New electricity tariff: Wo ọ̀nà ìsanwó tuntun fún àwọn oníbàárà iná mọ̀nàmọ́ná Eko, EKDC

aworan idamo ileese EKDC

Oríṣun àwòrán, EKDC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn araalu ni ipinlẹ Eko ti n pariwo sita pe inira nla lawọn n dojukọ nigbakugba ti awsn ba fẹ san owo ina mita tuntun alasansilẹ wọn iyẹn Prepaid meter.

Ninu ọrọ to ba ileeṣẹ BBC News Yoruba sọ ileeṣẹ apinna ọba lẹkun Eko, EKDC ṣalaye pe afikun owo ina to waye lo ṣokunfa ipenija yii.

Alukoro ileeṣẹ EKDC, ṣalaye pe ayipada ẹrọ igbalode wọn lati ba odiwọn owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ kede naa mu lo fa eyi.

Ki ni awọn ohun to n fa iṣoro?

Ṣaaju ayipada owo naa, nọmba atẹgbana kan ṣoṣo ni onibara yoo gba bi o ba ti sanwo lori ayeluja

Amọṣa ni kete ti ayipada naa de, nọmba atẹsanwo gba ina mẹta ni yoo waye.

Eyi kun ara ohun to n fa idiwọ naa nitori ọpọ onibara ni ko mọ bo ṣe jẹ.

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu

Igbesẹ tuntun to yẹ lati tẹlẹ fun onibara to ba fẹ tẹ nọmba atẹsanwo gba ina niwọn yii:

1.San owo iye odiwọn ina ọba ti o fẹ lori awọon oju opo ayelujara ti wọn ya sọtọ fun owo sisan.

2.Ri i daju pe nọmba atẹsanwo gba ina ọba mẹta lo gba

3.Ri i daju pe awọn numba naa jẹ ogun lori ẹyọ kan; eyi to fihan pe ogun lọna mẹta ọtọọtọ lawọn nọmba naa jẹ.

4.Wa tẹ awọn nọmba atẹsanwo gba ina ọba naa si oju kaadi rẹ ni ṣiṣẹ n tẹle bi wọn ṣe fi ranṣẹ si o.

5.Bi o ba ni iṣoro kankan ni o le e tọ oju opo ileeṣẹ ina mọnamọna ẹkun Eko lọ ki o si kọ bi ipenija ti o n koju ba ṣe jẹ sibẹ.

ibudo ina

Oríṣun àwòrán, Nigeria electricity

Wo ọ̀nà tí o le è gbà láti má san àfikún owó iná ẹ̀lẹ́ńtíríìkì tuntun

Awọn ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna lorilẹ-ede Naijiria ti bẹrẹ si ni lo saa owo ina tuntun fun awọn to n lo ina ọba ni Naijiria bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kinni, oṣu kẹsan an, ọdun 2020.

Igbesẹ yii n waye nitori ayipada ti ajọ to n mojuto ohun gbogbo lẹka ipese ina ọba lorilẹede Naijiria, NERC gbe kalẹ.

Eto owo ina tuntun yii pin awọn to n lo ina manamana ni Naijiria si isọri marun un ni ibamu pẹlu bi kaluku ṣe n lo ina si.

Itumọ eyi ni pe, bi o ṣe n lo ina si lojumọ ni yoo sọ isọri owo ina sisan ti o o wa.

Ibrahim Sani Shawai to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ apinna ọba ni agbegbe Kano, Katsina ati Jigawa ṣalaye fun BBC pe wọn pin ilana naa si ẹlẹkajẹka bii awọn ileeṣẹ, ileeṣẹ ijọba atawọn agbegbe olowonla.

Àkọlé fídíò, Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Amọṣa bi awọn eeyan ba ri i pe agbara awọn gbe isọri olowo nla, awọn naa lee bọ si isọri awọn to n lo ina ọba daadaa.

"Itumọ eyi ni pe bi owo rẹ ba ṣe mọ loo ṣe lo ina si" iyẹn gẹgẹ bi Shawai ṣe sọ.

ibudo ina

Oríṣun àwòrán, others

Awọn isọri naa niwọnyii.

Isọri A- Awọn ti yoo maa lo ina mọnamọna fun ogun wakati tabi ju bẹẹ lọ.

Isọri B: Awọn wọnyii yoo maa lanfani siina manamana laarin wakati mẹrindinlogun si ogun wakati.

