Àtúndì ìbò Kwara: Raheem Ọlawuyi ní èsì ìbò náà jẹ́ àseyọrí ire tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, Olawuyi Facebook
Raheem Ọlawuyi, to jawe olubori ninu atundi ibo si Ile Asojusofin lẹkun idibo Ekiti/Irepodun/Isin/Oke-Ero ni ipinlẹ Kwar, ti kede pe awọn eeyan ipinlẹ Kwara ti se oriire nitori bi wọn se dibo yan oun.
Ọlawuyi sọ eyi lasiko to n fesi si abajade idibo ti Ajọ INEC ti kede rẹ gẹgẹbi ẹni to jawe olubori ninu atundi ibo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ni, bi oun se moke ninu atundi ibo naa jẹ aseyori to n bọ lọpọ fawọn eeyan ipinlẹ naa.
PDP: APC fi bàálù dẹ́rùbà wa láti dìpò, tó sì fi ọlọ́pàá gbé ọ̀pọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ wa
Ẹgbẹ oselu PDP ti ni, oun ko gba esi idibo ti Ajọ Eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC gbe jade, lẹyin ti wọn kede Raheem Olawuyi ti ẹgbẹ oselu APC, gẹgẹbi ẹni to jawe olubori ninu atundi ibo si ile asojusofin lẹkun idibo Ekiti/Irepodun/Isin/Oke-Ero ni ipinlẹ Kwara.
Alaga ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Kwara, Kola Shittu, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni, ẹgbẹ PDP ti setan lati kọ esi idibo naa, amọ awọn si n duro ki INEC fi akọọlẹ akojọpọ esi ibo naa ransẹ si awọn.

Shittu ni, gbogbo ohun ti ko yẹ ko sẹlẹ lo waye lasiko idibo naa, ati wi pe, awọn ọlọpaa fi panpẹ ọba mu awọn ẹgbẹ oselu PDP ki idibo to bẹrẹ rara, tawọn ọlọpaa si n sa wọn kaakiri.
"Ko si ọmọ ẹgbẹ APC kankan ti ọlọpa gbe lasiko ibo naa, amọ se ni wọn n dunkoko mọ awọn asaaaju ẹgbẹ PDP lasaiko atundi ibo naa."
Shittu ni nigba ti ilẹ ọjọ Aiku yoo ba fi su, ẹgbẹ oselu PDP yoo kede erongba rẹ fun araye gbọ nipa esi ibo naa.

O tun fẹsun kan ẹgbẹ oselu APC wi pe, wọn lo ọkọ baalu lati fi dẹruba awọn eniyan lasiko ti wọn n dibo, eleyii ti wọn ni pe, ko fun wọn laaye lati dibo pẹlu irọrun.
Amọ, igbiyanju lati kan si ẹgbẹ oselu APC lati fesi si ẹsun naa jasi pabo.
INEC: Raheem Olawuyi ti APC mókè nínú àtúndì ìbò
Ajọ Eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti kede Raheem Olawuyi ti ẹgbẹ oselu APC, gẹgẹbi ẹni to jawe olubori ninu atundi ibo si ipo asojusofin lẹkun idibo Ekiti/Irepodun/Isin/Oke-Ero ni ipinlẹ Kwara.
Asoju Ajọ INEC ninu eto idibo ni ipinlẹ Kwara, Ọjọgbọn Abimbola Adesoji, lasiko to n kede esi ibo naa ni, Olawuyi jawe olubori pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna mọkanlelelogun ati ojilerugbadinmẹrin(21,236), nigba ti oludije fun ẹgbẹ oselu PDP ni ibo ẹgbẹrun lọna mejidinlogun ati marundinlọgọrun(18,095).
Ẹgbẹ Oselu Labour Party ni ibo aadọjọ( 150), ti ẹgbe oselu Peoples Party of Nigeria (PPN) ni ibo mẹrindinlọgọrin(76) ti UPN si ni ibo mejilelogoji(42).
Ọjọgbọn Adesoji ni, ninu gbogbo ibo ẹgbẹrun lọna ogoji ati ojilelẹẹdẹgbẹrun o din mẹwa (40, 930) ti wọn di, ẹgbẹrun lọna mọkandinlogoji ati ẹgbẹta din ẹyọ kan (39,599) lo jẹ ibo to yanju ninu rẹ, nigbati ibo ojilelẹẹdegbeje o din mẹsan (1,331) si jẹ asadanu.
Àtúndì ìbò Kwara: Ọmọ ẹgbẹ́ wa kò fowó ra ìbò - APC

