Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ni àwọn ènìyan ń bèèrè lọ́wọ́ Buhari lásìkò yí

Oríṣun àwòrán, @MBuhari/Twitter
- Author, Busayo Akogun
- Role, Broadcast Journalist, BBC Yoruba
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti fi èrò ọkan wọn han lori ohun ti wọn yoo ba Aarẹ Muhammadu Buhari sọ ti wọn ba ni anfaani iṣẹju meje pere lati ba a sọrọ.
Awọn ọmọ Naijiria ọhun fesi si ibeere kan ti BBC News Yoruba fi sita loju opo Facebook rẹ pe 'Ti ẹ ba ni anfaani iṣẹju meje pẹlu Aarẹ Buhari, ki lẹ o ba a sọ?''
A si ṣe akojọpọ diẹ lara awọn nkan ti wọn sọ.

Ọ̀kan lara wọn, Adeniji Jacobson Gbenga sọ pe oun yoo ni ''ki Aarẹ Buhari o fi kurani bura fun mi pe ìwé ẹri ti ajọ WAEC fun òun kii se ayederu".
Laipẹ yii ni awuyewuye waye lori esi idanwo WAEC ti Buhari ṣe nigba to pari ileewe girama. Ọpọlọpọ eniyan lo n sọ pe Buhari ko joko sẹ idanwo naa.
Lati ọdun 2015 to si ni awuyewuye naa ti di gbajugbaja, nitori pe Buhari ko fun ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, ni iwe ẹri rẹ gẹgẹ bi ara ohun ti wọn n gba lọwọ ẹnikẹni to ba fẹ ẹ dupo oṣelu ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Ohun ti Buhari sọ nigba naa ni pe ọwọ ileeṣẹ ologun ni iwe ẹri oun wa, ti awọn eniyan si n sọ pe to ba jẹ lootọ ni, ki ileeṣẹ ologun fi sita.
Awuyewuye naa lọ silẹ diẹ ko tun to di ọdun 2018 ti Buhari tun kọ lati fun ajọ INEC ni iwe ẹri naa nitori pe o fẹ tun dije fun ipo aarẹ l'ọdun 2019. Lẹyin ti ariwo pọ ni Buhari mu iwe ẹri kan lọ fun ajọ naa, eyi to tun bẹrẹ awuyewuye mi i.
Minisita meji ninu eto iṣakoso Muhammadu Buhari ni wọn fi ẹsun ayederu iwe ẹri agunbanirọ kan; Kẹmi Adeọṣun ati Adebayọ Shittu.

Diẹ lara awọn to dahun ibeere ọhun n fẹ ki Aarẹ Buhari sọ owo oṣu awọn oloṣelu dọgba pẹlu t'awọn oṣiṣẹ ijọba ni Naijiria.
O ṣeeṣe ki esi wọn yi jẹyọ nitori ẹkunwo oṣu ti ẹgbẹ́ oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC, n beere fun. Ẹgbẹ́ naa n fẹ ki ijọba maa san ọgbọ̀n ẹgbẹrun Naira gẹgẹ bi owo oṣu fun oṣiṣẹ to kere ju.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari/Twitter
Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Buhari ko ti i le sọ owo oṣu tuntun naa di ofin, lai jẹ pe ile aṣofin buwọlu, ọpọlọpọ awọn gomina Nairia ti sọ pe awọn ko le san ju ẹgbẹrun mejilelogun atẹẹdẹgbẹta Naira.
Maa sọ fun Buhari ko jawọ ninu oṣelu
Awọn kan to tun kopa ninu ibeere naa ni awọn yoo gba aarẹ Buhari ni iyanju tabi sọ fun pe ko fẹhinti ninu oṣelu, ko si pada si ilu rẹ, Daura nipinlẹ Katsina.
Lara wọn gbagbọ pe Buhari ti dagba kọja ẹni to yẹ ko wa lori aga iṣakoso. Igba akọkọ kọ niyi ti imọran yii jade si Buhari.
Awọn kan si gba pe iṣakoso rẹ ko so eso rere fun orilẹede Naijiria. Sugbọn eyi ko di Buhari lọwọ lati ma polongo ibo fun ọdun 2019.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ṣaaju ọdun 2015 to ti bọ si ipo aarẹ Naijiria ni ọpọ ọmọ orilẹede yii ti n pariwo pe ọjọ ori rẹ ko ni i jẹ ko ṣaṣeyọri nipo. Awọn kan si ti n sọ pe ọrọ wọn ọhun ti wa si imuṣẹ nitori bi Buhari ṣe ti lọ si ilẹ okeere lati gba itọju ni awọn asiko kan.
Ki Buhari wa nkan ṣe si itajẹsilẹ
O ti pẹ ti ija ẹsin ati ẹ̀yà ti n waye ni orilẹede Naijiria, paapa ni ẹkùn Ariwa. Ṣugbọn awọn kan gbagbọ pe ipaniyan ati ija ẹsin peleke si ni asiko eto iṣakoso Buhari.
Ipaniyan wọpọ l'awọn ipinlẹ bi i Kaduna, Plateau ati Benue. Bakan naa ni ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram naa n ṣọsẹ l'awọn ipinlẹ kan.
Ọpọ gbagbọ pe Buhari kọ lati koju awọn Fulani ti awọ̀n eeyan n fi ẹsun ipaniyan jakejado Naijiria kan, nitori pe o jẹ ẹ̀yà kan naa pẹlu wọn.

