Food Poison - Májèlé inú Àmàlà ṣekúpa ènìyàn mẹ́rin ní Ilorin

Oríṣun àwòrán, @Bamshaq_Potato
Énìyàn mẹ́rin nínú ìdílé kan ní ìlú Ilorin ti gbkmìí mì lkyìn tí wọ́n jẹ àmàlà tí wọ́n fura sí pé ó ní májèlè nínú.
A gbọ́ pé àwọn mẹ́rin mìí tó jẹ nínú àmàlà náà ti wà nílé ìwòsàn ti ìjọba tó wà ní ìlú Ilorin.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní agbègbè Magaji - Ogo lẹ́yìn ilé ìwé Kwara State Collefe of Arabic and Islamic Legal Studies nílùí Ilorin.
Ìròyìn sọ pé alẹ́ ọjọ́ àìkú ni wọ́n jẹ àmàlà, nígbà tó ma fi di òwúrọ̀ ọjọ kejì, wọ́n ti rékọjá sí ọ̀run alákeji.
Lọ́jọ́rú sì ni a gbọ́ pé olórí ilé náà gbẹ́mìí mì. Àwọn tí wọ́n ní wọ́n ti gbẹ́mìí mì ni bàbá, àbúrò rẹ̀ àti ọmọ méjì nígbà tí ìyá àti ọmọ mẹ́tàá ń gbìyànjú láti yè é nílé ìwòsàn.
Wọ́n ti sin òkú àwọn tó ti bá ìṣllẹ̀ náà rìn ní ìlànà ẹ̀sìn Islam.