Isọri C: Awọn to ba wa ni isọri yii yoo lanfani si ipese ina manamana fun wakati mẹjs si mejila lojumọ

Isọri D: wakati mẹrin si mẹjọ lojumọ lawọn to wa ni isọri yii yoo maa fi ri ina ọba lo lojumọ.

Wahala ipese ina ẹlẹntiriki lorilẹede Naijiria jẹ eyi ti ọpọ onwoye ti tọka si gẹgẹ biara ohun to n da họwuhọwu silẹ lẹka ọrọ aje, paapaajulọ ẹka idaleeṣẹ silẹ.

Ọpọlọpọ awọn ileeṣẹ lo ti ko igba wọle lorilẹede Naijiria tabi ko igba wọn lọ si awọn orilẹede miran lnilẹ Afirika nitori idakureku ina manamana lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá

Bawo lọrọ ṣe bẹrẹ?

Ọmọ Nàìjíríà, àfikún owó iná tuntun bẹ̀rẹ̀ lónìí: ọjọ́ kínní, oṣù kẹsàn án, ọdún 2020- NERC, Disco

Lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ ni ajọ NERC ti atẹjade kan sita pe awọn onibara ileeṣẹ mọna-mọna yoo bẹrẹ si i maa san owo to ju ohun ti wọn n san tẹlẹ lọ.

Lọjọ kinni, oṣu keje lawọn ileeṣẹ ina ọba fẹ kawọn onibara wọn bẹrẹ si ni san owo ina tuntun tẹlẹ,

Ṣugbọn ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja ni ki wọn duro di ibẹrẹ ọdun 2021 nitori bi ilu ṣe ri bayii.

Amọ, atẹjade ti ajọ NERC fi sita lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kinni, oṣu kẹsan an fihan pe NERC kọ eti ikun si aṣẹ ile igbimọ aṣofin l'Abuja, o ṣi ṣe afikun owo ina bi o ti sọ tẹlẹ.

Ajọ NERC sọ pe gbogbo awọn to lo ina ọba ni alekun ti ba owo ti wọn n san ayafi awọn ti ko ba ki n lo ina fun wakati mejila lojumọ loku.

Prepaid meter

Oríṣun àwòrán, @topsy_adeusi

Alaye lori afikun owo ina naa:

Ajọ naa ni afikun owo ina to bẹrẹ lọjọ kinni oṣu kẹsan an yoo da le iya wakati tawọn onibara fi n lo ina lori.

Ajọ NERC ni ipin meji lawọn onibara ileeṣẹ mọna-mọna bayii: awọn to lo ina gan an ati awọn ti ko lo ina pupọ.

Eleyi yatọ si bi o ti ri tẹlẹ to jẹ pe ipin awọn to n lo ina nile wọn, awọn to n ṣ'owo to niṣe pẹlu ina atawọn ileeṣẹ nla to n lo ina.

Fun apẹẹẹrẹ, onibara ileeṣẹ ina ọba Ikeja to ba ni ina fun wakati mejila o kere tan ti o si n lo feesi kan, naira mejilelogun ni yoo maa san bayii ni wakati t jẹ ilọpo meji ohun ti wọn n san tẹlẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Awọn onibara ileeṣẹ ina ọba Eko yoo maa san naira mẹtalelogoji ni wakati kan ti wọn lo ina fun wakati mejila o kere tan lojumọ.

Ninu ọrọ ti ajọ NERC fi si oju opo Twitter rẹ, o ṣalaye pe awọn mẹkunnu ni afikun owo ina tuntun yoo ṣe lanfaani.

Wọn ni ko ni si iyanjẹ nipa owo in ọba tawọn eeyan n san mọ pẹlu atunṣe sisan owo ina ti ajọ NERC ati DISCO ti ṣe bayii.

Osisẹ mọnamna kan n lọ waya ina lori opo

Oríṣun àwòrán, Others

Wo oye owó ti ìjọba fẹ́ fi lé owó ináa ìlẹ́tírìkì

Iroyin ti o tẹwa lọwọ ti fi han pe, lati ọdun ti n bọ, awọn ọmọ Naijaria yoo maa san ju iye owo ti wọn n san tẹlẹ lọ fun ina ijọba.

Awọn ajọ apinaka ni yoo fi iye owo ti o le ni naira meọ si merinla lori kilowati ina ti awọn olubara wọn ba n lo.

Ajọ to n mojuto eto ina ilẹtiriki lorlẹ-ede yi, Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC), ti fi ọwọ si afikun lori owo ina tuntun naa.