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti fidi rẹ mulẹ pe ibo kika ti bẹrẹ lawọn agọ idibo gbogbo to wa ni ẹkun idibo Irẹpọdun, Isin Ekiti àti Oke Ẹrọ, nibi ti atundi ti n waye lọjọ Satide.
Aago meji ọsan ni eto idibo naa pari, ti ohun gbogbo si lọ leto-leto bi o tilẹ jẹpe iroyin kan ti a ko lee fidi rẹ mulẹ sọ pe, awọn janduku oloselu kan si ja apoti idibo gba lawọn agọ idibo kan lẹkun idibo ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Wayi o, ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Kwara ti kede pe, ko si ootọ kankan ninu iroyin kan to gbode wi pe, ọmọ ẹgbẹ awọn kan n ṣe fakinfa pẹlu awọn ọ̀dọ́ nílùú Ekan meje ní ìjọba ìbílẹ̀ Oke-Ero, lasiko ti idibo atundi n waye nibẹ lọjọ Satide.
Charles Folayan, to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ APC lo salaye ọrọ yi fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwọ kan.
Folayan ni, lootọ ni wi pe Abdulfatah Yahaya Seriki Gambari, lo wa ninu awọran naa ṣugbọn wọn ko ya aworan naa ni ibudo idibo to wa ni ilu Ẹkan meje.

Oríṣun àwòrán, Kwara APC Information Center
''Ni Ẹkan ni mo ti dibo mi, mi o si gburo nkankan nibẹ. Aworan igba ti Abdulfatah Yahaya Seriki Gambari, n ṣe ipolongo gẹgẹ bi oludije fun ipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ APC, ni awọn ọbayejẹ eeyan fi sita''
O ni ọtọ ni aṣọ ti Abdulfatah Yahaya Seriki Gambari w,ọ ko si wa lati ṣe madaru kankan nibi idibo toni.
Ẹwẹ, ẹka to n risi ọrọ Iroyin nipa ẹgbẹ APC loju opo Facebook wọn ti fi ikede sita wi pe, ko si ootọ ninu iroyin kan to ni pe awọn ọdọ koju oro si Yahaya Seriki.

Oríṣun àwòrán, Kwara APC Information Center
'Dìbò ko sebẹ̀' tún gbòde ní àtúndì ìbò Kwara
Saaju ni iroyin ti gbode lori ẹrọ ayelujara wi pe awọn ọ̀dọ́ nílùú Ekan meje ní ìjọba ìbílẹ̀ Oke-Ero, tí kọjú ìjà sí ọkan nínú àwọn oludije tẹlẹ tó feròngba han láti díje dupò gómìnà ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara, Abdulfatah Yahaya Seriki Gambari, tí ìjọba ìbílẹ ìlà-oòrùn Ilorin.
Wọn fẹ̀sùn kàn pé o ń fí owó ra ìbò àwọn ará ìlú.
Nigba to n fidi isẹlẹ yii mulẹ, Oludamọran agba feto iroyin si gomina ipinlẹ Kwara, Muideen Akorede ni, se ni awọn ọ̀dọ̀ náà ń pariwo Gambari pé kó fi ìlú àwọn sílẹ̀ nítori kò sí ìdí tó fi yẹ kó wà nínú ìlú náà.

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmaad
Akorede sọ siwaju pe, awọn ọdọ naa ni Gambari pẹ̀lú àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó lé ní ogun, tó fí mọ àgba ẹgbẹ́ òṣèlú APC kan, Cook Gani Olododo, ní wọn ri níbi ti wọn ti ń fún àwọn ènìyàn lówó, kí wọn báa lè dìbò fún ẹgbẹ́ wọn.
Wọn fi kún ọ̀rọ wọn pé, ilé olùdíje ẹgbẹ PDP ninu atundi ibo naa, onímọ-ẹrọ Dare Bankole, ni Seriki Gambari ko awọn tẹlẹmuyẹ lọ lati mu si ahamọ̀, sùgbọn àwọn ọmọ ìlú kò gbà kí èyí wáyé.
Janduku ji apoti ibo gbe ni Kwara
Bí àtúndì ìbò ṣé ń lọ lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Kwara, ìròyìn tó ń dé sí etí ìgbọ́ BBC Yorùbá ní, àwọn jandùkú ti jí àpótí ìdìbò gbé ní ibùdó ìdìbò Olupodo ní wọ́ọ̀dù 1 Omù-Aran àti Federal Girls College Omu-Aran Woodu 2, sùgbọn àwọn ọlọ́ọpàá ti ríi gbà padà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à kò lè fì ìdí rẹ̀ múlẹ̀ irúfẹ́ ẹgbẹ òṣèlú tí àwọn janduku náà ń ṣiṣẹ́ fún, sibẹ ẹgbẹ́ òsèlú PDP àti APC ń nàka àlébù si ara wọn lori isẹlẹ naa.
Bakan náà ní ìròyín tún tẹ̀wá lọ́wọ́ pé, ẹ̀rọ̀ tó máà yẹ orúkọ àwọn olùdibò wo ti daṣẹ́ sílẹ̀ láwọn ibìkan, tàwọn ọmọ ẹgbẹ òṣèlú PDP si ní INEC mọ̀ọ́mọ̀ ṣe èyí ni nítòrí ibi tí ẹgbẹ àwọn ti láanfàní láti jáwé olúbori ni.
Isẹlẹ ‘dìbò kòo sebẹ̀’ náà kò gbẹ́yìn níbi ìdìbò tòní lágbègbè ile Bale nílù Òró sùgbọn ọkàn nínú èèkan ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó bá BBC sọ̀rọ̀, Lattef Oloyin sàlàyé pé ọwọ́ àwọn agbofínro ti tẹ ènìyàn márùn báyìí lori isẹlẹ naa.
Àtúndì Ìbò Kwara: APC àti PDP ń sọ òkò ọ̀rọ̀ síra wọn

