2023 Election: Ọọfììsì Ààrẹ ni Buhari kò ní gbápotí ìbò mọ́

Ọfiisi Aarẹ Orilẹ-ede Naijiria ti ṣi aṣọ loju eegun ọrọ wi pe Aarẹ Buhari ko ni ipinnu lati dije fun ipo naa lẹẹkẹta.
Ọrọ yii lo suyọ latari iwọde ti awọn ẹgbẹ kan ṣe fun ipadabọ Aarẹ naa lẹẹkẹta sori aleefa.
Ṣe iwe ofin orilẹ-ede yii ko kuku faaye gba gbigbe apoti ibo lẹẹkẹta lẹyin ti o ba ti ṣe ijọba lẹẹmeji.
Abẹnugan agba fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Garba Shehu tẹsiwaju wi pe Aarẹ ko ni akoko tabi ero ọkan lati yi ofin orilẹ-ede yii pada.
Alẹ ọjọ lṣẹgun ni Garba sọrọ yii pe Buhari ko le yi iwe ofin ti o ṣe alakalẹ ẹẹmeji pere fun Aarẹ pada rara.
O tẹsiwaju pe, Aarẹ naa dije ni ọdun 2015 leyin ti o pari saa kinni rẹ ti o si dije fun saa keji ni oṣu keji, ọdun 2019.
O ni fun idi eyi, o di ọdun ọdun 2023 ki o to pari saa keji ti yoo si gbe ijọba silẹ.
Shehu ṣe alaye pe, Aare yoo lo asiko saa keji naa ni ofiisi daadaa ti ko si ni gbe apoti idibo rara ni ọdun 2023.
Ṣe ṣaaju asiko ibo ni Aarẹ Buhari ti sọ wi pe ẹẹkan pere ni oun yoo ṣe ni ọdun 2015 .
Ṣugbọn ti o tun yi ohun pada to tun fi jade ni ọdun 2018 lati dije fun saa keji.
Tẹlẹ ni awọn aṣofin ilẹ yii ti fẹ yii iwe ofin naa pada fun Aarẹ ana Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni 2007 ti ipinnu yii si fori ṣọpọn.
Aarẹ Buhari ni o ti dari orilẹ-ede yii ṣaaju ọdun 2015 nigba ti o wa ni ologun ni ọdun 1983 ati 1985 gẹgẹ bi ọga ologun.














