Osun: Aregbesola ń kó'gbá sílé, Gboyega ń gbàjọba l'Ọ́ṣun

Oríṣun àwòrán, Aregbesola
Ipinlẹ Ọṣun ti n gbaradi fun ayipada iṣejọba ni ipinlẹ naa.
Ni ọjọ iṣẹgun ni Alhaji Gboyega Oyetọla yoo gba ijọba lọwọ gomina Rauf Arẹgbẹṣọla gẹgẹ bii gomina tuntun ni ipinlẹ ọhun.
Ni asiko idibo sipo gomina eyi to waye ni oṣu kẹsan ọdun 2018 ni awọn oludibo nipinlẹ Ọṣun yan gboyega Oyetọla gẹgẹ bii gomina tuntun lẹyin atundi ibo to waye laarin oun pẹlu Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kọkanla ọdun 2010 ni gomina to n fipo silẹ nipinlẹ Ọṣun, Rauf Arẹgbẹṣọla gun ori oye lẹyin idajọ ile ẹjọ kan to kede rẹ gẹgẹ bii ẹni ti ara ilu dibo yan ni tootọ lẹyin ti Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla ti wa ni ipo naa fun ọdun mẹta.

Oríṣun àwòrán, Omonijo Sunday
Gboyega Oyetọla ni olori awọn oṣiṣẹ to n ba gomina Arẹgbẹṣọla ṣiṣẹ fun ọdun mẹjọ ti o fi wa nipo ki wọn to dibo yan an gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa.
Ọkan o jọkan awọn alejo ni wọn ti wọ ilu Oṣogbo ni igbaradi fun ayẹyẹ ijẹjẹ fun ipo gomina ti wọn yoo ṣe fun gomina tuntun Gboyega Oyetsla ni ọjọ iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2018.
Aregbesola ní iṣẹ́ ọ̀fẹ́ ni òun ṣé lọ́dún mẹ́jọ tí ó fi jẹ gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Oríṣun àwòrán, Rauf Aregbesola, Facebook
Gomina ipinlẹ Ọṣun to n palẹmọ lati kuro lori oye, Rauf Aregbesola,ti ju ọrọ gbankọgbi kan kalẹ pẹlu bi o ti ṣe ni oun ko gba owo osu lọdun mẹjọ to fi jẹ gomina.
Lori eto kan nibi ti o tin ba ara ilu sọrọ lo ti lede ọrọ yi to si ni ọun ko nilo owo nitori ijọba lo n bọ́ ohun, to n san owo ọkọ ti wọn si tun fun oun ni ile igbe.
O ni ''pẹlu gbogbo nnkan wọn yi, mi o nilo owo''
Ṣugbọn ọrọ yi ti mu iriwisi orisirisi wa ti awọn kan sin yinmu si pẹlu oun to sọ.
Lẹnu ọjọ mẹta yi ọrọ nipa owo oṣu ti awọn ti wọn dibo yan si ijọba n gba ti n kọ ọpọ lominu paapa julọ pẹlu bi ara ilu ti ṣe mọ wi pe awọn sẹnẹto n gba owo ajẹmọnu to ju owo osu wọn lọ nilọpo mẹtala.
Koda gomina kan tẹlẹ ri sọ wi pe ti awọn ara ilu ba mọ iye ti awọn gomina n gba , niṣe wọn yoo yari patapata.
Eeyan kan lori ẹrọ ayelujara woye pe ṣe ọmọde ni ogbẹni Aregbesola ro wi pe oun n ba sọrọ ni ti ẹlomiran si bere wi pe 'bawo ni ai gba owo osu Aregbesola ti ṣe mu adinku ba inira to n ba ara ilu?'
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Losu to n bọ ni ọgbẹni Aregbesola yoo fi ipo silẹ gẹgẹ bii gomina.
Gboyega Oyetola ni yoo gba ipo lọwọ rẹ lẹyin to jawe olu bori ninu ibo to waye losu kẹsan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:















