Somalia: 'Wọ́n pàṣẹ fún mi láti dá Ramla dúró ká tò lè ṣe igbeyàwó'

Àkọlé fídíò, Somalia: 'Wọ́n pàṣẹ fún mi láti dá Ramla dúró ká tò lè ṣe igbeyàwó'

Ọpọlọpọ ọdun ni Ramla Ali fi n kan ẹ̀ṣẹ́ ni kọ̀ọ̀rọ̀ ki ọgbọ́n ọkọ rẹ to fún un ni ominira si gbangba.

Ramla ṣalaye fun BBC pé àwọn òbí oun kò kọ́kọ́ fọwọ si i ṣẹ to wu oun yii nitori pe wọn ko ri ọmọbinrin musulumi to n kan ẹ̀ṣẹ́ rí.

O ni ìbẹ̀rù kini àwọn eniyan yoo sọ nipa pé musulumi obinrin ni oun lo kọkọ dena itẹsiwaju oun.

Richard Moore to jẹ ọkọ ati olukọni fun Ramla sọrọ lori igbagbọ rẹ nipa ki obinrin ni ominira lati ṣe ohunkohun to ba wuu fun itẹsiwaju.

O mẹnuba idojukọ ti oun ni ki wọn to gba pe ki oun fẹ Ramla ni Somalia.

Anisa Maye Maalim, to jẹ iya Ramla ni ibẹru pé oun ko ri obinrin musulumi to n ṣere idaraya ri ni oun ko ṣe kọkọ fọwọ si i ṣẹ́ Ramla.

Ṣugbọn bayii ti ojú ti la sii, ti wọn ti n ri ògo ti Ramla n gbe wa fun Somalia, o ni gbogbo eeyan ti tẹwọgba iṣẹ́ Ramla.

Ireti Ramla ni pe ki oun lè ṣoju Somalia nidije Olympics tọdun 2020 to m bọ lọna.

Oriṣiiriṣi ami ẹyẹ tilẹ Gẹẹsi ni Ramla ti gab bayii lẹnu kikan ẹ̀ṣẹ́.