmisọnna fun eto isuna ni ipinlẹ Ondo ninu ọrọ rẹ sọ wi pe aibikita lo mu ki awọn ohun alumọni to wa ni ipinlẹ Ondo ni ifasẹyin.
Ninu ọrọ rẹ, Emmanuel Igbasan fikun wi pe epo bẹntiroolu ti ijọba gbe ọkan le lo mu ki wọn fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn ohun alumọni ti Ọlọrun ti fi fun ipinle naa.
O fikun wi pe nitori epo bẹntiroolu ti lọ silẹ lagbaye bayii, ijọba ti pada si ohun alumọni ati agbẹ to lere gẹgẹbi ọna lati mu ki ibugboro ba ọrọ aje Naijiria.
Kọmisọnna naa fikun wi pe laipe si isinyii ipinlẹ Ondo yoo ma a pese "sweet" ati ohun ipanu awọn ọmọ ile iwe bii "sunshine chocolate" lati ara cocoa.
Aṣòfin 18 sá àsálà kúrò nípínlẹ̀ Ondo
Awọn aṣofin mejidinlogun ti wọn yọ olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo ati igbakeji rẹ, ti sa fi ipinlẹ naa silẹ.
Ohun ti awọn aṣofin naa ni o faa ti wọn fi sa kuro ni ilu Akurẹ ko ṣẹyin bi wọn ṣe ni abo to peye ko si fun ẹmi awọn lati igba ti wọn ti yọ olori ile naa tẹtẹ nipo.

Oríṣun àwòrán, Ondostate house of assembly
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lẹyin ti awọn aṣofin naa yọ Bamidele Ọlẹyẹloogun ati igbakeji rẹ Ogundeji Iroju nipo ni awọn janduku ti iroyin sọ pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ awakọ ero NURTW nilu Akurẹ ya bo ile aṣofin naa ti wọn si lu awọn aṣofin ati oṣiṣẹ ti ọwọ wọn ba.
Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, olori tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan fun ile naa, Ọlamide George ni ilu Ibadan ni awọn sare wa fi ara sinko si nitori abo ẹmi wọn.

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu
"A ni lati sa kuro nilu nitori ko si abo fun ẹmi wa mọ. Ẹmi mi, ẹbi mi ati awọn aṣofin ẹgbẹ mi lo wa ninu ewu, idi si niyii ti a fi fi ilu silẹ wa fi ara pamọ si ilu Ibadan."
"A si ti fi asiko yii kigbe iranwọ si aarẹ Buhari ati ọga ọlọpa lorilẹede yii lati wa gba wa silẹ."Ni ọjọ ẹti ti o kọja ni awọn aṣofin mejidinlogun ninu mẹrindinlọgbọn to wa ni ile naa dibo yọ olori ile naa ati igbakeji rẹ lori ẹsun iwa aitọ, ṣiṣe owo baṣubaṣu, ṣiṣi agbara lo ati aikun oju iwọn lẹnu iṣẹ.
'Gómìnà Akeredolu lọ́wọ́ nínú wàhálà ilé aṣòfin Ondo'
Aṣofin Olamide George ti wọn yan sipo lẹyin ti awọn aṣofin kan panupọ yọ olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo nipo ti fi ẹsun kan gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu pe o lọwọ ninu wahala ti o n waye laarin aṣofin ipinlẹ naa.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, aṣofin George ni idi ti awọn aṣofin mejidinlogun fi gbe igbesẹ ati yi adari ile naa pada ko ju wi pe awọn aṣofin ipinlẹ naa ko lanfani lati ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bii iṣẹ ti awọn araalu fi ran wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ni gomina Akeredolu lo ko awọn agbofinro fun olori ile ti wọn yọ, Bamidele Ọlẹyẹlogun lati pada lọ ṣi ijoko ile lẹyin ti wọn ti yọọ.
"Gomina lọwọ sii ni. Nitori a gbọ pe lẹyin ti a yọ awọn adari ile tẹlẹ kuro, a gbọ pe awọn mẹfa ko ara wọn jọ lati pada lọ joko yi ohun ti awa mejidinlogun fi ẹnu ko le lori. Ti gomina si ko agbofinro tẹle wọn. Eyi ko yẹ ko ri bẹẹ rara.
