Lagos missing children: Ọ̀kan lára ìyá àwọn ọmọ tó sọnù náà ti ń sínwín

Lagos missing children

Inu ibanujẹ ati iporuru ọkan ni awọn obi kan wa lati nnkan bi ọdun kan abọ sẹyin ni agbegbe Otto, ni ipinlẹ Eko lẹyin ti awọn gbọmọ-gbọmọ ṣadede ji ọmọ wọn gbe lọ.

Awọn obirin naa to ba BBC sọrọ sọ pe, ko din ni ọmọ wẹwẹ marun un ti wọn ti ji gbe lagbegbe ọhun.

Ọkan lara awọn obinrin naa, iya Halimat sọ fun BBC pe ojojumọ ni oun maa n sọkun ti oun si maa n gbadura ki oun le e ri ọmọ naa pada.

Iya Halimat ṣalaye pe, nnkan bi aago mẹjọ abọ alẹ ni ọmọ oun di awati lẹyin ti ileeṣẹ mọnamọna mu ina ijọba lọ lalẹ ọjọ naa lọhun, o ni oun ko tii foju gan-ni Halimat lati igba naa.

Awọn ọmọde to n sere

Bo tilẹ jẹ pẹ Musulumi ni iya Halimat, o ni ọrọ ọmọ naa ti sọ oun di ẹni to n lọ si iṣọ oru ni ṣọọṣi, ti oun si n gbaawẹ ati adura ki ọmọ le e di riri.

O ni "Wọn sọ fun mi pe mo ṣi maa ri ọmọ mi, nigba miran ti mo ba gbaawẹ ti mo si fẹ ṣinu, gari ati agbọn ni mo maa n fi ṣinu, gbogboẹ gbogboẹ ki n le ri ọmọ mi yii naa ni."

Iya Halimat ni "gbogbo igba ti mo ba ri awọn ọmọ wẹwẹ ti wọn ba n ṣere ni adugbo ni mo maa n ronu nipa ọmọ mi to sọnu, koda, mi o gbọ ohun taye n sọ mọ nitori ironu ọmọ naa."

Adugbo Otto

Obinrin miran ti ọmọ rẹ sọnu sọ fun BBC pe, ọmọ kan ṣoṣo ti oun bi ni wọn ji gbe lọ.

O ni "Ojojumọ ni mo maa n sunkun nitori akọbi ati ọmọ kan ṣoṣo ti mo bi, ti wọn ji gbe."

Ẹlomiran ti ọmọ rẹ tun di awati sọ pe, obinrin kan lara awọn ti wọn ji ọmọ rẹ ladugbo ọhun ti ya were nitori iṣẹlẹ naa.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ti fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ohun kan naa ti wọn n sọ fun gbogbo wọn ni pe, wọn ṣi maa ri awọn ọmọ wọn pada, ṣugbọn ọmọ ẹni ku san ju ọmọ ẹni nu lọ.

Àkọlé fídíò, Jude Chukwuka: Wọ́n yóò fi ojú ọlọgbọ́n wo akúrí tó bá sọ ojúlówó èdè Yorùbá

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana ni iwadii n lọ lọwọ lati mọ bi awọn ọmọ naa ṣe rin ṣugbọn yoo gba akoko diẹ.

O ni akọsilẹ ọmọ mẹrin ni ileeṣẹ ọlọpaa ni pe o sọnu, ṣugbọn iṣẹ n lọ lọwọ lati ṣawari awọn ọmọ naa, ati lati fawọn le awọn obi wọn lọwọ.