World Food Day: Oúnjẹ àràmọ̀ǹdà mọ́kànlá tí wọ́n ń jẹ lágbààyé rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ounjẹ jijẹ jẹ ọrẹ ara, amọ jijẹ idin ninu burẹdi jẹ ohun to so si ni lẹnu, to si bu iyọ si.
Bayii ni ọrọ ri fun awọn to n gbe agbeegbe Sardinia ni orilẹede Italy, ti wọn fi idin se ounjẹ ajẹpọnnula, ti wọn yoo si dupẹ lọwọ ẹnikẹni to ba fun wọn ni burẹdi onidin jẹ.
Eyi lo mu ki wọn pinnu lati se afihan ile ounjẹ ti ko wọpọ lawujọ si awọn gbagede kan, eleyii ti yoo bẹrẹ ni Malmo, lorilẹede Sweden ni Ọjọ Kọkanlelọgbn, Osu Kẹwa, ọdun 2018.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Sise afihan ounjẹ yii yoo fi agbara fun ero awọn eniyan wi pe, ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran.
Ẹ wo oúnjẹ àràmàndà 11 tí wọ́n ń jẹ lágbààyé
Yoruba bọ wọn ni bayii lati n se ni ilẹ wa, eewọ ibomiran ni.
Eyi lo mu ki onimọ nipa ihuwasi ati ise ọmọniyan, Samuel West sọ wi pe, ounjẹ jijẹ jẹ ohun abalaye to n se afihan ihuwasi eniyan ati ibi ti eniyan ti ṣan wa.
Orilẹede Italy ma n jẹ burẹdi ati iyẹfun ti wọn fi idin se

Oríṣun àwòrán, Anja Barte Telin
Ni orilẹede China, wọn ma n jẹ oko akọ maluu. Awọn onimọ ni ki Obinrin o jẹ funfun, nigbati Ọkunrin yoo jẹ dudu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Anja Barte Telin
Tata ni ounjẹ awọn ara Uganda. Eleyii ti wọn ti yii lata. Wọn a ma jẹ ẹ pẹlu ọti waini. Amọ eewọ ni fun awọn obinrin oloyun, ki wọn ma ba a bi ọmọ ti ọpọn ori rẹ yoo jọ ti tata.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lorilẹede Mexico, ounjẹ ati papanu ni ẹyin kokoro. Wọn ma n din, ti wọn si ma n gbadun rẹ lọpọ igba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni Vietnam, ọkan ejo Sèbé ni awọn eniyan ma fi n se ounjẹ jẹ. Wọn ni o ma n fi agbara kun agbara wọn. Wọn si le e jẹ ọkan ejo naa pẹlu ẹjẹ ejo tabi oti waini Vodka.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ara orilẹede Iran, Afghanistan ati Iraq ko fi oju abo agbo sere rara ati ọpọlọ rẹ. Gbogbo rẹ ni jijẹ fun wọn. Wọn ni kii jẹ ki eniyan wuwo lalẹ.

Oríṣun àwòrán, Mo Styles
Ni Ilẹ Gẹẹsi, ounjẹ aarọ to peleke ni ki eniyan o fi ẹjẹ ẹlẹdẹ ti wọn ti sè, kun ounjẹ to fẹ jẹ lojumọ. Ounjẹ owurọ ko i tii pe ni Ilẹ Gẹẹsi ti ko ba si ẹjẹ ẹranko ti wọn ti se nibẹ. Wọn ni o dara fun eroja asaraloore iron, zinc ati protein.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni orilẹede Peru, omi ara ọpọlọ ti wọn ti rẹ ni awọn fi n se ara rindin, ti wọn si tun n ta a fun awọn eniyan gẹgẹbi omi ẹlẹrindodo to n mu araji pepe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun to wọpọ ni orilẹede Turkey ni lati fi igba aya ati ọmu akukọ fi se ounjẹ jijẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eleyii ya ni lẹnu pupọ ju. Orilẹede China a ma a fi ekute ile se ọti waini ẹlẹrin dodo. Amọ awọn ekute yii gbọdọ jẹ eyi ti wọn sẹsẹ bi, ti ko i ti pẹ ju nilẹ. Wọn ni o ma n sisẹ fun aisan ikọfe e ati aisan ẹdọ.

Oríṣun àwòrán, Mo Styles
Ni Russia, ko buruju ti wọn ba fi omi ara ẹja lasiko ti wọn ba n lopọ fi se ọbẹ ẹja, ti wọn yoo jẹ. Moloka ni wọn n pe orukọ ounjẹ naa. Orilẹede Japan naa a ma a jẹ ounjẹ yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
























