Yoruba World Congress: Mi o fi gbogbo ẹnu sọ pé ẹ̀yà Yorùbá yóò tún èrò rẹ̀ pa ní October 1- Akintoye

Akintoye

Oríṣun àwòrán, @thesignalng

Aarẹ ẹgbẹ ọmọ Yoruba l'agbaye, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti sọ pe oun ko lọwọ si lilo ipá tabi agidi fi ya kuro lorilẹ-ede Naijiria gẹgẹ bi ẹya Yoruba.

Ninu atẹjade kan to fi sita, Akintoye sọ pe looto ni oun gba pe awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni ẹto lati ṣe iwọde lori ipo ti orilẹ-ede wa.

Bakan naa ni wọn tun ni ẹtọ lati sọ pe awọn fẹ ẹ ya kuro lara Naijiria.

O ni ṣugbọn, oun kilọ pe ki awọn ẹya Yoruba ma ṣe fi ipo tyabi jagidijagan ṣe ohunkohun.

O ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ fun oun lati ri i ninu iwe iroyin kan pe oun sọ pe Aarẹ Buhari ni yoo jẹ aarẹ to kẹyin ni Naijiria, tabi pe ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ni ẹya Yoruba yoo tun ero rẹ pa.

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Akintoye ni: "Mi o fi igba kankan sọrọ lori ayajọ ọjọ ominira Naijiria, October 1, ju pe ki awọn to ba sọ pe dandan ni ki awọn ṣe iwọde ṣe e pẹlu alaafia ati ọwọ."

"Lootọ ni ipo ti Naijiria wa bayii ko dun mọ mi ninu, amọ erongba mi ni pe alaafia nikan ni a le fi mu ki ayipada o wa."

Ọjọgbọn Banji Akintoye ti fi igba kan jẹ senetọ lasiko iṣejọba awaarawa ẹlẹkeji.

Lẹnu ọjọ mẹta yii si ni iroyin ti n lọ lori ayelujara ati laarin ilu pe ẹya Yoruba yoo ya kuro lara orilẹ-ede Naijiria to ba di ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020. Ti wsn o si da orilẹ-ede ti wọn, Oduduwa Republic silẹ.

Fìdíhẹẹ́ ní Banji Akintoye nínú YWC, lílọ ni yóò lọ - Tola Adeniyi

Àkọlé fídíò, Fìdíhẹẹ́ ní Banji Akintoye nínú YWC, lílọ ni yóò lọ - Tola Adeniyi

Ó ti lé ni ọ̀ṣẹ̀ kan báyìí ti awuyewuye ti ń ṣẹ̀lẹ̀ láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Yoruba World Congress (YWC), ti àwọn kan si ti kéde pé ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye kìí ṣe olórí ẹgbẹ́ náà.

Kò pẹ́ sí àsìkò yìí ni àtẹ̀jáde míràn tún jẹ̀yọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ YWC pé kò ṣeeṣe kí ènìyàn mẹ́rin yọ ààré YWC kúrò lẹ́gbẹ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ̀nà láti mọ òkodoro ọ̀rọ̀ ló mú kí BBC News Yoruba bá olóyè Tola Adeniyi, ọjọ̀gbọ́n Banji Akintoye àti ọ̀túnba Deji Osibogun sọ̀rọ̀, láti tan ìmalẹ̀ sí awuyewuye náà.

Akọgun Tola Adeniyi:

Akogun Tola Adeniyi

Oríṣun àwòrán, Others

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Akọgun Tola Adeniyi sàlàyé pé, nǹkan to ṣe gbòógi jùlọ ni pé, YWC ko fi ìgba kan yan Akintoye gẹ́gẹ́ bi olórí, fìdí hẹ́ẹ lásan ni.

O ní lọ́pọ̀ ìgbà ti a wọn ba pe ìpàde, àwọn ti ko mọ bi ẹgbẹ́ YWC ṣe wa sáye, ni Akintoye maa n pè láti maa jẹ̀gàba lórí àwọn àgbà ẹgbẹ́.

Ó ni ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ti sọ fún Akintoye pé kìí ṣe gbogbo aṣọ ni à n sá lóòrùn, sùgbọ́n gbogbo àṣírí ẹgbẹ́ ni ọjọ̀gbọ́n máá n pe ará ìta sí.

Àkọlé fídíò, Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá

Adeniyi sàlàyé pe, èyí tó burú jùlọ ni pé, ọjọ́ kan ti o yẹ ki ìpàdé wáyé, ni bàbá lọ ko àwọn ènìyàn bi ogún kan wa, ti wọ́n si da ìpàdé rú, lẹ́yìn náà ni wọ́n gbe abájáde ìpàde lọ fun àwọn oní ìwé ìròyìn.

