Chief Kanran: Mi ò ṣagbe àmọ́ mo nílò ìrànlọ́wọ́ ọmọ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹ́ wo ìrírí tó mú àgbà òṣèré Chief Kanran dí ẹni tí kò rí ilé gbé mọ́, ti irinṣẹ́ jóná
Afiniṣẹ̀sín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá pàápàá àwọn ọ̀rẹ́ àwa òṣèré tíátà- Olusegun Akinremi
Agbaọjẹ oṣere lorilẹede Naijiria, Olusẹgun Akinrẹmi ti gbogbo eniyan mọ si Chief Kanran ti sọ iriri ati ilakọja rẹ fun awọn ọmọ Yoruba.
Chief Kanran sọ awọn ọrọ yii lasiko ifọrọwanilẹnuwo ti BBC News Yoruba ṣe pẹlu wọn ni ile ijọsin ti wọn n gbe.
Kanran sọ iriri rẹ bi oun ṣe di ẹni ti ko ri ile gbe mọ ati bi ohun gbogbo ṣe daru fun oun ni nkan bi ọdun melo ṣẹyin.
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa gbọ́nmi síi omi ò tó lórí ọ̀rọ̀ oyè Babaloja-General ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Iléẹjọ gíga jùlọ da ẹjọ́ SDP àti PDP nù, wọ́n ní Yahaya Bello ló wọlé ìbò gómìnà Kogi
- Ààrẹ Buhari buwọ́lu gbígbé ìṣàkoso nọ́mbà ìdánimọ̀ (NIMC) lọ sí ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀
- Wọ́n ti sún ìdájọ́ àwọn sójà tó pa ìyá àti ọmọ ní ọdun 2018 sí oṣù tó m bọ̀
Kanrani ni: "Lẹyin nkan bu oṣu diẹ ti mọ de lati Canada, ile iṣe ipolowo ọja ati yiya ere amohunmaworan mi jona raurau, ti irinṣe to le ni miliọnu lọna ọgbọn Naira si jọna patapata.''
"Ko pẹ diẹ si asiko yii ni awọn adigunjalẹ bẹrẹ si ni koju ija si mi, nitori wọn rọ wi pe emi ni mọ ni ile ti mo n gbe ati awọn ẹru ti wọn n ko wa lati oke okun to jẹ ti onile ti a n gbe naa.''
''Eyi lo mu ki n sakuro ni awọn ile ti mo n gbe naa, ti mo si sa asala fun ẹmi mi nipa sisalọ si ile ijọsin ni ibi ti mọ n gbe lọwọlọwo.''
Ẹyin ọmọ Yoruba, ẹ ran mi lọwọ lati ra irinṣẹ mi to jona patapata
Chief Kanran lasiko to n bere iranwọ lọwọ awọn ọmọ Naijiria sọ wi pe gbogbo ohun ini oun ni awọn ti oun ya owo ni ọwọ wọn lati ṣe sinima gba pada, ti oun si da ẹni ti ko ni ọkọ ayọkẹlẹ mọ.
O fikun wi pe ninu ipọnju yii ni oun wa fun ọpọlọpọ igba, ti iyawo meji ti oun ni si saisan ti wọn si ku.
"Idojukọ ti mo dojukọ ni lo mu mi ke gbajarẹ si awọn ọmọ ile Yoruba lati jọwọ ṣeranwọ fun mi nipa pipese irinṣẹ ti mo nilo lati bẹrẹ si ni ṣe ere oritage pada ati ṣiṣẹ awọn sinima.'
Bakan naa ni Chief Kanran fikun wi pe lọpọ igba ijọba kii ṣe iranwọ fun awọn oṣere bi ko ṣe pe asiko ti wọn ba ṣe aisan tabi ti wọn ba ku , ki wọn to dide iranlọwọ si wọn.
Amọ, agbaọjẹ naa sọ di mimọ pe oun ko tọrọ jẹ, bẹẹ ni oun ko ṣe agbẹ, ohun ti oun nilo lọwọ awọn ọmọ Yoruba ni iranlọwọ lati ra irinṣẹ ti yoo mu ohun pada si ipo.
Awọn oṣere igbalode ko pe wa si iṣẹ mọ , wọn ti gbagbe wa
Agbaọjẹ oṣere lorilẹede Naijiria, Olusẹgun Akinrẹmi ti ni awọn oṣere ode oni ti gbagbe awọn agbaojẹ oloṣere, ti wọn ko si naani wọn mọ.
Chief Kanran ni kii ṣe pe mama Ẹfunṣetan Aniwura ko le e kopa ninu ere mọ, amọ awọn eniyan ni ko pe wọn si iṣẹ.
Bakan naa ni wọn fikun pe afiniṣẹsin ni ọpọlọpọ awọn oṣere ni Naijiria, ti wọn si n wa isubu ẹnikeji wọn.
- Victoria Rubadir ọmọ Kenya ló gba àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor BBC World News.
- Ìjọba Ghana ṣí iléeṣẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà padà. Ó fún Nàìjíríà l'èsì àwọn ẹ̀sùn tó fi kàn-án
- Ọba ni mí, mi ò le b'ọ̀rìṣà, Olorì tuntun tó ń bọ̀ já gbogbo ''scale''- Oluwo ti Iwo
- Èèyàn méjì kú, méjìdínlógóje míì ṣẹ̀ṣẹ̀ kó COVID-19 lọ́jọ́ Àìkú
O ni oun ko fẹ iranwọ ẹgbẹ awọn oṣere ni Niajiria ati wi pe awọn ọmọ Yoruba ni oun fẹ ki wọn ran oun lọwọ lori iṣẹ oun.
Chief Kanran wa rọ awọn ọmọ Yoruba lati fi ọwọ sọwọpọ, ki wọn sọra fun gbogbo iwa ibajẹ ki wọn le de ibi aṣeyọri.
- Ìpínlẹ̀ Osun kéde ọjọ́ táwọn iléèwé yóò ṣí padà
- Máa gbé kẹ̀kẹ́ rẹ lọ, àwọn akọròyìn kọ̀ ìpàkọ́ sí Femi Fani Kayọde
- Èèyàn mẹ́tàlélógóje míì ṣẹ̀ṣẹ̀ kó COVID-19 ní Nàìjíríà
- Ọkùnrin kan di èrò ọ̀run nítorí pé o fi ẹ̀sùn kan alájọgbélé rẹ̀ pé o n yan ìyàwó ẹnìkan lálè
- Wo àwọn orílẹ́-èdè mẹ́wàá tí kò ní coronavirus lágbàáyé, bá wo ni wọ́n ṣe ṣe é?


















