Car Race: Elizade àti Akeredolu kópa nínú ìdíje eré sísá ni Ondo

Àkọlé fídíò, Car Race: Elizade àti Akeredolu kópa nínú ìdíje eré sísá ni Ondo

Ijọba ìpínlẹ̀ Ondo atawọn agbatẹru mii ni wọn fọwọsowpọ ṣeto idije eré sísá pẹlu ọkọ̀ tọdun yii ni Akurẹ ati Ilaramọkin.

Idije erẹ sisa pẹlu ọkọ̀ wọpọ lawọn orilẹ-ede to ti goke agba bii Amẹrika ni eyi ti wọn fi n pa owó gọbọi.

Bayii, ipinlẹ Ondo naa ti ja ere idaraya naa lójú ni Naijiria, àwọn akọṣẹmọṣẹ nipa idije naa nikan ni wọn fun laaye lati dije ninu tọdun 2018 nitori ewu to rọ mọ idije naa pọ.

Pataki idije yii ti Oloye Adeọjọ ti Elizade ati gomina Akeredolu to n tukọ ipinlẹ Ondo mẹnuba lasiko idije naa ni pe, yoo ṣí ojú awọn ọ̀dọ́ si ere idaraya mii to le maa pa owó wọle fun wón, ati pe yoo mu idagbasoke ba eto irin ajo afẹ́ àti ọrọ aje nipinlẹ Ondo.

Taiwo Fatimẹhin, Muyiwa Akintola, Omatseye Robinson atawọn oludije miran to kopa ninu idije ere sisa tọdun 2018 sọrọ lori ewu to rọ mo idije naa ati awọn ilana ti wọn ti la kale nilẹ okeere ti o n din awọn ewu naa ku.

Wọn sọrọ lori kikọ nipa ere sisa naa sii ki ẹnikẹni to lè kopa ninu ere idaraya naa.