Adeniyi ní àwọn ẹgbẹ́ bi ọgọ́ta to darapọ̀ mọ́ YWC, sùgbọ́n àwọn olùdásílẹ YWC kìí ṣe olórí ti àwọn mọ́.

Lẹ́yìn àlàyé Akọgun Adeniyi yìí ni BBC tún bá, ọjọ̀gbọ́n Akintoye to jẹ olórí ẹgbẹ́ YWC sọ̀rọ̀.

Ọjọ̀gbọ́n Banji Akintoye:

Ọjọgbọn Banji Akintoye

Oríṣun àwòrán, Others

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Akintoye sọ pé, Yoruba Organization lo se ìpàde ni ọjọ́ kejìlélógun, oṣù kẹjọ, ọdún 2019, tí wọ́n sì ní àwọn fẹ́ yan òun sípò ààrẹ ẹgbẹ́.

Sùgbọ́n òun kọ̀ lati fún wọ́n ni èsì títí di ẹ̀yìn oṣù kan. Lẹyin èyí ni ìpàdé míràn wáyé ní ìlu Ibadan níbi ti wọ́n ti yan òun gẹ́gẹ́ bii ààrẹ ẹgbẹ́.

Ọjọ̀gbọ́n Akintoye ni, ìlànà ti àwọn mẹ́rin náà fẹ́ ki òun tọ́ kìí ṣe ǹka ti òun lè ṣe gẹ́gẹ́ bi àdari.

Ó fi kún pé, irú òṣèlú ti Awolowo ṣe nígbà ayé rẹ̀ ni òun náà ń ṣe, láti fún gbogbo ènìyàn lánfàni kí wọ́n sọ èrò wọ́n fún ìgbéga ìràn Yoruba.

Àkọlé fídíò, Temitope Akinnusi: Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló takú láti gbà mí síṣẹ́ torí mo ní ojú kan

Akintoye ní àwọn mẹ́rin ti wọ́n kọ lati ba awọn ṣe ìpàdé ti àwọn ṣe kẹ́yin, ti wan kọ̀ láti darapọ̀ mọ́ àwọn kò lágbára láti sọ pé òun kìí ṣe ààrẹ YWC.

"Títí di àsìkò yìí, àwọn ti àwọn ènìyàn yìí ń pé ni ọmọde náà ló n sá sóke sódo fun ìlọsíwáju ẹgbẹ́"

"Àwá ti di àgbà, ìgbaagba mí si ni láti fún wọ́n lóóre ọ̀fẹ́ láti jẹ́ ki ìtẹ́síwájú wà.

Sáájú àsìkò yìí Tola Adeniyi àti àwọn míràn ti máa ṣe ìpàdé tẹ́lẹ̀.

Àkọlé fídíò, Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase

"Idí ti a fi dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ ni, ìròyìn tó ni èdè Yoruba yóò parun láìpọ́ àti pé ètò ààbò ìràn Yoruba mẹ́hẹ."

Sùgbọ́n, nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, ọmọ ẹgbẹ́ míràn to tún bá BBC Yoruba Otunba Deji Osibogun to tún jẹ́ aṣojú ẹgbẹ́ Yoruba Kọ̀yà, se atilẹyin fun Alintoye.

Ọtunbọ Ayodeji Osibogun:

Deji Osibogun

Oríṣun àwòrán, Others

Osibogun ní kìí ṣe ènìyàn kan ni yóò yọ ọjọgbọ́n Akintoye, oníruuru ẹgbẹ́ ló parapọ̀ lati yan Akintoye sípò nítori náà ti wọ́n yóò ba yọ àwọn náà ni yóò jọ sọ.

Ó ní àdúrà lo ṣe pàtàki ti ìràn Yorùbá nílò láti kẹ́sẹ jári.

Kò sí ewu lóko, àfi gìrì àparò, Ọ̀rẹ̀ ni Akọgun Tola Adeniyi jẹ́ si Akọgun òun si ló mu wọ́n mọ Kila.

Àkọlé fídíò, Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Kí wọ́n to di ààrẹ, wọ́n jọ máa n jírorò nilé Akintoye ni, nítori náà gbogbo ipò ti Tola Adeniyi kìí baa wà ni YWC, kò ni àkósílẹ̀ nínú iwe òfin YWC.