Buhari, dakun mu adinku ba owo epo bẹtiro
Awọn kan n fẹ ki Aarẹ Buhari din iye ti wọ̀n n ta jaala epo bẹtiro ku.
Ọdun 2016 ni ijọba Buhari kede alekun owo epo, to si yi i pada kuro ni naira mẹtadinlaadọrun to wa tẹlẹ si naira marundinlaadọjọ.
Alaye ti minisita keji fun ọ̀rọ̀ epo rọ̀bi, Ibe Kachikwu, ṣe nipe ijọba gbe igbesẹ naa lati fopin si ọwọn gogo epo bẹtiro to maa n waye.

Oríṣun àwòrán, AFP
Owo epo to le si ni awọn kan gbagbọ pe o n mu inira ba awọn to n gbe ni orilẹede Naijiria, nitori bi owo ounjẹ, ile, owo ọkọ, ati awọn nkan mi i ṣe lewo si.

Ijọba buhari kun fun iwa ijẹkujẹ
Awọn kan gbagbọ pe Aarẹ Buhari kuna ninu ẹ̀jẹ́ to jẹ lasiko ipolongo ibo pe iṣejọba oun yoo gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, ti oun yoo si fi ofin fiyajẹ awọn to ti ko owo ilu jẹ.
Lootọ ni ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, ti tẹ awọn oloṣelu kan to hu iwa ibajẹ, ṣugbọn awọn kan n koro oju si Buhari pe awọn ọmọ 'to jẹ ọ̀tá iṣakoso rẹ' nikan lo n fi igbesẹ rẹ gbogun ti.
Ẹgbẹ oṣelu alatako gboogi, Peoples Democratic Party, PDP, tilẹ n sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ́ awọn nikan ni Buhari doju ogun kọ, ti ko si gbe igbesẹ kan naa si ẹsun ti wọn fi kan awọn ọmọ ẹgbẹ́ All Progressives Congress to jẹ ti ẹ.

Ni ipari, ọ̀kan lara awọn olukopa, Mercy Mercy, n fẹ ki Buhari fi opin si eto isinru ilu, NYSC. O gba a nimọran pe ki ijọba maa ko owo to yẹ ki ọ̀dọ́ kọọkan o gba ninu eto isinru ilu fun un to ba ti n kẹkọ jade nileewe giga.

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
O ni wọn yoo le lo o lati fi da iṣẹ́ silẹ fun ara wọn, lati le koju iṣoro airi iṣẹ́ ṣe.
Igba akọkọ kọ niyii ti ipe lọ si ọ̀dọ̀ ijọba lati f'opin si eto isinru ilu, paapa nitori bi awọn agunbanirọ sẹ maa n padanu ẹmi wọn nibi ti wọn ti n sinru ilu.
Awọn agunbanirọ padanu ẹmi wọn lasiko awọ̀n eto idibo kan to ti waye ni Naijiria, ati ninu awọn iṣẹlẹ mi i.