Oríṣun àwòrán, @SKSolaKuti
Iran yoo dun wo ni ipinlẹ́ Kwara loni ọjọ Abamẹta nigba ti ẹgbẹ oselu PDP ati APC yoo maa ti ẹsẹ bọ sokoto kan naa lati yan asoju-sofin tuntun ti yoo maa soju ẹkun idibo Irẹpọdun, Isin Ekiti ati Oke ẹrọ.
Bẹẹ ba gbagbe, asoju-sofin to n soju ẹkun idibo naa tẹlẹ, Funkẹ Adedoyin lo dagbere faye lọjọ kejidinlọgbọn osu kẹsan ọdun 2018, lasiko aisan kan to mu, eyi to mu ki aga ẹkun idibo naa sofo nile asofin apapọ ilẹ wa.
Ọpọ eeyan si lo n fi oju wo eto atundi ibo naa gẹgẹ bii ija agba meji laarin aarẹ ile asofin agba ilẹ wa, Bukọla Saraki, tii se ọmọ bibi ipinlẹ Kwara ati aarẹ orilẹ́-ede yii, Mohammadu Buhari.

Oríṣun àwòrán, Greatkay
Niba yii na, awọn ẹgbẹ oselu meji to gbaju gbja julọ nipinlẹ Kwara, eyiun ẹgbẹ oselu PDP ati APC ti n sọ oko ọrọ si ara wọn nibayi ti eto atundi ibo naa wọle de.
Ẹgbẹ oselu APC, ninu igbe to fi bọnu faraye ni ẹgbẹ oselu PDP to n se ijọba lọwọ ni ipinlẹ Kwara ti fọn awọn janduku soke lati maa dunkoko mọ awọn alatako rẹ ninu atundi ibo ọhun.

Oludije fẹgbẹ oselu APC ninu atundi ibo naa, Raheem Ọlawuyi ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ rẹ fisita fawọn akọroyin nilu Omu Aran ni PDP da awọn janduku sita lati maa dun mahuru mahuru mọ awọn oludibo keto idibo naa to waye ni.
Sugbọn gomina ipinlẹ Kwara, AbdulFatai Ahmed, ti wa fesi pada pe ọ̀rọ naa ko ri bẹẹ rara nitori aabo to peye si n bẹ fun awọn oludibo.