Osibogun ni ìjà láàrin ọ̀rẹ́ ni, kìí ṣe láàrin ẹgbẹ́ YWC, nítori naa ọ̀rọ̀ tó ṣẹ́lẹ̀ kò lè da ẹgbẹ́ ru nítori kò sí ǹkan ti kò le dìjà láàrin ọ̀rẹ.

Yoruba World Congress:Akintoye yarí pé ọmọ ẹgbẹ́ mẹ́rin kò le yọ òun nípò

Akintoye

Oríṣun àwòrán, @deji_of_lagos

Awuyewuye to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ Yoruba World Congress, YWC, ti gbọna miran yọ, lẹyin ti awọn eekan inu ẹgbẹ naa faake kọri pe dandan ni ki wọn yọ ọjọgbọn Banji Akintoye nipo, gẹgẹ bi Aarẹ ẹgbẹ ọhun.

Ọkan pataki lara awọn to gbe ẹgbẹ naa kalẹ, Akogun Tola Adeniyi sọ fawọn akọroyin pe, lara idi ti wọn ṣe fi ọwọ osi juwe ile fun Akintoye, ko ṣẹyin awọn iwa kan to n wu, eyi to ni ko bojumu to.

O ni "A yọ ọ nipo gẹgẹ bi Aarẹ nitori a ri pe ko le e dari wa lọ ibi kankan pẹlu iru igbe aye to n gbe."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn oloye Taye Ayorinde to jẹ Baalẹ Ekotedo sọ pe, Akintoye ṣi ni aṣaaju awọn ọmọ kaarọ oojiire gẹgẹ bi awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba to le ni aadọrin ṣe yan an sipo.

Ẹwẹ, Akintoye funra rẹ ninu ifọrọwerọ kan ni eeyan mẹrin pere ko lagbara lati yọ oun nipo Aarẹ, ati pe oun mọ pe inu lo n bi wọn.

Akintoye

Oríṣun àwòrán, @thesignalng

Akintoye ni "Ede aiyede maa n waye ninu idile, ṣugbọn o di dandan ki wọn pari iru aawọ bẹẹ."

O tẹsiwaju pe "Mo mọ idi ti wọn ṣe n binu ṣugbọn eeyan mẹrin pere ko lagbara lati yọ adari nipo, o da mi loju pe gbogbo ohun to n run nilẹ maa tan laipẹ jọjọ."

Ṣugbọn Adeniyi ṣalaye siwaju sii pe, ohun to fa ede aiyede ko ṣẹyin bi awọn kan ṣe n fi aadọrin ẹgbẹ ọmọ Yoruba ti ko kọja ilu Ketu, ni Benin Republic ṣafiwe ẹgbẹ ọmọ Yoruba kakiri agbaye, eyi ti Akintoye jẹ adari fun ki wọn to fi ọwọ osi juwe ile fun un.

Nigba to n sọrọ lori pe awọn oloṣelu ti rapala wọ ẹgbẹ YWC, Adeniyi ni ko ṣeeṣe ki awọn oloṣelu darapọ mọ ẹgbẹ naa nitori awọn oloṣelu lo sọ orilẹ-ede naa di bo ṣe wa loni.

Ọdun 2019 ni wọn yan Akintoye sipo gẹgẹ bi Aarẹ ẹgbẹ YWC lẹyin ti aga naa ti ṣofo fun ọpọ ọdun lẹyin ti oloye Abraham Adesanya jade laye.

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu

Ki lo tin ṣẹlẹ sẹyin?

Wo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ 19 tó fọwọ́ sí yíyan Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye

Ọjọgbọn Banji Akintoye

Oríṣun àwòrán, Other

Eeyan mọkandinlogun ninu ọmọ ẹgbẹ itẹsiwaju Yoruba jakejado agbaye ti tọwọ bọwe pe irọ ni awuyewuye to n lọ lode pe wọn yọ Ọjọgbọn Akintoye to jẹ aarẹ loye.

Wọn sọrọ yi ninu atẹjade pe awọn adari nkan bii aadọta ẹlẹgbẹjẹgbẹ to parapọ di agbarijọ ẹgbẹ itẹsiwaju Yoruba lagbaye lo yan Ọjọgbọn Banji Akintoye gẹgẹ bi adari ẹgbẹ naa.

Bẹẹ wọn jẹ ko di mimọ pe oṣuṣu ọwọ kan ṣoṣo ni ẹgbẹ YWC labẹ idari Ọjọgbọn Banji Akintoye ati pe "a gboriyin fun igboya ati ọkan ire ti Akintoye ni si mimu ayipada ba iran Yoruba lagbaye".

Atẹjade naa sọ pe ko si idarudapọ kankan laarin ẹgbẹ YWC 'a o si si ninu fa ki n fa a pẹlu ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kankan.'

