Fredie Blom: Ọkùnrin tó dàgbà jù lágbàyé jáde láyé lẹ́ni ọdún 116 ní South Africa

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọkunrin ọmọ orilẹ-ede South Africa kan ti wọn ni o dagba julọ lagbaye ti dagbere faye lẹni ọdun mẹrindinlọgọfa.
Bo tilẹ jẹ pẹ ileeṣẹ to ma n ṣafihan awọn ohun to lamilaaka lagbaye, Guinness World Records, ko fi ontẹ lu ọjọ ori rẹ, wọn bi Fredie Blom ni agbegbe Ila Oorun Cape, lọdun 1904.
Ko to pe ogun ọdun lo ti padanu gbogbo ẹbi rẹ lọwọ ajakalẹ arun "Spanish flu" to kọlu agbaye lọdun 1918, lẹyin naa lo la ogun agbaye meji ọtọọtọ kọja.
- 'Ẹ̀pa ò bóró mọ́! Òkú ọmọ ọdún mẹ́ta tó kó sí kàǹga ní Ipaja ni wọ́n yọ'
- Ó ṣéeṣé ká fí owó kún #500,000 owó móríya ti a fi ń wá Sunday Shodipe- Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá
- Àwọn ohun tí ẹ nílò fún àyẹ̀wò ìgbanisíṣẹ́ ọlọ́pàá tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀la rèé
- Orí àkìtàn ni wọ́n ti rí ọkùnrin tó ń fi ìgbẹ́ jẹ Búrẹ́dì -Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo
- Bí mo ṣe mórí bọ́ nínú ọkọ̀ bàálù tí kò bá já - Aisha Buhari
Nigba to ba BBC sọrọ lọdun 2018, ọgbẹni Blom sọ pe ko si aṣiri kan gboogi si ẹmi gigun oun.
O ni "Ko si aṣiri kankan, Ọlọrun lo da mi si, igbakugba ni mo le ku ṣugbọn Ọlọrun lo gbemiro."
Iṣẹ alagbaṣẹ ni Blom fi pupọ ninu igbesi aye rẹ ṣe ko to fẹyinti lẹyin to le ni ọgọrin ọdun.

Oríṣun àwòrán, Fredie Blom
Blom maa n mu siga daadaa nigba aye rẹ, ṣugbọn o fi ọti silẹ lọpọ ọdun ko to jade laye.
Awọn ẹbi oloogbe ọhun sọ fun awọn akọroyin pe aisan kọ lo pa Blom.
Ọkan lara wọn, Andre Naidoo sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe "Ọsẹ meji ṣeyin, baba wa ṣi n la igi, ṣaka lara rẹ da, ko si si nkan kan to ṣelẹ si i."
Ṣugbọn o fi kun un pe o yọ jo laarin ọjọ diẹ sira wọn lai ṣaisan ṣaaju.
Naidoo pari ọrọ rẹ pe awọn ẹbi oloogbe naa ko gbagbọ pe arun Covid-19 lo mu ẹmi rẹ lọ.













