Àwọn aṣofin Nàìjíríà fẹ̀sùn kan Ọṣinbajo lórí ọ̀rọ̀ NEMA

Oríṣun àwòrán, @profosinbajo
NEMA sọ pe ọwọ wọn mọ, bi awọn aṣoju-ṣofin ṣe fẹsun kan Yẹmi Ọṣinbajo lori jibiti biliọnu mẹfa din diẹ.
Àjọ tó n rí sí ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì lorilẹ-ede Naijiria, NEMA ti sọ pe ọwọ wọn mọ lẹyin igba ti ile igbimọ-aṣofin kekere naa sọ pe ọga agba ajọ ọhun lọwọ ninu jibiti ti o to biliọnu mẹtalelọgbọn naira.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita ni NEMA ti ṣalaye ohun ti igbimọ naa gbe jade pé wọn kò ni nkan ṣe pẹlu awọn iwe aṣẹ ati aridaju ti awọn fi silẹ.
Ni ọjọbọ, igbimọ naa tun sọ pe igbakeji aare Naijiriya Yẹmi Ọṣinbajo naa fi ọwọ si milionu naira mẹfa-din (N5.8bn) ti ariwa owo-ifilọlẹ idasi, ti ile-igbinmọ sọ pe olodi s'ofin.
Ile-Igbinmọ naa sọ pe Yẹmi Ọṣinbajo ṣiṣe gẹgẹ bi aare nigba naa ni o fi tẹ ontẹ ki wọn na ọwọ naa in oṣu kẹfa, ọdun 2017.
Wọn ni o na ninu owo-ifilọlẹ apapọ nigba ti ko ri aṣe gba ni ile-igbinmo aṣofin lasiko naa.
Laolu Akande ti o je agbẹnusọ fun Ọṣinbajo jeri rẹ fun BBC pe awọn mọ si ẹsun naa ati pe awọn yoo fesi si iroyin naa láipẹ̀.
NEMA ṣalaye pẹlu apẹẹrẹ bi owo ti o le ni bilonu meji naira (N2.25 Billion) ni iye owo irẹsi ti ijọba China fi ranṣẹ si ilẹ Niajiria fun awọn aṣatipo ni ariwa, wọn si sọọ di mimọ pe bii milionu aadọtalenirinwo naira ni wọn na lati gbaa ati lati tọju awọn irẹsi naa, kii ṣe ẹgbẹrin milionu naira bi igbimọ naa ṣe sọ.
Ile-igbinmọ aṣoju naa ti gba Aare Muhammadu Buhari nimọran pé ki o da ọga NEMA, Maihaja duro lẹnu iṣẹ, pé ki o fun awọn agbofinro to n gbogun ti iwa ibajẹ n'ilu laṣẹ lati foju wọn ba ilé ẹjọ bi o ti yẹ.














