Coronavirus pandemic update: Wo àwọn orílẹ́-èdè tí kò ní coronavirus lágbàáyé

The Palau Hotel, Koror

Oríṣun àwòrán, Palau Hotel

Àkọlé àwòrán, The Palau Hotel, Koror

Ajakalẹ arun coronavirus ti ṣọṣẹ kaakiri orilẹ-ede gbogbo lagbaaye a fi orilẹ-ede mẹwaa kan ti ọwọja rẹ ko de.

Wọn ṣi ile itura lorilẹ-ede Palau lọdun 1982 ki irin-ajọ igbafẹ to fẹsẹ rinlẹ, ṣugbọn lati igba naa, ọrọ-aje Palau ti gberasọ.

Lọdun 2019, ẹgbẹrun lọna aadọrun arinrin-ajo igbafẹ lo ṣabẹwo si Palau, eyi si jẹ ilọpo marun un gbogbo eeyan to wa nilẹ naa.

Koda lọdun 2017, ajọ eleto ẹyawo lagbaaye, IMF sọ pe ẹka eto igbafẹ nikan ko ida ogoji ninu iko ọgunrun un ọrọ-aje orilẹ-ede naa.

Ṣugbọn ki ajakakẹ aarun covid-19 to de ni gbogbo eleyi.

Orilẹ-ede Palau ti ibode rẹ lati oṣu kẹta ọdun 2020. Palau jẹ ọkan lara orilẹede mẹwaa ti ko ni akọsilẹ coronavirus kankan lati igba ti aarun naa ti ba gbogbo aye finra(awọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ ajọ iṣọkan agbaye, UNO la n sọ nibi yatọ si North Korea ati Turkmenistan).

Lootọọ ni pe ko si ẹni to laarun covid-19 nibẹ, ṣugbọn ajakalẹ aarun coronavirus si ṣakoba fun wọn lọpọlọpọ.

Gbajugbaja ile itura Palau ti di titi pa lati oṣu kẹta, koda gbogbo ile ounjẹ naa ṣofo

Àkọlé fídíò, Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá

Awọn orilẹede ti ko ni akọsilẹ coronavirus ree

  • Palau
  • Micronesia
  • Marshall Islands
  • Nauru
  • Kiribati
  • Solomon Islands
  • Tuvalu
  • Samoa
  • Vanuatu
  • Tonga
Àkọlé fídíò, Natalia Mufuta ìyá Yakub, Kamil àti Adam sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ń sọ èdè mẹ́rin pàpọ

Palau

Okun to wa ni Palau ko ni afiwe kaakiri agbaye, oludari ile itura Palau, Brian Lee lo sọ bẹẹ.

Okun to lawọ rẹsurẹsu lo maa n da Brian lọrun. Gbogbo yara mẹrinlelaadọta to wa nile itura rẹ lawọn alejo maa fẹ n gba tan.

Ṣugbọn nnkan ko ṣẹnu 're mọ lati igba ti wọn ti ti ibode pa.

Brian ni orilẹede kekere ni Palau, awọn eeyan orilẹede naa kii fẹ gba ile itura Palau.

Ogun oṣiṣẹ lo n ṣiṣẹ nilu itura Palau, ko si ẹni ti wọn da duro ninu wọn.

Brian ni ''gbogbo awọn oṣiṣẹ lo ṣi n wa sibi iṣẹ bo tilẹ jẹ ko si alejo kankan.

O ni ko rọrun lati maa tun ile itura ṣe fun lai si alejo to n gba a. Brian ni ti oun yoo gbiyanju lati ṣe e fun oṣu mẹfa sii lẹyin naa oun le ti ile itura ọhun pa.

Ẹwẹ, aarẹ orilẹede naa kede laipẹ yii pe irin-ajo ọkọ ofurufu yoo bẹrẹ pada lọjọ kinni oṣu kẹsan.

Map of Pacific Island nations

Marshall Islands

Marshall Island to wa ni erekusu okun Pacific naa ko ni akọsilẹ aarun covid-19, bo tilẹ jẹ pe coronavirus ṣakoba fun ọrọ-aje ti wọn naa.

Awọn arinrin ajo igbafẹ ko lo ṣabẹwo sawọn itura to wa nibẹ lati oṣu kẹta ti wọn ti gbe ibode ti pa.

Ẹẹdẹgbẹrin eeyan lo ṣeeṣe ko padanu iṣẹ wọn nitori ajakalẹ aarun covid-19, ọtale lugba o din meji awọn eeyan yii lo n ṣiṣẹ nile itura atawọn ile ounjẹ.

Awọn oṣisẹ ni Vanautu lọdun 2019

Oríṣun àwòrán, Mario Tama/Getty Images

Vanuatu

Lootọọ ni pe ibode ti wọn ti pe sọ ọpọ di alaini ni Vanautu, ọpọ eeyan ilẹ naa ni ko si fẹ ki wọn ṣi ibode naa pada laipẹ.

Dokita Len Tarivonda to jẹ oludari eto ilera nilẹ naa sọ pe ọpọ ọmọ orilẹede naa tawọn eeyan rẹ ko ju ẹgbẹrun un lọna ọdunrun un lọ ko fẹ ki ijọba ṣi ibode pada.

Dokita Tarivonda ni ''ohun ti wọn sọ nipe awọn ko fẹ ko aarun nitori awọn ko pọ tẹlẹ lorilẹede naa, bi bẹẹ kọọ, gbogbo eeyan le ku tan patapata.

Ọjọ kinni oṣu kẹsan an ọdun 2020 yii ni ijọba orilẹede Vanuata n gbero lati ṣi ibode rẹ pada.

Àkọlé fídíò, 'Superstorm' Harold hits Vanuatu after killing 27

Ki lawọn orilẹ-ede ti ko larun covid-19 le ṣe?

Ọna abayọ ni kiakia ni pe ki ijọba maa sanwo fawọn oṣiṣẹ atawọn oniṣowo.

Ohun miiran ti ijọba tun le ṣe ni ki o ṣeto abẹrẹ ajẹsara fun gbogbo araalu.

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'

Oṣiṣẹ ile ifowopamọ Asia, Rommel Rabanal lo sọ bẹẹ, o ni ijọba ni lati ṣeto fun ayẹwo awọn eeyan ki o si ṣeto ibudo iyasọtọ aibaamọ aarun covid-19 le bẹ silẹ.

Jonathan Pryke, oludari eto Pacific Island sọ pe oun ko le sọ bo ya kii ṣe titi ibode mawọn alejo lati ilẹ okeere nikan lọna abayọ si ọrọ coronavirus.

Amọ, Pryke ṣalaye pe ti wọn ṣi ibode gan an bayii, awọn ọmọ orilẹede Australia ati New Zealand to n maa ṣabẹwo sawọn orilẹede Pacific ko le wa bayii nitori awọn naa ti ti ibode wọn.