Minimum Wage: Apá àwọn gómìnà ò ká ọgbọ̀n ẹgbẹ̀rún Naira owó oṣù-Yari

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmad
Aarẹ Buhari sọ fun wa pe eto ọrọ aje orilẹede Naijiria ko dara lasiko yii.
Eyi ni ọrọ ti iroyin sọ pe alaga ẹgbẹ awọn gomina, to tun jẹ gomina ipinlẹ Zamfara, Abdulaziz Yari, sọ fun awọn oniroyin lẹyin ipade ti awọn gomina mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria ṣe pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari l'ọjọ Ẹti.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, 'Aarẹ Buhari fi to wa l'eti wi pe ipo ti ọrọ aje Naijiria wa bayii ko dara. Nitorina, a gbọdọ pejọ, ki a ronu, ki a si sẹ atungbeyẹwo ọna abayọ.''
Ipade naa waye lati jiroro lori aigbọra ẹni ye to n waye laarin awọn gomina ati ẹgbẹ osisẹ lori ọgbọn ẹgbẹrun gẹgẹ bi owow oṣiṣẹ to kere ju.
Aarẹ Buhari ti ṣe iru ipade bẹ ẹ ri pẹlu awọn gomina l'ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, lẹyin ti igbimọ ẹlẹni mẹta gbe aabọ iwadi rẹ kalẹ fun Aarẹ Buhari. Ninu aabọ iwadi naa ni wọn ti gbero pe ki owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju jẹ ọgbọn ẹgbẹrun Naira.
Ṣugbọn, awọn gomina sọ pe ẹgbẹrun mejilelogun Naira ni awọn le san, nitori agbara awọn ko gbe ọgbọn ẹgbẹrun Naira.









