Omololu Olunloyo: Ọdọmọde Kọmiṣọnnà tí kò pé ẹni ọgbọ̀n ọdún tó tún jé Gómìnà oṣù mẹ́ta

Omololu Olunloyo

Oríṣun àwòrán, others

Ta bá ń sọ̀rọ̀ ojúlówó àwọn ọmọ Yorùbá tó dantọ, àwọn ọmọ ilẹ̀ Kaaro óò jiire tí kìí ṣe asadanu, ọkàn ni Victor Omololu Olunloyo jẹ́.

Ta ni Omololu Olunloyo?

A leè ṣe àpèjúwe rẹ bii oloselu to dantọ, onímọ̀ ìṣirò to pegede àti ojúlówó ọmọ Ibadan tó yanranti

Ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹrin, ọdún 2020 ni Olunloyo pé ẹni ọdún marundinlaadorun lókè eepẹ.

Eyí tó mú kí BBC Yoruba ṣe àkójọ ìtàn nípa akọni ọmọwe náà, wọn sá ní arise ni arika, arika si ni baba ìtàn.

Gẹ́gẹ́ bá ṣe rí ka lójú òpó itakun agbaye, a leè ṣe àpèjúwe Olunloyo bii ọmọ tí yóò jẹ Asamu, to ti kékeré jẹnu samusamu, torí láti ìgbà èwe rẹ lọ tí de ibi gíga, tó sì di àwọn ipò ńláńla mú.

Ìtàn ìgbé ayé VictorOmololu Olunloyo:

Ìlú Ibadan, tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni wọn ti bi Omololu Olunloyo ni ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù kẹrin, ọdún 1935 èyí tó pé fi ọdún marunlelọgọrin báyìí.

Ìdílé Horatio Olunloyo, tíì ṣe ẹlẹsin Kristẹni ati Alhaja Bintu Tejumola Abebi Olunloyo, tíì ṣe musulumi ni wọn bí Omololu sì àmọ́ tó yàn ẹṣin Kristẹni láàyò ni ìlànà baba rẹ.

Àkọlé fídíò, 'Oun tí Kunle Afolayan ṣe sí mi, mi ò lè ṣeé sí i'

Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni Omololu nigba ti baba rẹ dagbere fàyè, síbẹ̀, ó kàwé de ipò ọmọwe (PhD) èyí to gba nílé ẹ̀kọ́ Fáṣitì St. Andrews ni ọdún 1961, nígbà tó pé ọdún mejidinlọgbọn péré.

Olunloyo

Oríṣun àwòrán, @ayobamiolunloyo

Lẹ́yìn ọdún kan tó gba òye ọmọwe ni wọn yàn Omololu ni Kọmiṣọnna feto idagbasoke ọrọ aje ni ẹkun ìwọ oòrùn Naijiria lapapọ.

Bákan náà lo tun jẹ Kọmiṣọnna fún idagbasoke àwùjọ, Kọmiṣọnna feto ẹ̀kọ́ nigba méjì, Kọmiṣọnna fún àkànṣe isẹ àti Kọmiṣọnna fún ìjọba ìbílẹ̀ àti oye jíjẹ.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Olunloyo sì lo gbe adé àti ọ̀pá àṣẹ fún Aláàfin ti Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta lórí nigba to jẹ Ọba.

Oun kan naa ló gbé ọpa aṣẹ Ọba ati Ade le Ṣọun tí Ogbomoso, Oba Jimoh Oyewumi Ajagungbade Kẹta lásìkò tó wà ní ipò Kọmíṣọnna náà.

Olunloyo

Oríṣun àwòrán, others

Irinajo oselu Omololu kò tán si ipo Kọmiṣọnna rárá nítorí ó tún díbo wọlé sípò gomina ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́dún 1983.

Labẹ́ asia ẹgbẹ́ òṣèlú National Party of Nigeria, NPN, táwọn èèyàn tún mọ si ẹgbẹ́ Onílé ni Omololu Olunlọyọ fi dije dupo wọle lati tukọ ipinlẹ Oyo.

Àmọ́, kòkòrò àwọn ológun tó gba ijọba ilẹ̀ wá nígbà náà, kò jẹ ki Omololu gbádùn òbí ipò gomina tó gbó kaka. Oṣù mẹta péré lo fi jẹ gomina, tí ìjọba ológun Muhammadu Buhari gba akoso Nàìjíríà ni ọjọ́ Kọkanlelọgbọn, osu Kejìlá, ọdún 1983.

Àkọlé fídíò, Ogundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Omololu Olunloyo tún tiraka nínú ètò oselu lẹ́yìn èyí àmọ́ kò di ipo kankan mú mọ, tí o sì di àgbà ọjẹ fún àwọn ọmọdé oselu.Omololu Olunloyo ni aya, tí sì bí ọpọ ọmọ nínú èyí ta ti ri gbajumọ akọroyin obìnrin kan, Kemi Omololu Olunloyo.

Àkọlé fídíò, Kunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

BBC Yoruba wa n gbàdúrà fún ọmọwe Victor Omololu Olunloyo to pé ẹni ọdun marundinlaadọrun lókè eepẹ pé Ọba òkè yóò túbọ̀ lọ́ra ẹ̀mí wọn fún ilẹ Yoruba.