Nigba to n sọrọ siwaju, o ni irọ ni pe awọn ti ko ni anfani ati pada ni wọn n da wahala silẹ.
" Emi ti mo n sọrọ yii, mi o ra fọọmu pe mo fẹ dibo, nitorinaa ko si ẹni to lee sọ pe aini anfani ati pada si ile aṣofin lẹẹkan sii lo n faa."
Bakan naa lo fi kun un pe bi ọrọ ṣe ri yii, ẹsẹ ofin ni awọn yoo tọ lori ọrọ naa.
'Awọn aṣofin naa fẹ yọ emi ati gomina ipinlẹ Ondo nipo ni'
Amọṣa, olori ile naa ti wọn yọ nipo, Bamidele Ọlọyẹloogun ni mimi kan ko mi ohun kuro lori aga olori ile naa.
Ninu ọrọ ti oun pẹlu ba BBC News Yoruba sọ, awọn aṣofin ti ọrọ kan fẹ yọ oun ati gomina ipinlẹ naa nipo ni.
Wọn ya mi laṣọ, wọn na gbogbo awọn amugbalẹgbẹ mi. Mo si bi wọn pe ko si ijoko loni, emi nikan gẹgẹ bii olori ile nikan lo lee pe ipade ijoko ile."
Aṣofin Ọlẹyẹloogun ni ko si ohun to jọ janduku ni ile aṣofin naa ati pe awọn agbofinro wa nikalẹ. O ni o ṣeeṣe ko jẹ ẹhonu lori awọn ẹtọ to yẹ ati bi awọn kan ko ṣe ni anfani ati dije fun ijoko ile naa ni ibo ọdun 2019 wa lara ohun ti o n fa ikunsinu wọn.
O fi kun un pe igbesẹ alaafia yoo bẹrẹ ni ọsẹ ti o nbọ lati pa ina aawọ laarin wọn.
Ondo: Yánpọnyánrin ní ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ondo nítorí olórí tuntun

Oríṣun àwòrán, APC Ondo
Ọrọ di iṣu ata yan-an-yan-an ni ile aṣofin ipinlẹ ondo lọjọ ẹti pẹlu bi awọn aṣofin meji ṣe n pe ara wọn ni olori ile naa.
Gẹgẹ bi BBC News Yoruba ṣe gbọ, ọrọ naa bẹrẹ ni owurọ ọjọ ẹti nigba ti awọn aṣofin mejidinlogun ninu mẹrindinlọgbọn to wa ni ile naa dibo yọ ni ile olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo, Bamidele Oloyelogun ati igbakeji rẹ, Iroju Ogundeji kuro nipo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Oloyelogun ti wọn yọ nipo wa lori ijoko ni gbogbo asiko ti ariwo ati ys loye fi n waye.
Iroyin ọhun tun fi kun un pe idarudapọ waye ninu gbọngan ile aṣofin ọhun lẹyin ti igbesẹ ati yọ olori ile naa ati igbakeji rẹ ti waye tan pẹlu bi awọn janduku kan, ti awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero, NURTW ti ṣe ya wọ ile aṣofin naa ti wọn si le gbogbo awọn aṣofin atawọn oniroyin to fi mọ awọn oṣiṣẹ nile aṣofin naa da sigbo.
Koda iroyin naa fidi rẹ mulẹ pe awọn janduku naa tun ya aṣọ mọ olori ile naa tẹlẹ, Jumọkẹ Akindele lọrun lasiko ti gbogbo rukerudo yii fi waye.
Lẹyin eyi ni olori ile naa ti wọn ys nipo, Bamidele Oloyelogun atawọn to jẹ tirẹ ni ile aṣofin naa lọ ko ara jọ pọ ni ile rẹ nibi to ti ba awọn oniroyin sọrọ pe oun ṣi ni olori ile naa ati pe ohun ti ko lẹsẹ nlẹ ni igbesẹ naa.
Ni kete ti o pari ipade pẹlu awọn oniroyin yii ni o pada laarin ọpọ ọkọ, awọn janduku ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW ati awọn oṣiṣẹ alaabo lọ si ile aṣofin naa nibi ti oun ati awọn aṣofin mẹwa ti wọn fẹ tirẹ ni ile naa tun ti gbe ijoko mira kalẹ ti wọn si yọ paṣẹ lọ rọkun nile fun awọn aṣofin marundinlogun ti wọn ni wọn fi gbogbo ara kopa ninu igbesẹ lati yọọ nipo.
