Child Safety: Òkú Seyi ọmọ ọdún mẹ́ta tó kó ni wọ́n rí

Kanga omi

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ọmọ ikoko kan ti iroyin sọ pe o ko sinu kanga ni agbegbe Ipaja niluu Eko ni ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri Eko, LASEMA ti doola.

Ninu atẹjade ti alukoro ajọ naa, Nosa Okunbor fọwọ si, o ni awọn ko si akitiyan lati yọ ọmọ ọdun mẹta ọhun ni lati nkan bii agogo mẹjọ ku iṣẹju mejidinlogun alẹ ọjọ abamẹta ni number 1 Gemini Bus Stop, Baruwa Ipaja..

Ọmọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Seyi Jebose la gbọ pe nigba to n ṣere ninu ọgba ti oun atawọn obi rẹ n gbe ni o ṣubu latorii ideri onipaanu ti wọn fi bo kanga naa.

Nigba ti wọn gbe e de ile iwosan Solad Hospital. Maria Street ni agbegbe Baruwa kan naa ni Ipaja ti iṣẹlẹ ti ṣẹlẹ ni wọn rii pe o ti dakẹ.

Pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ panapana ati ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Alagolo ni wn jọ pawọpọ doola ọmọ naa latinu kanga.

Nibayii, wọn ti gbe oku ọmọ naa fun awọn mọlẹbi rẹ ati ikọ ọlọpaa to wa lati agọ ọlọpaa Alagolo eyi ti insipẹkitọ Abumere dari.

Lockdown: Àwọn jàǹdùkú ṣe ikú pa ẹnìkan ní Aboru l'ágbàgbè Iyana Ipaja

Awon olopaa

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI

Àkọlé àwòrán, Lockdown: Àwọn jàǹdùkú ṣe ikú pa ẹnìkan ní Aboru l'ágbàgbè Iyana Ipaja

Ènìyàn kan ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ níbi ìjà àwọn jàndùkú láti Aborun àti Mosan ní agbègbè Oke-Odo àti Ipaja nípìnlẹ̀ Eko.

Ìròyìn sọ pé, ìjà tí ó wáyé l'ọ́jọ́ ajé mú ìpalára bá ẹnìkan ti o sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tí ò ń wọ́n n gbe lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

Gẹ́gẹ́ bi fọ́nrán tó jẹyọ lọ́rí ayélujára, ọkùnrin kan gbé ẹni to ti farapa kọ́ apá to sì gbe gu ọ̀kadà lósí ibi ti ẹnìkan kò mọ.

"wọ́n ti paá , wọ́n ti paá ẹ lọ jùú si ibẹ̀ yẹn Abesan o fara rọ," bí ẹní to ká fọ́ran náà ṣe n pariwo rèé nígbà ti wọ́n ń gbé okú ẹni náà lọ ibi ti wọ́n ni wọ́n ti pàa.

Àwọn ti ọ̀rọ̀ náà sojú wọ́n ni to sì pe ara rẹ̀ ni Taiwo a.k.a Akala sàlàyé fún àwọn oníròyìn pé, ẹni tó gbé okú ọkùnrin náà ni wọ́n ń pe ni Eze, àti pé ni kété tó gbée kálẹ si ibi eti kana ni agbègbè afára Aboru ló kó àwọn jàǹdùkú míràn láti Aboru ló bá àwọn ara Mosan.

Àkọlé fídíò, Ọlọ́fàiná, àgbà òṣèré sinimá ní ìfẹ́ owó, àti ṣekárími ló ń dá wàhálà sílẹ̀ láwùjọ

Taiwo ní nítorí òfin ìgbéle COVID-19 ọ̀pọ̀ ló wà nílé, sáàjú ni àwọn ti gbọ́n pé àwọn One Million Boys ń bọ̀ láti kojú àwọn ará ilú, nítorí náà a kó ara wa síta láti gbèjà ara wa, sùgbọ́n nígbà tí o di ǹkan bíi aago mẹ́ta ọ̀sán mó rí Eze lórí ọ̀kadà pẹlú òkú èèyàn to sì gbékalẹ̀ sí Mosan lẹ́gbẹ̀ẹ́ afára aboru.

Kò pé ni o kó àwọn jàndùkú wá láti Aboru wá si Mosan tí wan si bẹ̀rẹ̀ si ni ṣọṣẹ́, wọ́n jí ǹkan àwọn èèyàn, ọ̀ps àwọn míràn tilẹ̀ fi ilé wọ́n sílẹ̀ tí wọ́n sì sálọ.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọpàá ní ìpínlẹ̀ Eko Bala Elkana sàlàyé pé, okú ti wọ́n ri yìí lo dá rúkèrúdò sílẹ̀ ní agbègbè náà àti pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣì ń wá Eze.

Bala ní wọ́n ti fi ẹjọ náà ṣọwọ́ sí ẹka ìwádìí ìwà ọ̀daràn ni Panti Yaba fún ìwádìí tó yẹ àti pé àwọn ọlọ́pàá ti gbé oku náà si ìpamọ́ láti tẹ̀síwájú nínú ìwádìí