Rice Subsidy: Ìjọba àpapọ̀ gbé ₦60bn kalẹ̀ bíi owó ìrànwọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mínísítà feto ọ̀gbìn, Audu Ogbeh ní ìjọba àpapọ̀ tí buwọ́lu ọgọ́ta bílíọ̀nù náírà gẹ́gẹ́ bíi owó iranwọ fún ìpèsè ìrẹsì ní orílẹ́-èdè Nàìjíríà.
Ó sọ èyí di mímọ̀ lẹ̀yìn ìpàdé pẹ̀lú àjọ tó ń mójú tó ààbò oúnjẹ tó wáyé ní ilé ìjọba nílù Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Nínú ìpádé ọ̀hún, eyi ti ààrẹ Muhammadu Buhari darí, ní mínísítà ti sàlàyé pé owó ìrànwọ ọhún ni láti mú àdínkù bá owó ìrẹ̀sì tó gbówó lórí gọbọi.
Ó ní ọ̀nà ọ̀tọ̀ ní àwọn yóò gbé owó ìrànwa eléyìí gba lójuna àti mase kó sínú wàhálà tí wọn kojú, lásìkò owó ìrànwọ́ epo bẹtiro, nítori náà ìgbìmọ tẹ̀ẹ́kótó yóò dìdé, tí mínísítà fún ìsúna yóò wà nínú rẹ̀ pẹ̀lú, láti sètò tó bá yẹ.

Oríṣun àwòrán, @Auduofficial
Ogbeh fí kún-un pé, ó sàn láti yá àwọn àgbẹ́ ìrẹ̀sì, àwọn tó n bó ìrẹ̀sì àtí àwọn alágbàtà lówó pẹ̀lú èlé tí kò guni lápá.