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmaad
Atẹjade kan ti Oludamọran agba rẹ feto iroyin, Muyideen AKorede fisita ni, ijọba ti ko awọn agbofinro sita lati fi ẹsẹ eto aabo mulẹ dain-dain, eyi ti yoo fun awọn oludibo lanfaani lati wa se ojuse wọn.
Gomina Ahmed wa rọ awọn olugbe ẹkun idibo naa lati tu jade sita wa kopa ninu atundi ibo ọhun, ki wọn si fi ibo wọn yan oludije ti ọkan wọn n fẹ.
APC ati PDP n gbena woju ara wọn ninu atundi ibo Kwara
Bi awọn ẹgbẹ oṣelu ṣe n gbaradi fun atundi ibo sile aṣoju-ṣofin lẹkun ijọba ibilẹ Ekiti, Oke Ero, Isin ati Irẹpọdun ni ipinlẹ Kwara, eleyi ti yoo waye ni ọjọ abamẹta, awọn agbebọn kan lo ṣaa dede kọlu awọn ọkọ ti o ko oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC, Tunji Ajulo Opin ati ikọ ipolongo rẹ pẹlu ibọn.
Iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣalaye pe nnkan bii aago kan oru ni ikọlu naa waye ni agbegbe ijọba ibilẹ Oke Ero nipinlẹ Kwara.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Iroyin naa tun ṣalaye pe ibi ipolongo idibo kan ni Tunji Ajulo Opin ati ikọ rẹ ti n bọ ki awọn agbebọn naa to kọlu wọn.
BBC News Yoruba fi idi rẹ mulẹ pe oludije fun ipo gomina ipinlẹ Kwara labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC, Abdulrazaq Abdulrahman ko si ninu eyikeyi ninu awọn ọkọ ti wọn kọlu lasiko naa gẹgẹ bii awọn iroyin kan ti n gbe e kiri.
Ninu ọrọ ti ọkan ninu awọn amugbalẹgbẹ oludije ẹgbẹ oṣelu APC naa ba BBC news Yoruba sọ, "ko si Alhaji Abdulraham pẹlu ikọ ipolongo naa lasiko ti ikọlu naa waye; ṣugbọn a lee sọ wi pe, Tunji Ajulo Opin to jẹ oludije fun aga ile aṣoju-ṣofin lẹkun Ekiti, Oke Ẹro, Isin ati Irẹpọdun ni ipinlẹ Kwara lẹgbẹ oṣelu APC ni wọn n lepa.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n ṣe akojọpọ iroyin ti ati iwadi lori iṣẹlẹ naa.
Kwara bye election:Tá ní yóò borí ìbò láàrin APC àti PDP?

Gbangba fẹ dẹkun ti kedere yoo si bẹwo nipinlẹ Kwara pẹlu ibo atundi ti yoo waye nibẹ lọjọ abamẹta.
Ibo naa ti yoo waye ni awọn ijọba ibilẹ kan ni guusu ipinlẹ naa jẹ eleyi ti wọn yoo fi yan asoju tuntun fun ẹkun idibo Irepodun/Oke-Ero/Isin/Ekiti .
Asofin to n soju agbegbe naa tẹlẹ Funke Adedoyin papoda laipẹ, eleyii to mu ki INEC seto idibo miiran.
Lootọ ni pe idibo ko ni waye ni gbogbo ipinlẹ naa sugbọn awọn amoye ni esi rẹ yoo sẹ atọna ibi ti ọpa ẹbiti idibo 2019 yoo re si.
Ki lo de ti ibo yi ṣe ṣe pataki
Idibo yi le jẹ laarin awọn oludibo ẹgbẹ APC ati PDP ṣugbọn ọrọ naa tan de ori Aarẹ ile asofin agba Bukola Saraki ati Aarẹ orileede Naijiria iyẹn Muhammadu Buhari.
Idi ni wi pe idibo yii tunbọ fagbara fun fa kin faa laarin wọn lori ẹni ti o lagbara ju lori oselu Kwara.
Saaju asiko yii, ẹgbẹ oselu APC lo n dari akoso ipinlẹ naa ti gbogbo awọn asoju to fi mọ awọn to di ipo mu wa lati inu ẹgbẹ APC.
Sugbọn bi Aarẹ ile asofin Bukola Saraki ti se kede wi pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ apc lọ si PDP, nise ni gbogbo awọn asoju to fi mọ Funke Adedoyin to salaisi naa sun tele.
Ti PDP ba mu oke ninu idibo yii, a jẹ wi pe gbogbo awọn asofin Kwara yoo jẹ ti wọn ni sugbọn tio APC ba fi le ri aaye rẹ gba,ohun iwuri ni yoo jẹ fun wọn.
Ifidirẹmi fun eyikeyi ẹgbẹ le se akoba fun wọn ninu idibo gbogbogbo to n ba lọdun 2019.
Awọn wo lon du ipo rẹ
Labẹ asia ẹgbẹ APC ni Funke Adedoyin to di ipo naa mu tẹlẹ wa ki o to lọ si ẹgbẹ PDP.
Ọgbẹni Raheem Olawuyi ni awọn ọmọ ẹgbẹ gbimọpọ yan gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ oselu APC.

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/Saheed Alatise/Raheem Olawuyi
A gbo wi pe ẹgbẹ oselu mẹwa lo fi oludije sile lati du ipo naa ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ iṣẹgun nise ni iroyin gbode wi pe awọn ẹgbẹ oṣelu meje ti pa imọran pọ lati yan Raheem Olawuyi gẹgẹ bi oludije wọn.
Bi ọrọ yi ba ri bẹ, ajẹ wi pe ẹgbẹ meje to fi mọ APC ni PDP yoo ma ba wọ iya ija lọjọ idibo.
Ọgbẹni Saheed Alatishe ni oludije ẹgbẹ PDP.
Ajumọyan ni awọn ọmọ ẹgbẹ PDP fi yan ohun naa si ipo gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ.

















