Human trafficking: Ọlọpàá Spain mú ènìyàn mọkànlá tó ń fi àwọn obìnrin Nàìjíríà ṣòwò aṣẹwó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọ awọn agbofinro lorilẹ-ede Spain ti tẹ eniyan mokanla lori ẹsun pe wọn n ko awọn ọmọbinrin Naijiria wa sorilẹ-ede naa lati fi se owo aṣẹwo.
Wọ́n mu wọn nilu Zaragoza nibi ti awon ọlọpaa ti doola ẹmi awọn obirin mẹrindinlogun lọwọ awọn to'n gbe won wa si ile okeere lati sowo nabi.
Wọn ni, iwadii fi han pe awọn onigbọwọ owo nabi yi maa n fi oogun halẹ mọ awọn ọmọbinrin naa lọri ẹro ibanisọrọ ni lati se ifẹ ti wọn.
Bakan naa ni awọn onigbọwọ owo nabi yi nfi ipa gba gbese tawọn ọmọbinrin naa ba jẹ wọn eyi to nii se pẹlu owo ti wọn fi gbe wọn lati Naijiria lọ silẹ okeere .

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn n fi ẹtan gbe awọn obinrin naa kuro nilu Benin wi pẹ igbe aye to rọsọmu n duro de wọn nile Yuroopu.
Lẹyin igba ti wọn de Spain ni wọn sọ fun wọn pe, wọn yoo ma sisẹ nabi lati le da owo irinna wọn pada.
Awọn iya isalẹ wọnyi a si maa dunkooko mọ wọn lori foonu pe wọn ko gbọdọ ṣalai sika adehun ti wọn sẹ.
Ẹgbẹ amunisin ọhun la gbọ wi pe wọn pẹka de orilẹ-ede Italy, Germany ati Denmark.













