A ti gba onírúurú ìgbẹ́ tí a rí lọ́wọ́ Emmanuel Egbu lọ fún àyẹ̀wò -Ọlọ́pàá Oyo

Oríṣun àwòrán, Police
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ni ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ ni pẹ̀rẹ̀wu lóri ọkunrin kan ti orukọ́ rẹ̀ ń jẹ́ Emmanuel Egbu ti wọ́n ni o n fi igbẹ jẹ búrẹdi ni ori akintan nilùú Ibadan.
Wọ́n ní awọn kan ni àdúgbò Sango lo ké gbàjare ti wọ́n si fi ọ̀rọ̀ náà tó ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá àgbègbè náà léti ki àwọn ará àdúgbò tó ṣe ìdájọ́ fún un láti ọwọ́ ara wọ́n.
Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ Oyo, Olugbenga Fadeyi ṣàlàye fún BBC News Yoruba pé, ni kété ti wọ́n mú ọkùnrin náà ni wọ́n ti gba ọ̀rọ̀ sílẹ̀ lẹ́nu rẹ̀ ti wọ́n sì gba oníruuru ìgbẹ́ ti wọ́n ri lọ́wọ́ rẹ̀ láti gbe lọ fun àyẹwò.
- Ọmọ márùn-ún sọnù ní Otto l‘Eko, àwọn ìyá wọn kò jẹ́ èèyàn mọ́ lẹ́yìn ọdún kan
- 'Ẹ̀pa ò bóró mọ́! Òkú ọmọ ọdún mẹ́ta tó kó sí kàǹga ní Ipaja ni wọ́n yọ'
- Ilé ẹrù míì tó jábọ́ l‘Eko tún mú ẹ̀mí obìnrin méjì lọ
- Ọkọ̀ rélùwéè 16 yóò ná Eko sí Ibadan láti oṣù tó ń bọ̀ lọ - Iléeṣẹ́ Rélùwéè kéde
- Ọba Ilorin ló pàṣẹ pé kí ń padà sọ́dọ̀ ọkọ mi - Risikat olójú búlúù
Yatọ sí ìròyìn kan to sọ pé gbájúgbaja olùtaja àwọn èròjà àṣara àti irun lóge ni ọkùnrin náà to sì ni ṣọ́ọ̀bù ńlá ńlá ni àdúgbo Sango nílùú Ibadan àti pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ ra ilé ńla kan ni, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ni ọjọ́ sátide, ọjọ́ kejìlélógun ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáye, àjọ ọlọ́pàá si ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lori ọ̀rọ̀ náà ni.
Fadeyi ni òun kò le fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ afi ti ìwádìí ba pari ṣùgbọ́n ni òótọ́ ni àwọn bá ìgbẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ti àwọn si ti kó wọ́n lọ fun àwọn àyẹwò to yẹ́.
Ẹ̀wẹ̀, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ọkùnrin náà wà ni àga ọlọ́pàá agbègbè Sango.
Police Attack: Kọ́bùrù ọlọ́pàá kú, Insipektọ farapa nínú ìkọlù agbébọn n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fi fesi lori ikọlu kan to waye sawọn osisẹ ọlọpaa lagbegbe Ikolaba nilu Ibadan.
Atẹjade kan ti ileesẹ ọlọpaa naa fisita lowurọ ọjọ Satide ni awọn osisẹ awọn to wa lẹba titi nidojukọ agọ ọlọpaa Ikolaba ni awọn agbegbọn naa kọlu.
Atẹjade ọhun ni awọn agbebọn ko ya bo agọ ọlọpa rara, amọ awọn to duro soju popo ni wọn se lọsẹ, ti ẹmi ọlọpaa kan si bọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ́mọ márùn-ún sọnù ní Otto l‘Eko, àwọn ìyá wọn kò jẹ́ èèyàn mọ́ lẹ́yìn ọdún kan
- Ilé ẹrù míì tó jábọ́ l‘Eko tún mú ẹ̀mí obìnrin méjì lọ
- Àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Mali ń fò fáyọ̀ pé ológun gba ìjọba mọ́ alágbádá lọ́wọ́
- Ọkọ̀ rélùwéè 16 yóò ná Eko sí Ibadan láti oṣù tó ń bọ̀ lọ - Iléeṣẹ́ Rélùwéè kéde
- Ọba Ilorin ló pàṣẹ pé kí ń padà sọ́dọ̀ ọkọ mi - Risikat olójú búlúù
- A fí ara mọ́ ìdájọ́ ikú Sharia tó tọ́ sí Olórin Yahaya- ẹgbẹ́ Amòfin Mùsùlùmí ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kano
- Wo bí ọkùnrin ọmọ òrukàn yìí ṣe ń ran àwọn opó tí ọkọ wọn kú sójú ogun lọ́wọ́
- Deji Akure pàṣẹ kí wọ́n ti gbogbo ọjà pa fún ọjọ́ méjì, ohun tó fàá nìyí
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Saka, Sunkanmi Omobolanle àtàwọn òṣèré sinimá míràn lọ́sẹ̀ yìí
Bakan naa ni wọn sọ pe Insipẹkitọ ọlspaa kan naa fara gbọgbẹ ọta ibọn, ti wọn si ti gbe lọ sile iwosan fun itọju.
Atẹjade ọhun fikun pe aayan ti n lọ lati mu awọn afurasi ọdaran to sisẹ ibi ọhun.
Gende agbebọn yabo ileesẹ ọlọpaa nibadan, ẹmi ọlọpaa kan bọ

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn gende agbebọn kan ti ya bo agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Ikolaba nilu Ibadan nirọlẹ ọjọ Ẹti, ti wọn si mu ẹmi Kọburu ọlọpaa kan lọ.
Osisẹ ọlọpaa yii si lo wa lara awọn ọlọpaa to wa lẹnu isẹ lasiko naa tawọn agbebọn ọhun ba wọn ni alejo.
Iroyin naa ni awọn osisẹ ọlọpaa yoku to wa lẹnu isẹ lo fara gba ọgbẹ ọta ibọn lorisirisi ninu ikọlu naa, eyi to ba wọn lojiji.
Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi ni lootọ ni.
Fadeyi ni oun ko ti gbọ ẹkunrẹrẹ alaye lori bi isẹlẹ naa se waye ati awọn eeyan to huwa ibi yii.
Amọ sa, o ni iwadii si n tẹ siwaju lati mọ ohun to sokunfa isẹlẹ naa, ti BBC Yoruba yoo si mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa fun yin.














