Àjọ NLC Naijiria : MTN kọ̀ jẹ́ kí òsìsẹ́ wọn darapọ̀ mọ́ àjọ òsìsẹ́

Àkọlé fídíò, Àjọ NLC Naijiria : MTN kọ̀ jẹ́ kí òsìsẹ́ wọn darapọ̀ mọ́ àjọ òsìsẹ́

Ajọ osisẹ lorilẹede Naijiria, NLC ti pasẹ fun awn akẹgbe rẹ lati se ifẹhọnu han niwaju ile isẹ ẹrọ ibaraẹnisọr, MTN kaakiri orilẹede Naijiria.

Ajọ NLC fi ẹsun kan MTN wi pe ileesẹ naa kọ lati fun awọn osisẹ won laaye lati darapọ mọ ajọ osisẹ lorilẹede Naijiria lati le ja fun ẹtọ wọn.

Àjọ NLC Naijiria
Àkọlé àwòrán, Àjọ òsìsẹ́ lórílẹ̀èdè Nàíjírìà pè fún ìfẹ̀họ́nú hàn nítorí iléesẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ MTN kò fún àwọn òsìsẹ́ wọn láàyè láti darapọ̀ mọ́ Àjọ òsìsẹ́.

Amọ, MTN nigba to n fesi si ifẹhọnu han ni oju opo ikansiraẹni, Twitter wọn bu ẹnu atẹ lu ifẹhọnu han naa.

Ile isẹ ibaraẹnisọrọ naa fikun wipe awọn to se ifẹhọnu han naa ba ọpọlọpọ nkan jẹ, ti awọn osisẹ wọn naa si farapa.