Kini ohun ti o n rugbo lagbo oṣelu nipinlẹ Ondo?
"Kii ṣe aṣiri to bo rara laarin agbami oṣelu nipinlẹ Ondo ati laarin awọn onwoye oṣelu nibẹ pe ọdọ gomina Rotimi Akeredolu ni olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo, Bamidele Oloyelogun ti wọn yọ kuro nipo fi ara ti si"
Eyi ni ọrọ ọpọ awọn onwoye to ba BBC News Yoruba sọrọ sọ.
Ni oṣu diẹ sẹyin ni wọn ti kọkọ yọ Bamidele Oloyelogun kuro ni ipo gẹgẹ bii olori ile naa ṣugbọn ti wọn ni gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu paṣẹ ki wọn daa pada sipo.
Amọṣa ohun ti wọn ni o ṣeeṣe ko fa ti ọtẹ yii ko fẹẹ ṣẹyin bi pupọ awọn aṣofin ile naa ko ṣe ni anfani ati oreọfẹ pipada dije fun ijoko ile ni ọdun 2019 naa lasiko idibo abẹle ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣe kọja.
Ni bayii, olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo, Bamidele Oloyelogun ati igbakeji rẹ, ti wọn yọ kuro nipo atawọn aṣofin mẹwa to jẹ tirẹ ti so ijoko ile aṣofin naa rọ di ọjọ miran ọjọ ire.
Nigba ti awọn akọroyin bere idi ti o fi ti ile pa, aṣofin Oloyelogun ni "ofin ilana ile fun oun laṣẹ lati ṣe bẹẹ."
Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ondo yan olórí tuntun

Oríṣun àwòrán, DailypostNigeria
Iroyin to tẹ BBC news Yoruba lọwọ ṣalaye pe nibi ijoko ile naa to waye ni ọjọ ẹti lawọn aṣofin mejidinlogun to wa nile aṣofin naa.
Nibayii, wọn ti yan Ọlamide George lati ẹkun ididbo ipinlẹ ti Akurẹ North gẹgẹ bii olori ile aṣofin naa nigba ti Abimbọla Fajolu lati ẹkun idibo Oluji/Okeigbo si bs si ipo igba keji.
Ẹsun ti wọn fi kan awọn mejeeji ti wọn yọ nipo naa ni iwa ibajẹ lẹnu iṣẹ.
Alaga igbimọ ile lori eto iroyin, aṣofin Fatai olotu ṣalaye fun awọn oniroyin lẹyin ijoko ile pe ẹsun ṣise owo baṣubaṣu, aikun oju iwsn lẹnu iṣẹ ati ẹsun miran ni wọn tun fi kan Bamidele Oloyelogun ati igbakeji rẹ, Iroju Ogundeji ki wọn to yọọ
Wọn ti yọ olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo, Bamidele Oloyelogun ati igbakeji rẹ, Iroju Ogundeji kuro nipo.
Iroyin to tẹ BBC news Yoruba lọwọ ṣalaye pe nibi ijoko ile naa to waye ni ọjọ ẹti lawọn aṣofin mejidinlogun to wa nile aṣofin naa.
Iroyin ọhun tun fi kun un pe idarudapọ waye ninu gbọngan ile aṣofin ọhun lasiko ti igbesẹ ati yọ olori ile naa ati igbakeji rẹ fẹ waye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni bayii, wọn ti yan Ọlamide George lati ẹkun idibo ti ariwa Akurẹ North gẹgẹ bii olori ile aṣofin naa nigba ti Abimbọla Fajolu lati ẹkun idibo Oluji / Okeigbo si ipo igba keji.
Ẹsun ti wọn fi kan awọn mejeeji ti wọn yọ nipo naa ni iwa ibajẹ lẹnu iṣẹ.
Alaga igbimọ ile lori eto iroyin, aṣofin Fatai olotu ṣalaye fun awọn oniroyin lẹyin ijoko ile pe ẹsun ṣise owo baṣubaṣu, aikun oju iwsn lẹnu iṣẹ ati ẹsun miran ni wọn tun fi kan Bamidele Oloyelogun ati igbakeji rẹ, Iroju Ogundeji ki wọn to yọọ.




















