Nigeria Police Recruitment 2020: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní Kano tí ṣe àyẹ̀wò àwọn 13, 048 tó fẹ́ darapọ̀ mọ́ wọn

olopaa

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ẹ wo ìgbésẹ̀ tí ẹ máa gbé láti di ọlọpàá Naijiria bayii.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Kano ti ṣe ayẹwo fun awọn eniyan to le ni ẹgbẹrun mẹtala ti wọn fẹ darapọ mọ wọn,

Agbẹnusọ ileeṣẹ awọn ọlọpaa nipinlẹ naa, DSP Abdullahi Haruna lo fi ọrọ naa lede lasiko ayẹwo naa ni Ọjọ Ẹti ni ilu Kano.

Haruna ni awọn ti ṣe ayẹwọ fun awọn eniyan to wa lati ijọba ibilẹ ogoji ninu mẹrinlelogoji to wa ni ipinlẹ naa.

Wọn fikun un wi pe lara awọn ti wọn ti ṣe ayẹwo fun naa wa lati ijọba ipinlẹ Takai, Tarauni, Tofa, Tsanywa, Tudun Wada, Warawa, Wudil, ati Ungogo

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kano naa ṣeleri lati ṣe ayẹwo awọn ti wọn ba kuna lati wa fun eleyii ti wọn n ṣe lọwọlọwọ laipẹ.

Gẹgẹ bi ọrọ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa naa, gbogbo eto ti to lati ri i wi pe awọn to fẹ darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa, ti wọn si wa fun ayẹwo naa tẹle ofin ijinasiraẹni ati awọn ofin miran to rọmọ didena itankalẹ arun Covid- 19.

Nigeria Police Recruitment 2020: Àwọn ohun tí ẹ nílò fún àyẹ̀wò ìgbanisíṣẹ́ ọlọ́pàá tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní Mon, Aug 24

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Oyo, Osun, Cross River ati Bayelsa yoo bẹrẹ ayẹwo igbanisiṣẹ fun awọn to ti forukọ silẹ lati darapọ mọ ọ bẹrẹ lati ọjo Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020.

Ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Twitter rẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ni ayẹwo ọhun yoo waye fun ọsẹ meji gbako.

Lara awọn ohun to ni ki awọn eeyan naa mu wa sojuko ti ayẹwo naa yoo ti waye ni yii:

1. Nọmba idanimọ gẹgẹ ọmọ Naijiria, NIN.

2. Ojulowo ati fọtokọpi iwe ẹri ile iwe girama, iwe ẹri ilu abinibi, iwe ẹri to n ṣafihan ọjọ ori, faili funfun meji ati aworan pelebe.

3. Fọọmu iforukọsilẹ

4. Fọọmu oniduro

5. Aṣo penpe funfun ati ṣokoto pelebe to ṣee sare

6. Ibomu.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ileeṣẹ ọlọpaa ayẹwo naa yoo ni ilbanu pẹlu ilana itaketesiraẹni nitori ajakalẹ arun Covid-19 to wa lode.

Ẹwẹ, fun awọn to wa ni ipinlẹ Osun, ayẹwo naa yo waye ni awọn ijọba ibilẹ kọọkan ni awọn ọjọ wọnyii:

Ọjọ Aje, 24/08/2020

1. Ayedaade

2. Ayedire

3. Atakumosa East

Ọjọ Iṣẹgun 25/08/2020

4. Atakumosa West

5. Boluwaduro

6. Boripe

Ọjọru, 26/08/2020

7. Ede North

8. Ede South

Ọjọbọ, 27/08/2020

9. Egbedore

10. Ejigbo

Ọjọ Ẹti, 28/08/2020

11. Ife Central

12. Ife East

Ọjọ Abamẹta, 29/08/2020

13. Ife North

14. Ife South

Ọjọ Aje, 31/08/2020

15. Ifedayo

16. Ifelodun

17. Ila

Ọjọ Iṣẹgun, 1/09/2020

18. Ilesa East

19. Ilesa West

Ọjọru, 2/09/2020

20. Irepodun

21. Irewole

22. Isokan

Ọjọbọ 3/09/2020

23. Iwo

24. Obokun

25. Odo-otin

Ọjọ Ẹti 4/09/2020

26. Ola-Oluwa

27. Olorunda

28. Oriade

Ọjọ Abamẹta, 5/09/2020

29. Orolu

30. Osogbo

Gbé àwọn ìgbésẹ̀ yìí láti ṣàfikún ìròyìn nípa ará rẹ lójú òpó ìgbanisíṣẹ́ ọlọ́pàá

Aworan ọga Ọlọpaa M.A Adamu

Oríṣun àwòrán, PoliceNG

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti kesi gbogbo awọn to n wa isẹ to forukọ silẹ loju opo wọn, lati ṣe afikun iroyin nipa ara wọn ti wọn ti kọ silẹ ṣaaju.