"Ọrọ aarin mọlẹbi leleyii to ṣẹlẹ a si ti n yanjuẹ laarin agbo ile".

"A ṣi ni ifarajin si awọn alakalẹ ati afojusun ẹgbẹ YWC gẹgẹ bi Ọjọgbọn Banji Akintoye ṣe ntukọ rẹ fun ayipada iran Yoruba ati lati ni ireti ọjọ iwaju rere fun awọn ọdọ.''

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Ruga settlement: YCE ní ìjọba àpapọ̀ ko tó bẹ̀ẹ́ láti kọ́ àgọ́ Fulani sílẹ̀ Yoruba

Wọn tẹnu mọ ọ pe "apapọ ẹgbẹ to dibo yan Ọjọgbọn Banji Akintoye gẹgẹ bi adari Yoruba lọdun kan sẹyin naa lo korajọ lati tun sọ pe awọn ni igbagbọ ninu rẹ''

Awọn mọkandinlogun to tọwọ bọwe ree:1. Chief Taiye Ayorinde2. Comrade Victor Taiwo3. Prof. Kayode Ogundoro4. Sheik Abdulraheem Aduanigba.chief imam YORUBA LAND5. Dr. Tunde Amusat6. Sina Akinpelu7. Evangelist Kunle Adesokan8. Princess Oyeronke Akinlolu9. Dr. Juwon Akinsola10. Engineer Muda Dayo Ogunsola11. Architect George Akinola12. Professor Wale Adeniran13. Princess Tanimowo Okusaga 14. Prince Kola Bamigbade15. Comrade Okunola Kolawole16. Brief Mrs Patricia Abiodun17. Alhaji Ali Dodo Oyedeji18. Hon. Babatunde Tolase19. Prince Lawal Onikeke Quassim

YWC yọ Ààrẹ Banji Akintoye nípò àbi Akintoye tú ìgbìmọ̀ aláṣẹ YWC ká?

Awuyewuye lori ẹgbẹ ọmọ Yoruba lagbaaye (Yoruba World Congress), tun ti bẹyin yọ, lẹyin ti aarẹ YWC, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ ọhun ka.

Awọn oludari ati akọwe ti gbogbo wọn jẹ mẹrindinlogun lo wa ninu igbimọ naa.

Ẹgbẹ YWC tun sọ pe ohun yoo gbe igbimọ ẹlẹni mẹrin dide lati ba Aarẹ ẹgbẹ naa Ọjọgbọn Akintoye ṣiṣẹ pọ titi ti wọn yoo yan awọn mii.

Ọmọ ẹgbẹ kan, Ọmọbabinrin Tanimowo Okusaga lo fọrọ yii lede ninu atẹjade kan to gbe sita lorukọ gbogbo ẹgbẹ YWC.

O tun sọ ninu atẹjade naa pe ko si iyapa ninu ẹgbẹ YWC, o ni gbọingbọin ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ duro lẹyin aarẹ ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Akintoye.

Àkọlé fídíò, Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá

Awọn eekan inu ẹgbẹ YWC bii Akin Adejuwon, Ariyike Obet, Nureen Soludero, Bunmi Abidogun, Kunle Adesokan, Muda Ogunsola, Oloye Aduranigba, Imaamu Iyanda Wasiu Abiodun, Paul Bankole, ati Ọmọbabinrin Oyeronke Akinlolu lo wa nibi ipade ti ọrọ naa ti jẹ jade niluu Ibadan.

Amọ, iroyin mii to tun lu ayelujara pa tun sọ pe ẹgbẹ YWC ti yọ Ọjọgbọn Akintoye gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ naa.

Àkọlé fídíò, Wo bí Sunday Orimola ṣe gba ikú ẹranko kú ní Ifon ni Ondo lórí ọ̀nà àtijẹ

Iroyin ọhun sọ pe Ọmọwe Amos Akingba, Oloye Tola Adeniyi, Oloye Solagbade Popoola ati Ọjọgbọn Anthony Kila ti wọn da ẹgbẹ YWC silẹ fi atẹjade kan sita ninu eyi ti wọn ti sọ pe iwa tani yoo mu mi, aikoju oṣuwọn ati titapa si ofin ẹgbẹ lo ṣe okunfa yiyọ ọ nipo.

Wọn ni ko ṣeku ko ṣẹyẹ ni Ọjọgbọn Akintoye wi pe bi o ṣe n ṣe ẹgbẹ Afẹnifere, lo n ṣe awọn ẹgbẹ mii nigba ti o si jẹ aarẹ YWC.

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'