#KẹmiAdeọṣunNYSC: Ìwádìí yóò bẹ̀rẹ̀ lóri ayédèrú iwé

Oríṣun àwòrán, NYSC/twitter
Ajọ tó n ri si ètò àgunbaniro lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NYSC) ti fèsì lórí awuywuye tó gbòde lóri ìwé ẹ̀rí ìsinlẹ̀ rú baba ẹni nípa Minisità fún ètò ìsúná Kemi Adeosun.
Wọn ni ìwádìí yóò bẹ̀rẹ̀ ní perewu láti mọ bi omi ṣe tẹ̀yìn wọgbín lẹ́nu lóri ọ̀rọ̀ náà.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ajọ náà ní ẹni tó ba ti pe ọmọ ọgbọn ọdun kò lè ni ànfààní láti sìnrú ìlú bàbá rẹ̀.
NYCS sọ èyí di mímọ nínú àtẹjáde kan tí adari èto ìfọ̀rọ̀léde Adeyemi Adenike fí síta, sàla[yé pé nínú akọsílẹ̀ àwọn, o fi han pe Adeosun kọ̀wé ránṣẹ́ láti gbààyè, sugbọn ìwádìí yóò wáyé lóri ọ̀rọ̀ náà.
Asiko ko dẹrun fun minisita fun eto iṣuna lorilẹede Naijiria, Kẹmi Adeoṣun lọwọlọwọ pẹlu iroyin kan to n ja kaakiri bayii pe ó lo ayederu iwe ẹri iyọnda kikopa gẹgẹ bi agunbanirọ.
Ileesẹ iroyin ori ayelujara kan, 'Premium times' lo gbee sita pe minisita naa ko ṣe isinruulu lẹyin to pari ẹkọ giga rẹ ni fasiti Polytechnic of East London ni ilẹ Gẹẹsi, gẹgẹ bi ofin ṣe laa silẹ fun gbogbo awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn ko tii to ọgbọn ọdun lorilẹede Naijiria.
Iwe iroyin naa ni lasiko ti minisita pari ẹkọ rẹ ko tii pe ọmọ ọgbọn ọdun ati pe lẹyin ọpọlọpọ ọdun ni arabinrin Adeọṣun to lọ gba iwe ẹri to wa fun awọn ti wọn yọọ lẹ kuro leto isinruulu nitori ọjọ ori wọn eleyi ti iwe iroyin naa ni iwadi awọn fihan pe ayederu ni.
Ẹ̀wẹ̀, ọ̀rọ̀ náà ti ńtàn kálẹ̀ débi pé lorí ẹ̀rọ ayélujára, àti Kẹ́mi Adeọsun, àti ìjọba àpapọ̀ ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ti ń nàka sí. Fún àpẹẹrẹ lójú òpò Twitter, ènìyàn kan sọ pé "bí ó bá jẹ́ lóòótọ́ ni Mínísítà fún ètò ìsúná kò ṣìnrú ìlú tí ó sì mú ayédèrú ìwé ẹ̀rí jáde, kò tọ́ sí ipò tí ó wà bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n gbúdọ̀ rọ̀ọ́ lóyè."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bákan náà, JJ Ọmọjuwà tẹ̀ẹ́ síta wípé "dídákẹ́ Kẹ́mi Adéọ̀ṣun ti bábá pariwo ara rẹ̀. àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ti lóòrìn tó sùgbọ́n bí ó ṣe kan àwọn aṣòfin lórí ẹ̀sùn tí wọ́n ń fi kàn án, o tí wá sọ ọ di ọ̀rọ̀ tó le tí ǹkan gbúdọ̀ tibẹ̀ jáde"
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

Kini ijọba n sọ?
Gbogbo akitiyan BBC Yoruba lati kan si arabinrin Kẹmi Adeọṣun lati wi ti ẹnu rẹ lo jasi pabo nitori pe ipe si ori number ibanisọrọ rẹ gbogbo ti akọrọyin BBC ṣe ni o dun ṣugbọn ti ẹnikẹni ko gbe.
Bakanaa ni ileeṣẹ aarẹ pẹlu ko tii sọ ohunkohun lori ọrọ naa.
nigba ti BBC pe olubadamọran pataki fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adesina, o ni oun yoo sọrọ lori rẹ bi o ba ya.

Kini ẹgbẹ alatako n sọ?
Nibayii, ẹgbẹ oṣelu PDP pẹlu ti da si ọrọ naa ti wọn si ti n ke si aarẹ Buhari pe ko rọ Adeọṣun loye; ko si ṣe iwadi rẹ pẹlu ijiya to tọ bi aje iwa ibajẹ naa ba ṣi mọọ lori.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi sita, o ni asiko to fun aarẹ lati jẹwọ smọluwabi ti o n pe ara rẹ nipa fifaaye gba iwadi ti ko lọwọ ijọba ninu lori ẹsun iwa ibajẹ laarin awọn ọmọ igbimọ rẹ.
" A rọ aarẹ Buhari lati maṣe daabo bo Adesṣun gẹgẹ bii iṣe rẹ nigbakugba ti awsn eeyan to sun mọọ tabi jẹ oṣiṣẹ rẹ ba ti ko sinu ọgbun ẹsun iwa kotọ"

Oríṣun àwòrán, @HMKemiAdeosun
Ẹgbẹ oṣelu PDP ni ọọyẹ to la lori ọrọ yii ti fihan pe ootọ n bẹ ninu awọn ọrọ ti ẹgbẹ oṣelu naa ti sọ ṣaaju pe, ibuba awọn agbalọwọ meri ati ọlọṣa to fi mọ awọn ti iṣẹ ọwọ wọn ko mọ ni iṣejọba aarẹ Buhari.
Bi a ko ba ni gbagbe, laipẹ yii pẹlu ni ileẹjọ giga kan nilu Oṣogbo gbe idajọ kalẹ pe lati faaye gba ile aṣofin apapọ pe ko bẹrẹ igbesẹ irọloye fun aarẹ lori awọn ẹsun kan ninu eyi ti a ti ri ẹsun to nii ṣe pẹlu iwe ẹri pẹlu.
Ìhà wo ní àwọn ọmọ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà kọ si ọ̀rọ̀ yìí
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Naàìjíríà ló ti ń nàka àlébù sí ilé iṣẹ́ ààrẹ pé kò wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdá lóri ọ̀rọ̀ Kẹ́mi Adeosun
Eyi ni ohun ti Femi Fani Kayode àti àwọn ọmọ Nàìjíríà míìràn sọ lori ọ̀rọ̀ náà
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

End of X post, 4

Oríṣun àwòrán, ogundamisi/twitter
Àwọn míràn tilẹ̀ ń nàka àlébù sí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ asòfin pe wọn mọ àṣírí ọ̀rọ̀ náà lásìkò ti wọn ń ṣe ìfọ̀rọwanilẹ́nu wo fún Kemi Adeosun, sùgbọ́n wọn bo ọ̀rọ̀ náà mọ abẹ́ aṣọ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5

End of X post, 6