Igbaniwọle ṣisẹ ọlọpaa bẹrẹ pẹlu ṣisi oju opo wọn lọjọ Kọkanlelọgbọn oṣu Keje ọdun 2020.

Nibẹ ni awọn to n wa iṣẹ pẹlu ọlọpaa yoo fi awọn iroyin nipa ara wọn si .

Wo bi o ti ṣele ṣafikun iroyin nipa ara rẹ

Kọ nọmba idanimọ NIN rẹ si oju aaye ti wọn la kalẹ.

Aworan ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, PoliceNG

Bi o ba ti fi nọmba yi ṣọwọ si aaye naa, o ma ni lati kọ gbogbo iroyin ti wọn n beere silẹ lati le fi ṣafikun eleyi to ti kọ tẹlẹ.

Awọn iwe ti o ma ni lati fi ṣọwọ:

•Iwe ẹri sabuke akẹkọjade ileewe girama

•Iwe ẹri ọjọ ori tabi iwe miran to tọka ọjọ ibi rẹ

•Iwe ẹri ọmọ ilu to ti wa eleyi ti oloyinbo n pe ni Certificate of Origin

Lẹyin to ba ti fi awọn nkan wọn yi ranṣẹ, tẹ aaye atẹjisẹ, buwọlu laaye ti wọn la kalẹ ki o si fi ṣọwọ.

Ri wi pe o tẹ iwe ẹri jade ti yoo ṣafihan pe o ti pari ipele yi ko si ṣakiyesi nọmba idanimọ ti yoo wulo fun ni ipele miran ninu eto igbaniwọle.

Tẹ iwe awọn ti yoo ṣe oniduro fun ọ jade.

Njẹ o tun ni awọn ibeere miran?

Pe sori ago yi 08100004507.

Tabi ki o tẹ iwe atẹjiṣẹ si adirẹsi yi loju opo ayelujara [email protected] or [email protected].

Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ lákọ̀tun

Ileeṣẹ Ọlọpaa Naijiria ti kede eto igbanisiṣẹ lakọtun bayii.

Wọn ni ẹni ọdun mẹtadinlogun si mẹẹdọgbọn nikan lo ni anfani lati kopa ninu eto naa.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ loju opo ikansiraẹni Twitter wọn pe

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Bawo ni ẹ ṣe maa fi orukọ silẹ?

Ti o ba ṣetan lati kopa ninu eto igbanisiṣe naa, kan si oju opo yii ki o si fi orukọ rẹ silẹ bi o ti yẹ:

Ẹ tẹ ni ori ẹrọ ibanisọrọ yin:

www.policerecruitment.gov.ng/maintainance

tabi ki ẹ kan si :

http://policerecruitment.gov.ng/maintanance.html

Kete ti ẹ ba ti de ibi yii ni ẹ ki ẹ pese awọn ifitonileti bii ibi ti ẹ ka iwe de, awọn iwe ẹri ti é ni ati bẹẹ bẹẹ lọ bayii:

olopaa

Oríṣun àwòrán, @Nigeria Police force

Ṣaaju ni Bashir Ahmed to jẹ olubadamọran si Aarẹ Buhari lori ifitonileti lori ayelujara naa ti kọkọ fi soju opo twitter rẹ nipa eto igbanisiṣẹ naa

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Diẹ lara awon Amuyẹ ki wọn to gba eeyan siṣẹ ree:

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹni to ba fẹ kopa ninu eto igbanisi iṣẹ naa gbọdọ ni esi idanwo WAEC rẹ pe iṣẹ marun un,

Ki o da pe lọmọkunrin tabi lọmọbinrin laini aisan kankan lara.

O tun gbọdọ jẹ ọlọpọlọ pipe ti ko ni aisan opolo.

Wọn ni alaboyun ko nile ko pa lasiko yii afi to ba bimọ tan.

O ko gbọdọ kuru ju iwọn 1.67 fun ọkunrin ati 1.64 fun obinrin to ba fẹ kopa.

Fifẹ aya rẹ gẹgẹ bii ọkunrin ko gbọdọ pọ ju iwọn 34 inches lọ.

olopaa

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, léeṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ lákọ̀tun