Theresa May: A dúpé lọ́wọ́ Minisita fún isẹ́ tó se lásìkò rẹ̀

Boris Johnson

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, Ìròyìn sọ pé ìkọ̀wéfipọ̀sílẹ̀ Boris Johnson tó jẹ́ Minisita fórọ̀ ilẹ̀ òkèèrè, ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nííse pẹ̀lú 'Brexit'.

Minisita fọrọ ilẹ okeere ni Ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson ti kọ iwe fi ipo rẹ silẹ.

Iroyin so pe ikọwe fi ipo silẹ Boris Johnson to jẹ Minisita fọrọ Ilẹ Okeere ni Ilẹ Gẹẹsi niise pẹlu igbaradi orilẹede Britain lati kuro ninu Ajọ Isọkan Ilẹ Europe ( European Union) , eleyi ti wọn n pe ni 'Brexit'.

Boris Johnson ni ẹnikeji ti ipo rẹ gaju lẹyin olootu ijọba Ilẹ Gẹẹsi naa, Theresa May.

Ninu atẹjade kan, Ile-isẹ Olotu Ijọba IlẹGẹẹsi (No 10 ) , dupẹ lọwọ Arakunrin Johnson fun isẹ ribiribi to se nigba to wa ni ipo, atiwipe wọn ko ni pẹ kede ẹni ti yoo gba ipo rẹ.

Iroyin fikun wipe ikọwefiposilẹ rẹ waye nigba to ku ọgbọn isẹju ti olotu naa yoo se ipade pẹlu awọn asofin ni Ile Igbimo Asofin Orilẹede naa nipa afihan ero rẹ tuntun lori ati kuro ninu Ajo Isọkan Europe ( European Union) naa.