Buhari ba osinbajo sayẹyẹ igbeyawo ọmọ rẹ.

Aarẹ Buhari ba Damilọla Osinbajo ati ọkọ rẹ sajọyọ

Oríṣun àwòrán, Twitter.com

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Buhari ba Damilọla Osinbajo ati ọkọ rẹ sajọyọ

Aarẹ orilẹede yii Muhammadu Buhari ni o ti ba igbakeji rẹ Yẹmi Osinbajo sayẹyẹ igbeyawo ọmọ rẹ.

Igbeyawo ọun, laarin Oluseun Bakare ati Damilọla Osinbajo lo waye nile ijọba nilu Abuja.

Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter.com

Àkọlé àwòrán, Buhari ba ọkọ ati iyawo sajọyọ

Yatọ si aarẹ Buhari ti iyawo rẹ naa ba kọwọ rin, nibi igbeyawo ọun ni a tun ti ri awọn jankanjankan bii Gomina Amosun ti ipinlẹ Ogun, Gomina Ajimọbi ti ipinlẹ Ọyọ, Gomina Rochas Okorocha ati bẹẹbẹẹ lọ.

Aarẹ Buhari ba Damilọla Osinbajo ati ọkọ rẹ sajọyọ

Oríṣun àwòrán, Twitter.com

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Buhari ba Damilọla Osinbajo ati ọkọ rẹ sajọyọ

Kii se ayẹyẹ igbeyawo yii nikan ni aarẹ Buhari yoo ti farahan, a ti ri aarẹ nibi awọn igbeyawo miiran laipẹ yii, bii igbeyawo laarin ọmọ Gomina Gunduje ati ọmọ Gomina Ajimọbi.